ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 72
  • Ọlọ́run Ran Hesekáyà Ọba Lọ́wọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ọlọ́run Ran Hesekáyà Ọba Lọ́wọ́
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọba Kan Jẹ Èrè Ìgbàgbọ́ Rẹ̀
    Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà—Ìmọ́lẹ̀ fún Gbogbo Aráyé, Apá Kìíní
  • Ó Fún Wa Lómìnira Láti Ṣe Ohun Tó Wù Wá
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2010
  • Àwòkọ́ṣe—Hesekáyà
    Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì
  • Olùṣọ́ Àgùntàn Méje àti Mọ́gàjí Mẹ́jọ ti Òde Òní
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 72
Ọba Hesekáyà tẹ́ lẹ́tà tí ọba Ásíríà kọ sílẹ̀ níwájú pẹpẹ Jèhófà, ó sì ń gbàdúrà

ÌTÀN 72

Ọlọ́run Ran Hesekáyà Ọba Lọ́wọ́

ǸJẸ́ o mọ ìdí rẹ̀ tí ọkùnrin yìí fi ń gbàdúrà sí Jèhófà? Kí ló dé tó fi kó àwọn lẹ́tà wọ̀nyí síwájú pẹpẹ Jèhófà? Hesekáyà ni ọkùnrin yìí. Òun ni ọba ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjì tó wà ní gúúsù. Ó sì wà nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìṣòro. Kí ló ṣẹlẹ̀?

Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé àwọn ọmọ ogun Ásíríà ti pa ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà ní àríwá run. Jèhófà ló jẹ́ kó ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ torí pé àwọn èèyàn yẹn burú púpọ̀. Nísinsìnyí àwọn ọmọ ogun Ásíríà sì ti wá láti bá ìjọba ẹ̀yà méjì yìí jà.

Ọba Ásíríà ṣẹ̀ṣẹ̀ fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí Hesekáyà Ọba ni. Àwọn lẹ́tà yẹn ni Hesekáyà kó wá síwájú Ọlọ́run níhìn-ín. Ọ̀rọ̀ tó ń fi Jèhófà ṣẹ̀sín ló wà nínú àwọn lẹ́tà yẹn, wọ́n sì kọ ọ́ sínú lẹ́tà wọn pé kí Hesekáyà juwọ́ sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Hesekáyà fi gbàdúrà báyìí pé: ‘Jọ̀wọ́, Jèhófà, gbà wá lọ́wọ́ ọba Ásíríà. Èyí á jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè mọ̀ pé ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run.’ Ṣé Jèhófà máa gbọ́ àdúrà Hesekáyà?

Ọba dáadáa ni Hesekáyà. Òun ò dà bí àwọn ọba búburú tó jẹ lórí ìjọba ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá, tàbí bíi bàbá rẹ̀ Áhásì Ọba búburú. Hesekáyà ti ṣọ́ra láti ṣe ìgbọràn sí gbogbo òfin Jèhófà. Nítorí náà, lẹ́yìn tí Hesekáyà parí àdúrà rẹ̀, wòlíì Aísáyà rán iṣẹ́ yìí sí i láti ọ̀dọ̀ Jèhófà pé: ‘Ọba Ásíríà kò ní wọ inú Jerúsálẹ́mù. Kò sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ tó tiẹ̀ máa sún mọ́ ọn. Wọn ò ní ta ọfà kankan sí ìlú yìí.’

Àwọn ọmọ ogun Ásíríà kú sílẹ̀ ní ibùdó wọn

Wo àwòrán tó wà ní ojú ewé yìí. Ṣé o mọ ẹni táwọn ọmọ ogun tó kú wọ̀nyí jẹ́? Ará Ásíríà ni wọ́n. Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀, áńgẹ́lì yẹn sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [185,000] àwọn ọmọ ogun Ásíríà ní òru ọjọ́ kan ṣoṣo. Nítorí náà, ọba Ásíríà juwọ́ sílẹ̀ ó sì padà sí ilé.

Jèhófà gba ìjọba ẹ̀yà méjì náà là, àwọn èèyàn yẹn sì lálàáfíà fúngbà díẹ̀. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí Hesekáyà kú, Mánásè ọmọ Hesekáyà di ọba. Mánásè àti ọmọ rẹ̀ Ámónì tó jẹ lẹ́yìn rẹ̀ jẹ́ ọba tó burú gan-an. Nítorí náà, ilẹ̀ yẹn tún kún fún ẹ̀ṣẹ̀ dídá àti ìwà ipá lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ Ámónì Ọba pa á, Jòsáyà ọmọ rẹ̀ ni wọ́n fi jọba lórí ìjọba ẹ̀yà méjì.

2 Àwọn Ọba 18:1-36; 19:1-37; 21:1-25.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́