ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 16
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Wọ́n lè pa àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù (1-4a)

      • Iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ máa ṣe (4b-16)

      • Ìbànújẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn máa di ayọ̀ (17-24)

      • Jésù ti ṣẹ́gun ayé (25-33)

Jòhánù 16:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2002, ojú ìwé 17

Jòhánù 16:2

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 9:22
  • +Mt 24:9; Iṣe 8:1; 12:1, 2; 26:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

Jòhánù 16:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 8:19; 15:20, 21; Ro 10:2; 1Kọ 2:8

Jòhánù 16:4

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 13:19; 14:29

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

Jòhánù 16:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:33; 13:3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

Jòhánù 16:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 16:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

Jòhánù 16:7

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:16, 26; 15:26; Iṣe 2:32, 33

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

    9/15/1992, ojú ìwé 15-16

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 22

Jòhánù 16:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 22

Jòhánù 16:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 15:22
  • +Jo 5:37, 38

Jòhánù 16:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 12:31; 14:30

Jòhánù 16:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 49

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2012, ojú ìwé 6-7

Jòhánù 16:13

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Ọ̀rọ̀ náà “ìyẹn” àti “ó” tó wà ní ẹsẹ 13 àti 14 ń tọ́ka sí “olùrànlọ́wọ́” tó wà ní ẹsẹ 7. Jésù lo ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́” (tí wọ́n ń lò fún ọkùnrin lédè Gíríìkì) bí àkànlò èdè tó ń tọ́ka sí ẹ̀mí mímọ́ bíi pé ó jẹ́ ẹnì kan. Agbára ni ẹ̀mí yìí, kì í ṣe ẹnì kan, ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń lò fún un lédè Gíríìkì kò tọ́ka sí ọkùnrin tàbí obìnrin.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 16:7
  • +Iṣe 11:28; 21:10, 11; 1Ti 4:1

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìjọba Ọlọ́run Ti Ń Ṣàkóso!, ojú ìwé 49

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

    4/1/2000, ojú ìwé 8-9

    Mẹtalọkan, ojú ìwé 22

Jòhánù 16:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Jo 4:2
  • +Jo 15:26; 1Jo 2:27

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/15/2008, ojú ìwé 32

Jòhánù 16:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 17:10

Jòhánù 16:16

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:33; 14:19

Jòhánù 16:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 28:8; Lk 24:39-41; Jo 20:19, 20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 278

Jòhánù 16:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 24:51, 52

Jòhánù 16:23

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Flp 4:6
  • +Jo 14:13; 15:16; 1Jo 5:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde),

    No. 1 2021 ojú ìwé 10

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 17

    Ayọ, ojú ìwé 122-124

Jòhánù 16:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 17

    Ilé Ìṣọ́,

    2/1/2008, ojú ìwé 11-14

Jòhánù 16:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:21
  • +Jo 17:7, 8

Jòhánù 16:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 13:3; Heb 9:24

Jòhánù 16:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 13:7; Mt 26:31; Mk 14:27
  • +Jo 8:29

Jòhánù 16:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 14:27; Ef 2:14
  • +Jo 14:30; Iṣe 14:22; 1Jo 4:4; 5:4; Ifi 3:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àlàyé Àwọn Ẹsẹ Bíbélì, àpilẹ̀kọ 22

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2021, ojú ìwé 4

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    4/2016, ojú ìwé 25-26

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 279

    Ìparí Ìṣípayá, ojú ìwé 84-85

    Ilé Ìṣọ́,

    3/15/2003, ojú ìwé 4

    2/1/1993, ojú ìwé 5

Àwọn míì

Jòh. 16:2Jo 9:22
Jòh. 16:2Mt 24:9; Iṣe 8:1; 12:1, 2; 26:11
Jòh. 16:3Jo 8:19; 15:20, 21; Ro 10:2; 1Kọ 2:8
Jòh. 16:4Jo 13:19; 14:29
Jòh. 16:5Jo 7:33; 13:3
Jòh. 16:6Jo 16:22
Jòh. 16:7Jo 14:16, 26; 15:26; Iṣe 2:32, 33
Jòh. 16:9Jo 15:22
Jòh. 16:9Jo 5:37, 38
Jòh. 16:11Jo 12:31; 14:30
Jòh. 16:13Jo 16:7
Jòh. 16:13Iṣe 11:28; 21:10, 11; 1Ti 4:1
Jòh. 16:141Jo 4:2
Jòh. 16:14Jo 15:26; 1Jo 2:27
Jòh. 16:15Jo 17:10
Jòh. 16:16Jo 7:33; 14:19
Jòh. 16:20Mt 28:8; Lk 24:39-41; Jo 20:19, 20
Jòh. 16:22Lk 24:51, 52
Jòh. 16:23Flp 4:6
Jòh. 16:23Jo 14:13; 15:16; 1Jo 5:14
Jòh. 16:27Jo 14:21
Jòh. 16:27Jo 17:7, 8
Jòh. 16:28Jo 13:3; Heb 9:24
Jòh. 16:32Sek 13:7; Mt 26:31; Mk 14:27
Jòh. 16:32Jo 8:29
Jòh. 16:33Jo 14:27; Ef 2:14
Jòh. 16:33Jo 14:30; Iṣe 14:22; 1Jo 4:4; 5:4; Ifi 3:21
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 16:1-33

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

16 “Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kí ẹ má bàa kọsẹ̀. 2 Àwọn èèyàn máa lé yín kúrò nínú sínágọ́gù.+ Kódà, wákàtí náà ń bọ̀, nígbà tí ẹnikẹ́ni tó bá pa yín+ máa rò pé ṣe lòun ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún Ọlọ́run. 3 Àmọ́ wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan yìí torí pé wọn ò tíì wá mọ Baba, wọn ò sì tíì wá mọ̀ mí.+ 4 Síbẹ̀, mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, kó lè jẹ́ pé tí wákàtí tí wọ́n máa ṣẹlẹ̀ bá dé, ẹ máa rántí pé mo sọ fún yín.+

“Mi ò kọ́kọ́ sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, torí mo wà pẹ̀lú yín. 5 Àmọ́ ní báyìí, mò ń lọ sọ́dọ̀ Ẹni tó rán mi;+ síbẹ̀ ìkankan nínú yín ò bi mí pé, ‘Ibo lò ń lọ?’ 6 Àmọ́ torí pé mo sọ àwọn nǹkan yìí fún yín, ẹ̀dùn ọkàn ti bá yín gidigidi.+ 7 Síbẹ̀, òótọ́ ni mò ń sọ fún yín, torí yín ni mo ṣe ń lọ. Ìdí ni pé tí mi ò bá lọ, olùrànlọ́wọ́ náà+ ò ní wá sọ́dọ̀ yín; àmọ́ tí mo bá lọ, màá rán an sí yín. 8 Tí ó bá sì dé, ó máa fún ayé ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ nípa ẹ̀ṣẹ̀, nípa òdodo àti nípa ìdájọ́: 9 lákọ̀ọ́kọ́, nípa ẹ̀ṣẹ̀,+ torí pé wọn ò ní ìgbàgbọ́ nínú mi;+ 10 lẹ́yìn náà, nípa òdodo, torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ ò sì ní rí mi mọ́; 11 lẹ́yìn náà, nípa ìdájọ́, torí pé a ti dá alákòóso ayé yìí lẹ́jọ́.+

12 “Mo ṣì ní ọ̀pọ̀ nǹkan tí mo fẹ́ sọ fún yín, àmọ́ ẹ ò ní lè gbà á báyìí. 13 Àmọ́ tí ìyẹn* bá dé, ẹ̀mí òtítọ́,+ ó máa darí yín sínú gbogbo òtítọ́, torí kì í ṣe èrò ara rẹ̀ ló máa sọ, àmọ́ ohun tó gbọ́ ló máa sọ, ó sì máa kéde àwọn nǹkan tó ń bọ̀ fún yín.+ 14 Ó máa yìn mí lógo,+ torí pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín.+ 15 Gbogbo ohun tí Baba ní jẹ́ tèmi.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ pé ó máa gbà lára ohun tó jẹ́ tèmi, ó sì máa kéde rẹ̀ fún yín. 16 Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi mọ́,+ bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi.”

17 Ni àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bá sọ fún ara wọn pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún wa pé, ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi’ àti pé, ‘torí pé mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba?” 18 Torí náà, wọ́n ń sọ pé: “Kí ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé, ‘ní ìgbà díẹ̀ sí i’? A ò mọ ohun tó ń sọ.” 19 Jésù mọ̀ pé wọ́n fẹ́ bi òun ní ìbéèrè, torí náà, ó sọ fún wọn pé: “Ṣé torí mo sọ pé: ‘Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ ò ní rí mi, bákan náà, ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹ máa rí mi,’ lẹ ṣe ń bi ara yín lọ́rọ̀ yìí? 20 Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ẹ máa sunkún, ẹ sì máa pohùn réré ẹkún, àmọ́ ayé máa yọ̀; ẹ̀dùn ọkàn máa bá yín, àmọ́ ẹ̀dùn ọkàn yín máa di ayọ̀.+ 21 Tí obìnrin kan bá fẹ́ bímọ, ẹ̀dùn ọkàn máa ń bá a torí pé wákàtí rẹ̀ ti tó, àmọ́ tó bá ti bí ọmọ náà, kò ní rántí ìpọ́njú náà mọ́ torí inú rẹ̀ máa dùn pé a ti bí ọmọ kan sí ayé. 22 Bẹ́ẹ̀ náà ni ẹ̀yin, ẹ̀dùn ọkàn bá yín báyìí; àmọ́ màá tún rí yín, inú yín sì máa dùn,+ ẹnì kankan ò sì ní gba ayọ̀ yín mọ́ yín lọ́wọ́. 23 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ ò ní bi mí ní ìbéèrè kankan rárá. Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, tí ẹ bá béèrè ohunkóhun lọ́wọ́ Baba,+ ó máa fún yín ní orúkọ mi.+ 24 Títí di báyìí, ẹ ò tíì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi. Ẹ béèrè, ẹ sì máa rí gbà, kí ayọ̀ yín lè kún rẹ́rẹ́.

25 “Àfiwé ni mo fi sọ àwọn nǹkan yìí fún yín. Wákàtí náà ń bọ̀ nígbà tí mi ò ní lo àfiwé láti bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, àmọ́ màá sọ fún yín nípa Baba lọ́nà tó ṣe kedere. 26 Ní ọjọ́ yẹn, ẹ máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi; ohun tí mo sọ yìí ò túmọ̀ sí pé màá bá yín béèrè. 27 Torí Baba fúnra rẹ̀ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún yín, torí pé ẹ ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún mi,+ ẹ sì ti gbà gbọ́ pé mo wá bí aṣojú Ọlọ́run.+ 28 Mo wá bí aṣojú Baba, mo sì ti wá sí ayé. Mo ti wá ń kúrò ní ayé báyìí, mo sì ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”+

29 Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ pé: “Wò ó! Ọ̀rọ̀ rẹ ti ṣe kedere báyìí, o ò lo àfiwé. 30 A ti wá mọ̀ báyìí pé o mọ ohun gbogbo, o ò sì nílò kí ẹnikẹ́ni bi ọ́ ní ìbéèrè. Èyí mú ká gbà gbọ́ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run lo ti wá.” 31 Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ṣé ẹ ti gbà gbọ́ báyìí? 32 Ẹ wò ó! Wákàtí náà ń bọ̀, ní tòótọ́, ó ti dé, nígbà tí wọ́n máa tú ẹnì kọ̀ọ̀kan yín ká sí ilé rẹ̀, ẹ sì máa fi èmi nìkan sílẹ̀.+ Àmọ́ mi ò dá wà, torí pé Baba wà pẹ̀lú mi.+ 33 Mo ti sọ àwọn nǹkan yìí fún yín kí ẹ lè ní àlàáfíà nípasẹ̀ mi.+ Ẹ máa ní ìpọ́njú nínú ayé, àmọ́ ẹ mọ́kàn le! Mo ti ṣẹ́gun ayé.”+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́