Ẹ̀KỌ́ 93
Jésù Pa Dà sí Ọ̀run
Nígbà tí Jésù wà pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ní Gálílì, ó gbé iṣẹ́ pàtàkì kan lé wọn lọ́wọ́. Ó pàṣẹ fún wọn pé: ‘Ẹ lọ, kẹ́ ẹ sì máa sọ àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn. Ẹ máa kọ́ wọn ní ohun tí mo ti kọ́ ọ yín, kẹ́ ẹ sì ṣèrìbọmi fún wọn.’ Jésù wá ṣèlérí pé, ‘òun máa wà pẹ̀lú wọn.’
Láàárín ogójì (40) ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jí dìde, ó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó pọ̀ ní Gálílì àti Jerúsálẹ́mù. Ó kọ́ wọn láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì, ó sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Àwọn àpọ́sítélì ẹ̀ wá bá a lórí Òkè Ólífì fúngbà ìkẹyìn, ó sì sọ fún wọn pé: ‘Ẹ dúró ní Jerúsálẹ́mù kẹ́ ẹ sì máa retí ohun tí Baba ṣèlérí.’
Àmọ́ ohun tó ń sọ ò yé àwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Wọ́n wá béèrè pé: ‘Ṣó o ti fẹ́ di Ọba Ísírẹ́lì báyìí ni?’ Jésù dáhùn pé: ‘Kò tíì tó àkókò tí Jèhófà yàn fún mi láti di Ọba. Ṣùgbọ́n láìpẹ́, ẹ̀mí mímọ́ máa fún yín lágbára, ẹ ò sì máa wàásù nípa mi. Torí náà, ẹ lọ máa wàásù ní Jerúsálẹ́mù, Jùdíà, Samáríà àtàwọn apá ibi tó jìnnà jù láyé.’
Lẹ́yìn náà, Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í gòkè lọ sí ọ̀run títí ìkùukùu fi bò ó. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá tẹ́jú mọ́ òkè, àmọ́ wọn ò rí i mọ́.
Àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà wá kúrò lórí Òkè Ólífì, wọ́n sì lọ sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n máa ń pàdé pọ̀ déédéé láti gbàdúrà nínú yàrá òkè nílé kan. Wọ́n ń dúró de Jésù kó wá sọ ohun tí wọ́n máa ṣe.
“A ó sì wàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, kó lè jẹ́ ẹ̀rí fún gbogbo orílẹ̀-èdè, nígbà náà ni òpin yóò dé.”—Mátíù 24:14