ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/97 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 1/97 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní January àti February: Ẹ́fíìkì àti Haúsá—Yálà Alafia ati Ãbò Tõtọ—Lati Orisun Wo? tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Gẹ̀ẹ́sì—Yálà Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun tàbí The Bible—God’s Word or Man’s? Ìgbò—Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye, True Peace and Security—How Can You Find It?, tàbí Yiyan Ọna Igbesi Ayé Ti O Dara Julọ. Ísókó—Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. Yorùbá—Ayọ̀—Bi A Ṣe Lè Rí I, Igba Ewe rẹ—Bi o ṣe le Gbadun rẹ Julọ, Igbesi Aye Yii Ha Ni Gbogbo Ohun Ti O Wà Bi?, tàbí Iwọ Le Walaaye Titilae ninu Paradise lori Ilẹ Aye. (A óò fi gbogbo ìwé olójú ewé 192 tí ó wà lókè yìí lọni ní ẹ̀dínwó ₦50 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦40]; ìwé Walaaye Titilae ní Ẹ́fíìkì, Haúsá, Ìgbò, Ísókó, àti Yorùbá jẹ́ ₦80 [iye tí aṣáájú ọ̀nà yóò gbà á, ₦50]. A ti fi lẹ́tà tí ó sọ̀rọ̀ nípa èyí ránṣẹ́ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn alàgbà ní May.) March: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé. April: Àsansílẹ̀ Ilé Ìṣọ́. Fún àwọn ìpínlẹ̀ ti a sábà máa ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ̀, a lè lo ìwé pẹlẹbẹ tuntun náà, Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? ÀKÍYÈSÍ: Àwọn ìjọ tí yóò nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí ní láti béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn, ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ Ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn ti ọ̀sẹ̀ January 6, a óò mú káàdì Advance Medical Directive/Release wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún gbogbo akéde tí ó ti batisí tí ó wà ní ìjókòó àti Identity Card fún àwọn ọmọ wọn.

◼ Bẹ̀rẹ̀ láti February, tí kò sì gbọ́dọ̀ kọjá March 2, ọ̀rọ̀ àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ yóò jẹ́ “Lo Ẹ̀kọ́ Ìwé Láti Yin Jèhófà.”

◼ Kí àwọn ìjọ ṣe ètò rírọgbọ láti ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ọdún yìí ní Sunday, March 23, lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Bí ọ̀rọ̀ àsọyé náà tilẹ̀ lè tètè bẹ̀rẹ̀, gbígbé àwọn ohun ìṣàpẹẹrẹ Ìṣe Ìrántí kò gbọ́dọ̀ bẹ̀rẹ̀, àfi lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀. Ẹ wádìí ládùúgbò láti mọ ìgbà tí oòrùn máa ń wọ̀ ní àgbègbè yín. Níwọ̀n bí a kò ti ni ṣe ìpàdé kankan yàtọ̀ sí ti iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ yẹn, ẹ ní láti ṣe ètò tí ó yẹ láti ṣe Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ní ọjọ́ mìíràn. Àwọn alábòójútó àyíká yóò ní láti ṣe ìyípadà nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé wọn fún ọ̀sẹ̀ náà, ní ìbámu pẹ̀lú àyíká ipò àdúgbò. Bí ó tilẹ̀ dára pé kí ìjọ kọ̀ọ̀kan ṣe ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí tirẹ̀, èyí lè má fìgbà gbogbo ṣeé ṣe. Níbi tí ó ti jẹ́ pé àwọn ìjọ púpọ̀ ń lo Gbọ̀ngàn Ìjọba kan náà, bóyá ìjọ kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lè lọ wá gbọ̀ngàn míràn lò ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn. Kò yẹ kí bíbẹ̀rẹ̀ Ìṣe Ìrántí náà pẹ́ jù débi tí kì yóò fi rọrùn fún àwọn olùfìfẹ́hàn tuntun láti pésẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà kò gbọ́dọ̀ kún fọ́fọ́ jù débi pé kò ní sí àkókò ṣáájú àti lẹ́yìn ayẹyẹ náà láti kí àwọn àlejò, láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí ń bá a lọ fún àwọn ẹni tuntun, tàbí láti gbádùn ìṣepàṣípààrọ̀ ìṣírí ní gbogbogbòò. Lẹ́yìn gbígbé gbogbo ọ̀ràn yẹ̀ wò dáradára, àwọn alàgbà ní láti pinnu ètò tí yóò ran àwọn tí wọ́n pésẹ̀ síbi Ìṣe Ìrántí náà lọ́wọ́ jù lọ láti jàǹfààní kíkún rẹ́rẹ́ láti inú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

◼ A óò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé àkànṣe fún gbogbo ènìyàn fún àkókò Ìṣe Ìrántí 1997 ní Sunday, April 6. A óò pèsè ìlapa èrò kan. Àwọn ìjọ tí yóò ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká, àpéjọ àyíká, tàbí ọjọ́ àpéjọ àkànṣe ní òpin ọ̀sẹ̀ yẹn, yóò sọ ọ̀rọ̀ àsọyé àkànṣe náà ní ọ̀sẹ̀ tí ó tẹ̀ lé e. Ìjọ kankan kò gbọ́dọ̀ sọ àsọyé àkànṣe náà ṣáájú April 6.

◼ Ó yẹ kí ẹgbẹ́ àwọn alàgbà mọ̀ pé àwọn ìyípadà tí ó tẹ̀ lé e yìí pọn dandan nígbà tí ìjọ bá ń lọ sí àpéjọ àdúgbò: Nígbà tí a bá ṣètò fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ọjọ́ àpéjọ àkànṣe, ìjọ gbọ́dọ̀ ṣe gbogbo ìpàdé tí a máa ń ṣe jálẹ̀ ọ̀sẹ̀, yàtọ̀ sí pé kò ní sí Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn àti Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́. Nígbà tí ẹ bá ṣètò láti lọ sí àpéjọ àyíká, kò ní sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn pẹ̀lú; kìkì Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ni ẹ óò ṣe ládùúgbò ní ọ̀sẹ̀ yẹn.

◼ Yearbook fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà—Gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àkànṣe, tí ó forúkọ sílẹ̀ ṣáájú tàbí ní July 1, 1996, lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀dà Yearbook kan lọ́fẹ̀ẹ́. A lè gba èyí nínú ẹrù tí a fi ránṣẹ́ sí ìjọ. A gbọ́dọ̀ kọ iye Yearbook ọ̀fẹ́ tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà sórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20, kí a baà lè yọ owó ọ̀kọ̀ọ̀kan kúrò. Àwọn aṣáájú ọ̀nà lè gba àfikún Yearbook ní ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà. Ìwọ̀nyí jẹ́ fún lílò ní pápá. A gbọ́dọ̀ kọ èyí sí ibòmíràn lábẹ́ ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà, lórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20. Kọ “Yearbook fún ẹ̀dínwó aṣáájú ọ̀nà” síbẹ̀. A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìwọ̀nyí dà rú pọ̀ mọ́ àwọn ẹ̀dà tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lọ́fẹ̀ẹ́. A óò dínwó ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan tí ẹ tà lẹ́dìn-ínwó aṣáájú ọ̀nà fún yín.

◼ Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ fún Àwọn Aṣáájú Ọ̀nà—Gbogbo aṣáájú ọ̀nà déédéé àti àkànṣe, tí ó forúkọ sílẹ̀ ṣáájú tàbí ní July 1, 1996, lẹ́tọ̀ọ́ sí ẹ̀dà kan lọ́fẹ̀ẹ́ fún ìlò ara ẹni. Fún ọ̀kọ̀ọ̀kan tí a fi fúnni, a óò yọ owó rẹ̀ kúrò nínú àkọsílẹ̀ ìṣirò owó ìwé yín. A kò fi àwọn aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ kún àwọn ìṣètò wọ̀nyí. Pẹ̀lúpẹ̀lù, a ní láti kọ iye es97-YR tí a fún àwọn aṣáájú ọ̀nà lọ́fẹ̀ẹ́ sórí fọ́ọ̀mù ìfowóránṣẹ́ S-20, kí a baà lè yọ owó ọ̀kọ̀ọ̀kan kúrò.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́