ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 5/1 ojú ìwé 8-9
  • Awọn Ifarahan Ikẹhin, Ati Pẹntikọsti 33 C.E.

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Awọn Ifarahan Ikẹhin, Ati Pẹntikọsti 33 C.E.
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ifarahan Ikẹhin, ati Pẹntikọsi 33 C.E.
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ló Rí Jésù Ṣáájú Ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Jésù Pa Dà sí Ọ̀run
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • “Ẹ Ó sì Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Mi”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 5/1 ojú ìwé 8-9

Igbesi-aye ati Iṣẹ-ojiṣẹ Jesu

Awọn Ifarahan Ikẹhin, Ati Pẹntikọsti 33 C.E.

NI AWỌN akoko kan Jesu ṣeto fun gbogbo awọn aposteli rẹ mọkanla lati pade rẹ lori oke kan ni Galili. Awọn ọmọ-ẹhin miiran ni o farahan pe a sọ fun nipa ipade naa, apapọ awọn eniyan ti wọn ju 500 ni wọn si pejọ. Iru apejọpọ alayọ wo ni eyi jasi nigba ti Jesu farahan ti o si bẹrẹ sii kọ́ wọn!

Laaarin awọn nnkan miiran, Kristi ṣalaye fun awọn ogunlọgọ titobi naa pe Ọlọrun ti fun oun ni gbogbo aṣẹ ni ọrun ati ni ori ilẹ-aye. O gba wọn niyanju pe, “Ẹ lọ ki ẹ si sọ awọn eniyan gbogbo orilẹ-ede di ọmọ-ẹhin, ki ẹ maa baptisi wọn ni orukọ Baba ati ti Ọmọkunrin ati ti ẹmi mimọ, ki ẹ maa kọ wọn lẹkọọ lati kiyesi ohun gbogbo ti mo ti palaṣẹ fun yin.”

Ro o wò ná! Awọn ọkunrin, obinrin, ati awọn ọmọde gbogbo wọn gba iṣẹ kan naa yii lati ṣajọpin ninu iṣẹ sisọni di ọmọ-ẹhin. Awọn alatako yoo gbiyanju lati dá wiwaasu ati kikọni wọn duro, ṣugbọn Jesu tù wọn ninu pe: ‘Ẹ wòó! Emi wà pẹlu yin ni gbogbo ọjọ titi de ipari opin eto awọn nnkan.’ Jesu wà pẹlu awọn ọmọlẹhin rẹ nipasẹ ẹmi mimọ, lati ran wọn lọwọ lati mu iṣẹ-ojiṣẹ wọn ṣẹ.

Jesu fi ara rẹ̀ hàn láàyè fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ fun sáà akoko 40 ọjọ tẹle ajinde rẹ̀. Laaarin awọn ifarahan wọnyi, o fun wọn ni itọni nipa Ijọba Ọlọrun, o tẹnumọ ohun ti awọn ẹru-iṣẹ wọn jẹ́ gẹgẹ bi ọmọ-ẹhin rẹ̀. Ni akoko kan o tilẹ farahan Jakọbu ọmọ iya rẹ o si mu dá alaigbagbọ tẹlẹri yii loju pe Oun nitootọ ni Kristi.

Nigba ti awọn aposteli ṣi wà ni Galili, lọna ti o hàn gbangba Jesu fun wọn ni itọni lati pada si Jerusalẹmu. Nigba ti o npade pọ pẹlu wọn nibẹ, o sọ fun wọn pe: “Ẹ maṣe kuro ni Jerusalẹmu, ṣugbọn ẹ maa duro de ohun ti Baba ti ṣeleri, eyi ti ẹ gbọ nipa rẹ lẹnu mi; nitori Johanu, nitootọ, fi omi baptisi, ṣugbọn a o fi ẹmi mimọ baptisi yin kii ṣe ni ọjọ pupọ lẹhin eyi.”

Lẹhin naa Jesu pade pọ̀ pẹlu awọn aposteli rẹ lẹẹkansi o si ṣamọna wọn jade kuro ni ilu lọ jinna titi de Bẹtani, eyi ti o wà lori gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ iha ila-oorun Oke Olifi. Lọna ti o yanilẹnu, laika ohun gbogbo ti o ti sọ nipa gbigbera lọ si ọrun rẹ laipẹ si, sibẹ wọn gbagbọ pe Ijọba rẹ ni a o fi idi rẹ mulẹ lori ilẹ-aye. Nitori naa wọn beere pe: “Oluwa, iwọ ha nda ijọba naa padabọsipo fun Israẹli ni akoko yii bi?”

Dipo gbigbiyanju lẹẹkansii lati tun aṣiloye wọn ṣe, Jesu wulẹ dahun pe: “Kii ṣe ti yin lati ni imọ awọn akoko tabi awọn asiko ti Baba ti fi si abẹ aṣẹ oun tikaaraarẹ.” Lẹhin naa, ni titẹnumọ iṣẹ ti wọn gbọdọ ṣe lẹẹkansi, o wipe: “Ẹyin yoo gba agbara nigba ti ẹmi mimọ ba de sori yin, ẹ o si jẹ ẹlẹrii mi ni Jerusalẹmu ati ni gbogbo Judia ati Samaria ati titi de ibi ti o jinna julọ ni ilẹ-aye.”

Nigba ti wọn si nwo o, Jesu bẹrẹ sii gbera soke si iha ọrun, ati lẹhin naa awọ sanmọ bo o kuro loju wọn. Lẹhin bibọ ara ẹran rẹ kalẹ, oun goke re ọrun gẹgẹbi ẹni ẹmi kan. Bi awọn mọkanla naa ti nbaa lọ ni bibojuwo oke awọ sanmọ, awọn ọkunrin meji ti wọn wọ ẹwu funfun farahan lẹgbẹẹ wọn. Awọn angẹli ti wọn gbe awọ eniyan wọ wọnyi beere pe: “Ẹyin eniyan Galili, eeṣe ti ẹ fi duro nwoju oke ọrun? Jesu yii ti a gbà soke kuro lọdọ yin si oju ọ̀run yoo wá bayii ni iru ọna kan naa bi ẹ ti ri ti nlọ si oju ọrun.”

Iru ọna eyi ti Jesu ṣẹṣẹ gbà fi ilẹ-aye silẹ jẹ laisi afẹfẹyẹyẹ itagbangba, awọn ọmọlẹhin rẹ oluṣotitọ nikan ni wọn si nkiyesi. Nitori naa oun yoo pada ni iru ọna kan naa—laisi afẹfẹyẹyẹ itagbangba, awọn ọmọlẹhin rẹ oluṣotitọ nikan ni foye mọ pe o ti pada o si ti bẹrẹ wiwà nihin in rẹ ninu agbara Ijọba.

Nisinsinyi awọn aposteli naa sọkalẹ lọ si isalẹ Oke Olifi, wọn la afonifoji Kidroni kọja, wọn si wọnu Jerusalẹmu lẹẹkansi. Wọn wa nibẹ ni igbọran si aṣẹ Jesu. Ọjọ mẹwaa lẹhin naa, nigba Ayẹyẹ awọn Juu ti Pẹntikọsti 33 C.E.. nigba ti nnkan bi 120 awọn ọmọ-ẹhin pejọ ninu yara oke ni Jerusalẹmu, ariwo kan gan an bii afẹfẹ iji lile bo ile naa lojiji. Awọn ahọn ti o dabi ti ina farahan, o si bà lori ọkọọkan awọn wọnni ti wọn wà nibẹ, gbogbo awọn ọmọ-ẹhin naa si bẹrẹ si sọ oniruuru ede. Eyi ni itujade ẹmi mimọ ti Jesu ti ṣeleri! Matiu 28:16-20, NW; Luuku 24:49-52, NW; 1 Kọrinti 15:5-7; Iṣe 1:3-15; 2:1-4, NW.

◆ Awọn wo ni Jesu fun ni itọni idagbere ni ori oke kan ni Galili, ki si ni awọn itọni wọnyi?

◆ Itunu wo ni Jesu pese fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, bawo ni oun yoo si ṣe wà pẹlu wọn?

◆ Bawo ni o ti pẹ to ti Jesu farahan awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lẹhin ajinde rẹ̀, ki ni o si fi kọ wọn?

◆ Ẹni wo, ti ko tii di ọmọ-ẹhin sibẹ ṣaaju iku Jesu, ni Jesu farahan fun?

◆ Awọn ipade ikẹhin meji wo ni Jesu ni pẹlu awọn aposteli rẹ, ki ni o si ṣẹlẹ ni awọn akoko wọnyi?

◆ Bawo ni o ti jẹ pe Jesu yoo pada ni iru ọna kan naa ti oun gba lọ?

◆ Ki ni o ṣẹlẹ ni Pẹntikọsti 33 C.E.?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́