ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Sekaráyà 12
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Sekaráyà

      • Jèhófà yóò dáàbò bo Júdà àti Jerúsálẹ́mù (1-9)

        • Jerúsálẹ́mù yóò di “òkúta tó wúwo” (3)

      • Wọ́n ń pohùn réré ẹkún torí ẹni tí wọ́n gún (10-14)

Sekaráyà 12:1

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “èémí.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Job 26:7; Ais 42:5
  • +Sm 102:25; Ais 45:18

Sekaráyà 12:2

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “abọ́.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sek 14:14

Sekaráyà 12:3

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “òkúta tó jẹ́ ẹrù ìnira.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Sef 3:19
  • +Sek 14:2, 3

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 23

Sekaráyà 12:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 23-24

Sekaráyà 12:5

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Séríkí jẹ́ olóyè láàárín ẹ̀yà kan.

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:10; Joẹ 3:16; Sek 12:8

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 24-25

Sekaráyà 12:6

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “àyè tó tọ́ sí wọn.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 41:15
  • +Mik 4:13; Sek 9:15
  • +Sek 2:4

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 24-25

    12/1/2007, ojú ìwé 11

Sekaráyà 12:7

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹwà.”

  • *

    Tàbí “ẹwà.”

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 25

Sekaráyà 12:8

Àlàyé ìsàlẹ́ ìwé

  • *

    Tàbí “ẹni tó jẹ́ aláìlera jù lọ.”

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jer 23:6; Joẹ 3:16; Sek 2:5; 9:15
  • +Ẹk 14:19; 23:20

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 25

Sekaráyà 12:9

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ais 54:17; Hag 2:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/15/2007, ojú ìwé 25

Sekaráyà 12:10

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Jo 19:34, 37; 20:27; Ifi 1:7

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!, ẹ̀kọ́ 15

    Jésù—Ọ̀nà, ojú ìwé 303

    Ilé Ìṣọ́,

    8/15/2011, ojú ìwé 16

    Ọjọ́ Jèhófà, ojú ìwé 55

Sekaráyà 12:11

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Ọb 23:29; 2Kr 35:22

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́,

    12/1/2007, ojú ìwé 10

Sekaráyà 12:12

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +2Sa 5:13, 14; Lk 3:23, 31

Atọ́ka

  • Ìwé Ìwádìí

    Ilé Ìṣọ́ (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́),

    5/2019, ojú ìwé 30

Sekaráyà 12:13

Atọ́ka Àárín Ìwé

  • +Ẹk 6:16
  • +Ẹk 6:17; 1Kr 23:10

Àwọn míì

Sek. 12:1Job 26:7; Ais 42:5
Sek. 12:1Sm 102:25; Ais 45:18
Sek. 12:2Sek 14:14
Sek. 12:3Sef 3:19
Sek. 12:3Sek 14:2, 3
Sek. 12:5Ais 41:10; Joẹ 3:16; Sek 12:8
Sek. 12:6Ais 41:15
Sek. 12:6Mik 4:13; Sek 9:15
Sek. 12:6Sek 2:4
Sek. 12:8Jer 23:6; Joẹ 3:16; Sek 2:5; 9:15
Sek. 12:8Ẹk 14:19; 23:20
Sek. 12:9Ais 54:17; Hag 2:22
Sek. 12:10Jo 19:34, 37; 20:27; Ifi 1:7
Sek. 12:112Ọb 23:29; 2Kr 35:22
Sek. 12:122Sa 5:13, 14; Lk 3:23, 31
Sek. 12:13Ẹk 6:16
Sek. 12:13Ẹk 6:17; 1Kr 23:10
  • Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • 1
  • 2
  • 3
  • 4
  • 5
  • 6
  • 7
  • 8
  • 9
  • 10
  • 11
  • 12
  • 13
  • 14
Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Sekaráyà 12:1-14

Sekaráyà

12 Ìkéde:

“Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ nípa Ísírẹ́lì,”

Ọ̀rọ̀ Jèhófà, Ẹni tó na ọ̀run jáde,+

Tó fi ìpìlẹ̀ ayé lélẹ̀,+

Tó sì dá ẹ̀mí* sínú èèyàn.

2 “Èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di ife* tó ń mú kí gbogbo àwọn tó yí i ká ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́; wọn yóò sì gbógun ti Júdà àti Jerúsálẹ́mù.+ 3 Ní ọjọ́ yẹn, èmi yóò sọ Jerúsálẹ́mù di òkúta tó wúwo* fún gbogbo èèyàn. Ó dájú pé gbogbo àwọn tó bá gbé e máa fara pa yánnayànna;+ gbogbo orílẹ̀-èdè ayé sì máa kóra jọ láti gbéjà kò ó.+ 4 Jèhófà sọ pé, “Ní ọjọ́ yẹn, màá dẹ́rù ba gbogbo ẹṣin, màá sì mú kí orí ẹni tó ń gùn ún dà rú. Ojú mi yóò wà lára ilé Júdà, àmọ́ màá fọ́ ojú gbogbo ẹṣin àwọn èèyàn náà. 5 Àwọn séríkí* Júdà yóò sì sọ nínú ọkàn wọn pé, ‘Àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù ti fún wa lókun nípasẹ̀ Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun tó jẹ́ Ọlọ́run wọn.’+ 6 Ní ọjọ́ yẹn, màá ṣe àwọn séríkí Júdà bí ìkòkò iná láàárín igi àti bí ògùṣọ̀ oníná láàárín ìtí ọkà+ tí wọ́n tò jọ, wọn yóò sì jó gbogbo èèyàn tó wà yí ká run ní ọ̀tún àti ní òsì;+ àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù yóò sì pa dà sí àyè wọn,* ní Jerúsálẹ́mù.+

7 “Jèhófà yóò kọ́kọ́ gba àgọ́ Júdà là, kí iyì* ilé Dáfídì àti iyì* àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù má bàa pọ̀ gan-an ju ti Júdà lọ. 8 Ní ọjọ́ yẹn, Jèhófà yóò dáàbò bo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù;+ ní ọjọ́ yẹn, ẹni tó bá kọsẹ̀* nínú wọn yóò dà bíi Dáfídì, ilé Dáfídì yóò sì dà bí Ọlọ́run, bí áńgẹ́lì Jèhófà tó ń lọ níwájú wọn.+ 9 Ní ọjọ́ yẹn, ó dájú pé màá pa gbogbo orílẹ̀-èdè tó wá gbéjà ko Jerúsálẹ́mù run.+

10 “Màá tú ẹ̀mí ojú rere àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dáfídì àti àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù, wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún,+ wọ́n sì máa pohùn réré ẹkún torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń sunkún torí ọmọkùnrin kan ṣoṣo; wọ́n sì máa ṣọ̀fọ̀ gan-an torí rẹ̀ bí ìgbà tí wọ́n ń ṣọ̀fọ̀ torí àkọ́bí ọmọkùnrin. 11 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n á pohùn réré ẹkún gan-an ní Jerúsálẹ́mù, bí ẹkún tí wọ́n sun ní Hadadirímónì ní Pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò.+ 12 Ilẹ̀ náà máa pohùn réré ẹkún, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dáfídì lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé Nátánì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 13 ìdílé Léfì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; ìdílé àwọn ọmọ Ṣíméì+ lọ́tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀; 14 àti gbogbo ìdílé tó ṣẹ́ kù, ìdílé kọ̀ọ̀kan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀ àti àwọn obìnrin wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́