ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yc ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 10-11
  • Ó Mú Inú Bàbá Rẹ̀ àti Inú Jèhófà Dùn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Mú Inú Bàbá Rẹ̀ àti Inú Jèhófà Dùn
  • Kọ́ Ọmọ Rẹ
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọlọ́run Fẹ́ràn Rẹ̀, Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ̀ sì Fẹ́ràn Rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
  • Ìlérí Jẹ́fútà
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Tá A Bá Jẹ́ Olóòótọ́, A Máa Rí Ojúure Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2016
  • Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
Àwọn Míì
Kọ́ Ọmọ Rẹ
yc ẹ̀kọ́ 4 ojú ìwé 10-11
Jẹ́fútà ń bá ọmọbìnrin rẹ̀ ṣeré nígbà tó wà ní kékeré

Ẹ̀kọ́ 4

Ó Mú Inú Bàbá Rẹ̀ Àti Inú Jèhófà Dùn

Jẹ́fútà ń gbàdúrà nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń bá àwọn ọ̀tá wọn jà

Ìlérí wo ni Jẹ́fútà ń ṣe fún Jèhófà?

Jẹ́fútà gbá ọmọbìnrin rẹ̀ mọ́ra lẹ́yìn tó ti ojú ogun dé

Kò rọrùn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà rárá, àmọ́ ó ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ ṣèlérí fún Jèhófà

Ṣé o rí ọmọbìnrin tó wà nínú àwòrán yìí?— Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jẹ́fútà ni bàbá rẹ̀. Bíbélì kò sọ orúkọ ọmọbìnrin yìí fún wa, àmọ́ ohun tá a mọ̀ ni pé ó mú inú bàbá rẹ̀ àti inú Jèhófà dùn. Jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti Jẹ́fútà bàbá rẹ̀.

Ẹni rere ni Jẹ́fútà, ó máa ń lo ọ̀pọ̀ àkókò láti kọ́ ọmọ rẹ̀ nípa Jèhófà. Ó lágbára gan-an, aṣáájú rere sì ni. Torí náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ pé kó ṣáájú àwọn, kí wọ́n lè lọ bá àwọn ọ̀tá wọn jà.

Jẹ́fútà gbàdúrà sí Ọlọ́run, pé kó jẹ́ kí òun ṣẹ́gun. Ó wá ṣèlérí pé tí òun bá ṣẹ́gun, ẹni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé òun ni òun máa fún Jèhófà. Gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ni ẹni yẹn á fi máa gbé nínú àgọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, tí á sì máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Inú ibi tí àwọn èèyàn ti máa ń lọ jọ́sìn Ọlọ́run nígbà yẹn ló ń jẹ́ àgọ́ ìjọsìn. Lọ́rọ̀ kan, Jẹ́fútà ṣẹ́gun nínú ìjà náà! Ǹjẹ́ o mọ ẹni tó kọ́kọ́ jáde nínú ilé rẹ̀ nígbà tó pa dà dé ilé?—

Bẹ́ẹ̀ ni, ọmọbìnrin Jẹ́fútà ni! Ọmọ kan ṣoṣo tó ní nìyẹn, àmọ́ ní báyìí ó gbọ́dọ̀ rán ọmọ náà lọ. Inú Jẹ́fútà kò dùn rárá. Ṣùgbọ́n o, rántí pé ó ti ṣèlérí tẹ́lẹ̀. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ọmọbìnrin rẹ̀ sọ pé, ‘Bàbá mi, ẹ ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ ní láti mú ìlérí yín ṣẹ.’

Ọmọbìnrin Jẹ́fútà ń kó igi tí wọ́n á lò ní àgọ́ ìjọsìn jọ; àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ wá kí i

Lọ́dọọdún, àwọn ọ̀rẹ́ ọmọbìnrin Jẹ́fútà máa ń lọ sọ́dọ̀ rẹ̀

Inú ọmọbìnrin Jẹ́fútà náà kò dùn. Tó bá lọ sí àgọ́ ìjọsìn, kò ní lọ́kọ, kò sì ní bímọ. Àmọ́ ó gbà láti ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ sọ, kí ó lè mú inú Jèhófà dùn. Ó gbà pé ìyẹn ṣe pàtàkì sí òun ju ọkọ tàbí ọmọ lọ. Torí náà, ó kúrò nílé, gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀ ló sì fi gbé nínú àgọ́ ìjọsìn.

Ǹjẹ́ o rò pé ohun tó ṣe yẹn mú inú bàbá rẹ̀ àti inú Jèhófà dùn?— Bẹ́ẹ̀ ni o, inú wọn dùn! Tí ìwọ náà bá jẹ́ onígbọràn tí o sì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà bíi ti ọmọbìnrin Jẹ́fútà, wàá mú inú àwọn òbí rẹ àti inú Jèhófà dùn.

KÀ Á NÍNÚ BÍBÉLÌ RẸ

  • Diutarónómì 6:4-6

  • Onídàájọ́ 11:30-40

  • 1 Kọ́ríńtì 7:37, 38

ÌBÉÈRÈ:

  • Irú ẹni wo ni Jẹ́fútà jẹ́? Ìlérí wo ló ṣe?

  • Kí nìdí tí kò fi rọrùn fún ọmọbìnrin Jẹ́fútà láti ṣe ohun tí bàbá rẹ̀ ṣèlérí?

  • Báwo ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ṣe mú inú bàbá rẹ̀ dùn?

  • Kí la rí kọ́ lára ọmọbìnrin Jẹ́fútà?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́