ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jòhánù 18
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Jòhánù

      • Júdásì da Jésù (1-9)

      • Pétérù lo idà (10, 11)

      • Wọ́n mú Jésù lọ sọ́dọ̀ Ánásì (12-14)

      • Ìgbà àkọ́kọ́ tí Pétérù sẹ́ (15-18)

      • Jésù dé iwájú Ánásì (19-24)

      • Pétérù sẹ́ lẹ́ẹ̀kejì àti lẹ́ẹ̀kẹta (25-27)

      • Jésù dé iwájú Pílátù (28-40)

        • “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí” (36)

Jòhánù 18:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ojú ọ̀gbàrá Kídírónì ti ìgbà òtútù.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 15:23
  • +Mt 26:36; Mk 14:32; Lk 22:39

Jòhánù 18:3

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:47; Mk 14:43

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

Jòhánù 18:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 35-36

Jòhánù 18:5

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 2:23
  • +Lk 22:47

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn,” ojú ìwé 35-36

Jòhánù 18:6

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 7:46

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

Jòhánù 18:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

Jòhánù 18:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 6:39; 17:12

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

Jòhánù 18:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:51; Mk 14:47; Lk 22:50

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/1998, ojú ìwé 14-15

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 16-17

Jòhánù 18:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:52; Lk 22:51; Jo 18:36
  • +Mt 20:22; 26:42

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 284

    Ilé Ìṣọ́,

    9/1/2002, ojú ìwé 10

Jòhánù 18:12

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “fàṣẹ ọba mú.”

Jòhánù 18:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Lk 3:2; Iṣe 4:5, 6
  • +Mt 26:57; Jo 18:24

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2012, ojú ìwé 9

    4/1/2011, ojú ìwé 19

    1/15/2006, ojú ìwé 10-11

Jòhánù 18:14

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 11:49, 50

Jòhánù 18:15

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:58; Mk 14:54; Lk 22:54

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 288

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 16-17

    Ilé-Ìṣọ́nà,

    4/1/1991, ojú ìwé 31

Jòhánù 18:16

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àbáwọlé.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ìwé fún Gbogbo Ènìyàn, ojú ìwé 16-17

Jòhánù 18:17

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:69, 70; Mk 14:66-68; Lk 22:55-57; Jo 18:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 288

Jòhánù 18:18

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé, 5/2018, ojú ìwé 7

Jòhánù 18:20

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:55; Lk 4:15; 19:47; Jo 7:14

Jòhánù 18:21

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2011, ojú ìwé 19

Jòhánù 18:22

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 50:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2011, ojú ìwé 19

Jòhánù 18:23

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “jẹ́rìí sí.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    2/15/2011, ojú ìwé 5

Jòhánù 18:24

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:57

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 30-31

Jòhánù 18:25

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:69, 70; Mk 14:69, 70; Lk 22:58

Jòhánù 18:26

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 18:10

Jòhánù 18:27

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 26:74; Mk 14:72; Lk 22:60; Jo 13:38

Jòhánù 18:28

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:2; Mk 15:1; Lk 23:1
  • +Iṣe 10:28

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 290-291

    “Ilẹ̀ Dáradára,” ojú ìwé 30-31

Jòhánù 18:30

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “kì í ṣe ọ̀daràn ni.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2011, ojú ìwé 21

Jòhánù 18:31

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:6
  • +Jo 19:10

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 291

Jòhánù 18:32

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 20:18, 19; Jo 3:14; 12:32

Jòhánù 18:33

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:11; Jo 12:13

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 291

Jòhánù 18:34

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 291

Jòhánù 18:35

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 291

Jòhánù 18:36

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +1Ti 6:13
  • +Ais 9:6; Da 2:44; 7:14
  • +Mt 26:52, 53; Jo 18:11

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 31

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    6/2018, ojú ìwé 4-5

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 292

    Ilé Ìṣọ́,

    11/1/2002, ojú ìwé 15-16

    2/1/1992, ojú ìwé 5-6

    Jọ́sìn Ọlọ́run, ojú ìwé 160-161

Jòhánù 18:37

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:11
  • +Jo 1:14, 17; 14:6

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 18

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    3/2020, ojú ìwé 18

    Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́,

    10/2018, ojú ìwé 7

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 292

    Ilé Ìṣọ́,

    1/1/2005, ojú ìwé 14-16

    10/1/2003, ojú ìwé 9-10

    8/1/2003, ojú ìwé 12

    7/15/2002, ojú ìwé 16

    3/1/2002, ojú ìwé 13

Jòhánù 18:38

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:24; Lk 23:4; Jo 15:25

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 292

    Ilé Ìṣọ́,

    6/1/2014, ojú ìwé 12

    5/15/2010, ojú ìwé 5

    10/1/2007, ojú ìwé 32

    8/1/2003, ojú ìwé 12

    3/1/2002, ojú ìwé 13

    7/1/1995, ojú ìwé 3

    12/15/1992, ojú ìwé 15

Jòhánù 18:39

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Mt 27:15; Mk 15:6

Jòhánù 18:40

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Nọ 35:31; Lk 23:18, 19; Iṣe 3:14

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    4/1/2011, ojú ìwé 10

Àwọn míì

Jòh. 18:12Sa 15:23
Jòh. 18:1Mt 26:36; Mk 14:32; Lk 22:39
Jòh. 18:3Mt 26:47; Mk 14:43
Jòh. 18:5Mt 2:23
Jòh. 18:5Lk 22:47
Jòh. 18:6Jo 7:46
Jòh. 18:9Jo 6:39; 17:12
Jòh. 18:10Mt 26:51; Mk 14:47; Lk 22:50
Jòh. 18:11Mt 26:52; Lk 22:51; Jo 18:36
Jòh. 18:11Mt 20:22; 26:42
Jòh. 18:13Lk 3:2; Iṣe 4:5, 6
Jòh. 18:13Mt 26:57; Jo 18:24
Jòh. 18:14Jo 11:49, 50
Jòh. 18:15Mt 26:58; Mk 14:54; Lk 22:54
Jòh. 18:17Mt 26:69, 70; Mk 14:66-68; Lk 22:55-57; Jo 18:25
Jòh. 18:20Mt 26:55; Lk 4:15; 19:47; Jo 7:14
Jòh. 18:22Ais 50:6
Jòh. 18:24Mt 26:57
Jòh. 18:25Mt 26:69, 70; Mk 14:69, 70; Lk 22:58
Jòh. 18:26Jo 18:10
Jòh. 18:27Mt 26:74; Mk 14:72; Lk 22:60; Jo 13:38
Jòh. 18:28Mt 27:2; Mk 15:1; Lk 23:1
Jòh. 18:28Iṣe 10:28
Jòh. 18:31Jo 19:6
Jòh. 18:31Jo 19:10
Jòh. 18:32Mt 20:18, 19; Jo 3:14; 12:32
Jòh. 18:33Mt 27:11; Jo 12:13
Jòh. 18:361Ti 6:13
Jòh. 18:36Ais 9:6; Da 2:44; 7:14
Jòh. 18:36Mt 26:52, 53; Jo 18:11
Jòh. 18:37Mt 27:11
Jòh. 18:37Jo 1:14, 17; 14:6
Jòh. 18:38Mt 27:24; Lk 23:4; Jo 15:25
Jòh. 18:39Mt 27:15; Mk 15:6
Jòh. 18:40Nọ 35:31; Lk 23:18, 19; Iṣe 3:14
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
  • 15
  • 16
  • 17
  • 18
  • 19
  • 20
  • 21
  • 22
  • 23
  • 24
  • 25
  • 26
  • 27
  • 28
  • 29
  • 30
  • 31
  • 32
  • 33
  • 34
  • 35
  • 36
  • 37
  • 38
  • 39
  • 40
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Jòhánù 18:1-40

Àkọsílẹ̀ Jòhánù

18 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí òdìkejì Àfonífojì Kídírónì,*+ níbi tí ọgbà kan wà, òun àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì wọnú ibẹ̀.+ 2 Júdásì, ẹni tó dà á náà mọ ibẹ̀, torí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sábà máa ń pàdé níbẹ̀. 3 Torí náà, Júdásì kó àwùjọ àwọn ọmọ ogun àti àwọn òṣìṣẹ́ ti àwọn olórí àlùfáà àtàwọn Farisí, wọ́n sì wá síbẹ̀, tàwọn ti ògùṣọ̀, fìtílà àti ohun ìjà.+ 4 Jésù mọ gbogbo ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun, torí náà, ó bọ́ síwájú, ó sì sọ fún wọn pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” 5 Wọ́n dá a lóhùn pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.”+ Ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni.” Júdásì, ẹni tó dà á náà wà ní ìdúró pẹ̀lú wọn.+

6 Àmọ́ nígbà tí Jésù sọ fún wọn pé, “Èmi ni,” wọ́n sún mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì ṣubú lulẹ̀.+ 7 Torí náà, ó tún bi wọ́n pé: “Ta lẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní: “Jésù ará Násárẹ́tì ni.” 8 Jésù dáhùn pé: “Mo ti sọ fún yín pé èmi ni. Torí náà, tó bá jẹ́ èmi lẹ̀ ń wá, ẹ fi àwọn yìí sílẹ̀.” 9 Èyí jẹ́ torí kí ohun tó sọ lè ṣẹ, pé: “Mi ò pàdánù ìkankan nínú àwọn tí o fún mi.”+

10 Ni Símónì Pétérù tó ní idà bá fà á yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó gé etí rẹ̀ ọ̀tún dà nù.+ Málíkọ́sì ni orúkọ ẹrú náà. 11 Àmọ́ Jésù sọ fún Pétérù pé: “Fi idà náà sínú àkọ̀ rẹ̀.+ Ṣé kò yẹ kí n mu ife tí Baba fún mi ni?”+

12 Àwọn ọmọ ogun náà àti ọ̀gágun àti àwọn aláṣẹ àwọn Júù wá mú* Jésù, wọ́n sì dè é. 13 Wọ́n kọ́kọ́ mú un lọ sọ́dọ̀ Ánásì, torí òun ni bàbá ìyàwó Káyáfà,+ tó jẹ́ àlùfáà àgbà lọ́dún yẹn.+ 14 Ní tòótọ́, Káyáfà ló gba àwọn Júù nímọ̀ràn pé ó máa ṣe wọ́n láǹfààní kí ọkùnrin kan kú torí àwọn èèyàn.+

15 Símónì Pétérù àti ọmọ ẹ̀yìn míì ń tẹ̀ lé Jésù.+ Àlùfáà àgbà mọ ọmọ ẹ̀yìn yẹn, ó sì bá Jésù lọ sínú àgbàlá àlùfáà àgbà, 16 àmọ́ Pétérù dúró síta níbi ilẹ̀kùn.* Torí náà, ọmọ ẹ̀yìn kejì, tí àlùfáà àgbà mọ̀, jáde lọ bá aṣọ́nà sọ̀rọ̀, ó sì mú Pétérù wọlé. 17 Ìránṣẹ́bìnrin tó jẹ́ aṣọ́nà wá sọ fún Pétérù pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn ọkùnrin yìí ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sọ pé: “Rárá o.”+ 18 Àwọn ẹrú àti àwọn òṣìṣẹ́ dúró yí ká iná èédú tí wọ́n dá, torí pé òtútù mú, wọ́n sì ń yáná. Pétérù náà dúró síbẹ̀, ó sì ń yáná.

19 Torí náà, olórí àlùfáà bi Jésù léèrè nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 20 Jésù dá a lóhùn pé: “Mo ti bá ayé sọ̀rọ̀ ní gbangba. Gbogbo ìgbà ni mò ń kọ́ni nínú sínágọ́gù àti nínú tẹ́ńpìlì,+ níbi tí gbogbo àwọn Júù ń kóra jọ sí; mi ò sì sọ ohunkóhun ní ìkọ̀kọ̀. 21 Kí ló dé tí ò ń bi mí? Bi àwọn tí wọ́n gbọ́ ohun tí mo sọ fún wọn. Wò ó! Àwọn yìí mọ ohun tí mo sọ.” 22 Lẹ́yìn tó sọ àwọn nǹkan yìí, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tó dúró nítòsí gbá Jésù létí,+ ó sì sọ pé: “Ṣé bí o ṣe máa dá olórí àlùfáà lóhùn nìyẹn?” 23 Jésù dá a lóhùn pé: “Tó bá jẹ́ ohun tí kò tọ́ ni mo sọ, jẹ́rìí nípa* ohun tí kò tọ́ náà; àmọ́ tó bá jẹ́ ohun tó tọ́ ni mo sọ, kí ló dé tí o fi gbá mi?” 24 Ánásì wá dè é, ó sì ní kí wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ Káyáfà àlùfáà àgbà.+

25 Símónì Pétérù wà lórí ìdúró níbẹ̀, ó ń yáná. Wọ́n wá sọ fún un pé: “Ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?” Ó sẹ́, ó sì sọ pé: “Rárá o.”+ 26 Ọ̀kan lára àwọn ẹrú àlùfáà àgbà, tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ọkùnrin tí Pétérù gé etí rẹ̀ dà nù+ sọ pé: “Mo rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọgbà, àbí mi ò rí ọ?” 27 Àmọ́ Pétérù tún sẹ́, àkùkọ sì kọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.+

28 Wọ́n wá mú Jésù látọ̀dọ̀ Káyáfà lọ sí ilé gómìnà.+ Àárọ̀ kùtù ni. Àmọ́ àwọn fúnra wọn ò wọnú ilé gómìnà, kí wọ́n má bàa sọ ara wọn di aláìmọ́,+ kí wọ́n lè jẹ Ìrékọjá. 29 Torí náà, Pílátù jáde wá bá wọn, ó sì sọ pé: “Ẹ̀sùn wo lẹ fi kan ọkùnrin yìí?” 30 Wọ́n dáhùn pé: “Ká ní ọkùnrin yìí ò ṣe ohun tí kò dáa ni,* a ò ní fà á lé ọ lọ́wọ́.” 31 Pílátù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ̀yin fúnra yín ẹ mú un, kí ẹ sì fi òfin yín dá a lẹ́jọ́.”+ Àwọn Júù sọ fún un pé: “Kò bófin mu fún wa láti pa ẹnikẹ́ni.”+ 32 Èyí jẹ́ torí kí ọ̀rọ̀ Jésù lè ṣẹ, èyí tó sọ kí wọ́n lè mọ irú ikú tí òun máa tó kú.+

33 Torí náà, Pílátù tún wọnú ilé gómìnà, ó pe Jésù, ó sì bi í pé: “Ṣé ìwọ ni Ọba Àwọn Júù?”+ 34 Jésù dáhùn pé: “Ṣé ìwọ lo ronú ìbéèrè yìí fúnra rẹ, àbí àwọn míì ló sọ ọ̀rọ̀ mi fún ọ?” 35 Pílátù dáhùn pé: “Èmi kì í ṣe Júù, àbí Júù ni mí? Àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè rẹ àti àwọn olórí àlùfáà ló fà ọ́ lé mi lọ́wọ́. Kí lo ṣe?” 36 Jésù dáhùn pé:+ “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí.+ Ká ní Ìjọba mi jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ìránṣẹ́ mi ì bá ti jà kí wọ́n má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ́.+ Àmọ́, bó ṣe rí yìí, Ìjọba mi ò wá láti orísun yìí.” 37 Pílátù wá bi í pé: “Ó dáa, ṣé ọba ni ọ́?” Jésù dáhùn pé: “Ìwọ fúnra rẹ ń sọ pé ọba ni mí.+ Torí èyí la ṣe bí mi, torí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.+ Gbogbo ẹni tó bá fara mọ́ òtítọ́ ń fetí sí ohùn mi.” 38 Pílátù wá bí i pé: “Kí ni òtítọ́?”

Lẹ́yìn tó sọ èyí, ó tún jáde lọ bá àwọn Júù, ó sì sọ fún wọn pé: “Mi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.+ 39 Àmọ́, ẹ ní àṣà kan, pé kí n máa tú ẹnì kan sílẹ̀ fún yín nígbà Ìrékọjá.+ Torí náà, ṣé ẹ fẹ́ kí n tú Ọba Àwọn Júù sílẹ̀ fún yín?” 40 Wọ́n bá tún kígbe pé: “A ò fẹ́ ọkùnrin yìí, Bárábà la fẹ́!” Àmọ́ olè ni Bárábà.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́