ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 53
  • Ìlérí Jẹ́fútà

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìlérí Jẹ́fútà
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ó Mú Inú Bàbá Rẹ̀ àti Inú Jèhófà Dùn
    Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Ọlọ́run Fẹ́ràn Rẹ̀, Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ sì Fẹ́ràn Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Tá A Bá Jẹ́ Olóòótọ́, A Máa Rí Ojúure Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 53
Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ń lu ìlú tanboríìnì bó ṣe ń jáde wá pàdé bàbá rẹ̀

ÌTÀN 53

Ìlérí Jẹ́fútà

ǸJẸ́ o ti ṣèlérí kan rí tó o wá rí nígbà tó yá pé ó ṣòroó mú ṣẹ? Irú ẹ̀ ló ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin tó wà nínú àwòrán yìí, ìdí sì nìyí tó fi banú jẹ́ gidigidi. Onídàájọ́ kan ní Ísírẹ́lì tó nígboyà ni ọkùnrin náà, Jẹ́fútà ni orúkọ rẹ̀.

Jẹ́fútà gbé ayé ní àkókò kan táwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún kọ̀ láti máa jọ́sìn Jèhófà. Wọ́n tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ohun tó burú. Nítorí náà, Jèhófà jẹ́ káwọn ará Ámónì bẹ̀rẹ̀ sí i fojú wọn gbolẹ̀. Èyí ló mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì ké pe Jèhófà pé: ‘Àwa ti ṣẹ̀ sí ọ. Jọ̀wọ́ gbà wá!’

Inú àwọn èèyàn náà bà jẹ́ nítorí ohun búburú tí wọ́n ti ṣe. Wọ́n fi hàn pé àwọn kábàámọ̀ ohun búburú tí àwọn ṣe nípa ríronú pìwà dà láti máa sin Jèhófà lẹ́ẹ̀kan sí i. Nítorí náà, Jèhófà tún ràn wọ́n lọ́wọ́.

Jẹ́fútà làwọn èèyàn náà yàn láti bá àwọn ará Ámónì búburú náà jagun. Jẹ́fútà fẹ́ kí Jèhófà ran òun lọ́wọ́ gidigidi nínú ìjà náà. Nítorí náà, ó ṣèlérí fún Jèhófà pé: ‘Bó o bá lè jẹ́ kí n ṣẹ́gun àwọn ará Ámónì, ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ jáde láti inú ilé mi láti pàdé mi nígbà tí mo bá ń padà bọ̀ láti ibi ìṣẹ́gun náà ni màá fi fún ọ.’

Inú Jẹ́fútà bà jẹ́ bó ṣe rí i pé ọmọbìnrin òun ló kọ́kọ́ wá pàdé òun

Jèhófà fetí sí ìlérí tí Jẹ́fútà ṣe, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun. Nígbà tí Jẹ́fútà ń padà bọ̀ wá sílé, ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ jáde wá pàdé rẹ̀? Ọmọbìnrin rẹ̀ tí í ṣe ọmọ kan ṣoṣo tó bí ni. Jẹ́fútà kígbe pé: ‘Yéè, ọmọbìnrin mi! Ìbànújẹ́ ńláǹlà lo kó bá mi yìí. Ṣùgbọ́n mo ti ṣèlérí fún Jèhófà, mi ò sì lè má mu un ṣẹ.’

Nígbà tí ọmọbìnrin Jẹ́fútà gbọ́ ìlérí tí bàbá rẹ̀ ṣe, lákọ̀ọ́kọ́ inú tiẹ̀ náà bà jẹ́. Nítorí ó túmọ̀ sí pé ó ní láti fi bàbá rẹ̀ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà ni yóò fi gbogbo ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ máa sìn nínú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà tó wà ní Ṣílò. Nítorí náà, ó wí fún bàbá rẹ̀ pé: ‘Bẹ́ ẹ bá ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ ò gbọ́dọ̀ má mu un ṣẹ.’

Bí ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe lọ sí Ṣílò nìyẹn o tó sì lo gbogbo ìyókù ayé rẹ̀ fún sísin Jèhófà nínú àgọ́ ìjọsìn rẹ̀. Ọjọ́ mẹ́rin nínú ọdún làwọn obìnrin Ísírẹ́lì máa fi ń lọ kí i níbẹ̀, wọ́n sì jùmọ̀ máa ń gbádùn ara wọn. Àwọn èèyàn náà fẹ́ràn ọmọbìnrin Jẹ́fútà nítorí tí òun jẹ́ ìránṣẹ́ rere fún Jèhófà.

Àwọn Onídàájọ́ 10:6-18; 11:1-40.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́