Ẹ̀KỌ́ 36
Ìlérí Tí Jẹ́fútà Ṣe
Nígbà tó yá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tún fi Jèhófà sílẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bọ òrìṣà. Nígbà táwọn ọmọ Ámónì bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jà, àwọn òrìṣà yẹn ò ràn wọ́n lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi jìyà. Wọ́n wá sọ fún Jèhófà pé: ‘A ti dẹ́ṣẹ̀. Jọ̀ọ́ gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.’ Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó àwọn òrìṣà wọn dànù, wọ́n sì pa dà bẹ̀rẹ̀ sí í jọ́sìn Jèhófà. Inú Jèhófà ò dùn bí ìyà ṣe ń jẹ wọ́n.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá yan jagunjagun kan tó ń jẹ́ Jẹ́fútà láti ṣáájú wọn kí wọ́n lè lọ gbógun ja àwọn ọmọ Ámónì. Jẹ́fútà sọ fún Jèhófà pé: ‘Tó o bá jẹ́ ká ṣẹ́gun, mo ṣèlérí pé tí mo bá pa dà délé, ẹnikẹ́ni tó bá kọ́kọ́ jáde wá pàdé mi ni màá yọ̀ǹda fún ẹ.’ Jèhófà gbọ́ àdúrà Jẹ́fútà, ó sì jẹ́ kó borí ogun náà.
Nígbà tí Jẹ́fútà pa dà délé, ọmọbìnrin ẹ̀ ló kọ́kọ́ jáde wá pàdé ẹ̀, òun sì ni ọmọ kan ṣoṣo tó bí. Ó ń jó, ó sì ń lu ìlù tanboríìnì. Kí ni Jẹ́fútà máa ṣe báyìí? Ó rántí ìlérí tó ṣe, ó sì sọ pé: ‘Áà ọmọbìnrin mi! O ti bà mí lọ́kàn jẹ́. Mo ṣèlérí fún Jèhófà. Kí n lè mú ìlérí náà ṣẹ, mo gbọ́dọ̀ rán ẹ lọ sí àgọ́ ìjọsìn ní Ṣílò, kó o lè lọ sìn níbẹ̀.’ Ọmọbìnrin ẹ̀ wá sọ fún un pé: ‘Bàbá mi, tẹ́ ẹ bá ti ṣèlérí fún Jèhófà, ẹ gbọ́dọ̀ mú ìlérí yín ṣẹ. Àmọ́, ẹ fún mi lóṣù méjì, kí n lè wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi lórí àwọn òkè. Lẹ́yìn náà, màá lọ.’ Àgọ́ ìjọsìn ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà ti sìn ní gbogbo ọjọ́ ayé ẹ̀, tọkàntọkàn ló sì fi sin Jèhófà níbẹ̀. Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ̀ sì máa ń lọ kí i ní Ṣílò lọ́dọọdún.
‘Ẹnikẹ́ni tó bá nífẹ̀ẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin jù mí lọ kò yẹ fún mi.’—Mátíù 10:37