ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 98
  • Lórí Òkè Ólífì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Lórí Òkè Ólífì
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Pa Dà sí Ọ̀run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Mímú Àwọn Ọjọ́ Tí Jésù Lò Kẹ́yìn Lórí Ilẹ̀ Ayé Wá sí Ìrántí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • “Wákàtí Náà Ti Dé!”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Jésù Padà Sọ́run
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 98
Jésù bá díẹ̀ lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sọ̀rọ̀ lórí Òkè Ólífì

ÌTÀN 98

Lórí Òkè Ólífì

JÉSÙ nìyí lórí Òkè Ólífì. Àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ni ọkùnrin mẹ́rin tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ yẹn. Àwọn ni Áńdérù àti Pétérù tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù táwọn náà jẹ́ tẹ̀gbọ́n-tàbúrò. Tẹ́ńpìlì Ọlọ́run tó wà ní Jerúsálẹ́mù lò ń wò lọ́ọ̀ọ́kán yẹn.

Tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù

Ọjọ́ méjì sẹ́yìn ni Jésù gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ Jerúsálẹ́mù. Ọjọ́ Tuesday ni ọjọ́ yìí. Ibẹ̀ ni àwọn àlùfáà ti gbìyànjú láti mú Jésù, kí wọ́n sì pa á. Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà wọ́n torí pé àwọn èèyàn fẹ́ràn Jésù.

Jésù pe àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn ní, ‘Ẹ̀yin ejò àti ọmọ ejò!’ Ìgbà náà ni Jésù sọ pé Ọlọ́run á fi ìyà jẹ wọ́n nítorí gbogbo búburú tí wọ́n ti ṣe. Lẹ́yìn èyí ni Jésù wá sórí Òkè Ólífì, ni àwọn àpọ́sítélì mẹ́rin wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àwọn ìbéèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ǹjẹ́ o mọ ohun tí wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ Jésù?

Àwọn àpọ́sítélì béèrè nípa àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Wọ́n mọ̀ pé Jésù máa fi òpin sí ìwà búburú gbogbo láyé. Ṣùgbọ́n wọ́n fẹ́ mọ ìgbà tí nǹkan wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀. Ìgbà wo ni Jésù máa padà wá láti wá ṣàkóso bí Ọba?

Jésù mọ̀ pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ò ní rí òun nígbà tí òun bá padà dé. Ìdí ni pé ọ̀run ló máa wà kò sì ní ṣeé ṣe láti rí i níbẹ̀. Nítorí náà, Jésù sọ díẹ̀ lára àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà tó bá ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba ní ọ̀run fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyí?

Jésù sọ pé àwọn ogun ńláńlá á máa jà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ á máa ṣàìsàn tí ebi á sì máa pa wọ́n, ìwà ọ̀daràn á peléke sí i, ilẹ̀ á sì máa mì jìgìjìgì. Jésù tún sọ pé a ó wàásù ìhìn rere nípa ìjọba Ọlọ́run níbi gbogbo lórí ilẹ̀ ayé. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí ti ń ṣẹlẹ̀ lákòókò wa? Bẹ́ẹ̀ ni! Nítorí náà, ó dá wa lójú pé Jésù ti ń ṣàkóso ní ọ̀run báyìí. Láìpẹ́ ó máa fòpin sí gbogbo ìwà búburú tó ń ṣẹlẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.

Mátíù 21:46; 23:1-39; 24:1-14; Máàkù 13:3-10.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́