Àpótí Ìbéèrè
◼ Èé ṣe tí ó fi yẹ kí a ròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wa ní kánmọ́ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù?
Gbogbo wa ni a máa ń dunnú nígbà tí a bá gbọ́ ìròyìn ohun rere tí a ṣàṣeparí rẹ̀ nínú wíwàásù ìhìn iṣẹ́ Ìjọba. (Wo Òwe 25:25.) Ìṣe 2:41 ròyìn pé, tẹ̀ lé àwíyé Pétérù tí ń runi sókè, ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, “nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn ni a sì fi kún wọn.” Kò pẹ́ lẹ́yìn náà, iye yẹn ti ròkè sí “nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” (Ìṣe 4:4) Ẹ wo bí àwọn ìròyìn wọ̀nyẹn yóò ti mú inú àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní dùn tó! A ń nímọ̀lára lọ́nà kan náà sí àwọn ìròyìn afúnniníṣìírí lónìí. A máa ń láyọ̀ láti gbọ́ nípa àṣeyọrí tí àwọn ará wa máa ń gbádùn nínú wíwàásù ìhìn rere kárí ayé.
Níwọ̀n bí kíkó àwọn ìròyìn yẹn jọ ti máa ń gba ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá, ìfọwọ́sowọ́pọ̀ akéde Ìjọba kọ̀ọ̀kan ṣe kókó. Ó ha máa ń jẹ ọ́ lọ́kàn láti fi ìròyìn rẹ sílẹ̀ ní kánmọ́ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù bí?
Ìròyìn ìbísí máa ń mú ayọ̀ púpọ̀ wá fún wa. Ní àfikún sí i, ìròyìn ń ran Society lọ́wọ́ láti bójú tó ìtẹ̀síwájú iṣẹ́ kárí ayé náà. Wọ́n ní láti pinnu ibi tí a ti nílò ìrànlọ́wọ́ síwájú sí i tàbí irú àti iye àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò mú jáde. Àwọn alàgbà inú ìjọ kọ̀ọ̀kan ń lo ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá láti pinnu ibi tí ìjọ ti ní láti ṣe dáradára sí i. Ìròyìn rere máa ń gbéni ró, ó máa ń sún gbogbo wa láti ṣàyẹ̀wò iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa dáradára láti túbọ̀ ṣe dáradára sí i, bí ó bá ṣeé ṣe.
Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo akéde mọ ẹrù iṣẹ́ tí ó já lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wa léjìká láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wa sílẹ̀ ní kánmọ́ lẹ́ẹ̀mejì lóṣooṣù. Àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ wà ní ipò tí ó dára láti rán àwọn akéde létí ẹrù iṣẹ́ yìí, níwọ̀n bí wọ́n ti wà lójúfò láti pèsè ìrànlọ́wọ́ ara ẹni fún àwọn tí ó lè ṣòro fún láti ṣàjọpín nínú iṣẹ́ ìsìn pápá déédéé lóṣooṣù. Wọ́n lè ṣe ìránnilétí yìí ní ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ tí ó gbẹ̀yìn lóṣù tàbí ní àkókò míràn tí ó rọgbọ. Bí kò bá sí àǹfààní èyíkéyìí láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá sílẹ̀ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ lè gbà wọ́n, kí ó sì rí i pé ó tẹ akọ̀wé lọ́wọ́ lákòókò, kí ó bá a lè rò ó mọ́ ìròyìn oṣooṣù ìjọ tí ó sábà máa ń fi ránṣẹ́ sí Society.
Aápọn wa nínú ríròyìn ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìsìn pápá wa ní kánmọ́ déédéé, ń mú kí ẹrù àwọn tí ó ni iṣẹ́ bíbójútó ire wa nípa tẹ̀mí túbọ̀ fúyẹ́.