Àfidípò Ìtọ́jú Ìṣègùn Tí Kò Mú Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ́
1 Bí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn ṣe ń bẹ àwọn dókítà àti ilé ìwòsàn wò fún àǹfààní Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Nàìjíríà, láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ lórí àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, ọ̀pọ̀ dókítà àti oníṣẹ́ abẹ ti múra tán nísinsìnyí láti tọ́jú àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa láìfàjẹ̀ sí wọn lára. A ní ìmọrírì tòótọ́ fún ìbùkún yìí láti ọ̀dọ̀ Jèhófà. Àwọn amọṣẹ́dunjú nínú ìṣègùn tí ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ bẹ́ẹ̀ lé ní 800 ní Nàìjíríà.
2 Lẹ́yìn ṣíṣèpàdé pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, dókítà kan ní Kàdúná sọ nípa ètò náà pé: “A tẹ́wọ́ gba èrò náà dáradára. Níní tí àwọn mẹ́ńbà yín ní káàdì Advance Medical Directive ti mú kí nǹkan túbọ̀ rọrùn dáradára fún gbogbo wa [aláìsàn/dókítà].” Òmíràn láti Ìpínlẹ̀ Rivers sọ pé: “Mo mọrírì ìsapá fún ìgbétásì ìlàlóye nípa [àìlo] ẹ̀jẹ̀ nínú ìtọ́jú àwọn aláìsàn ní ilé ìwòsàn wa.” Dókítà kan láti Ìpínlẹ̀ Ògùn sọ pé: “Ètò náà ń lani lóye gan-an. Ẹ máa bá a nìṣó. Ẹ ṣeun.” Òmíràn láti Ìpínlẹ̀ Kwara sọ pé: “Gbogbo aláìsàn ní ẹ̀tọ́ láti pinnu ìtọ́jú dídára jù lọ tí ó fẹ́, ó sì jẹ́ ẹrù iṣẹ́ oníṣègùn kan tí orí rẹ̀ pé láti gbé ìṣòro aláìsàn rẹ̀ yẹ̀ wò, kí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ó lè ṣe láti gba ẹ̀mí aláìsàn náà là láìjẹ́ kí ó juwọ́ sílẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ ìsìn rẹ̀.” Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún wa níṣìírí, àbí wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀?
3 Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn máa ń pa dà bọ̀ nígbà gbogbo pẹ̀lú ìhìn iṣẹ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn dókítà àti nọ́ọ̀sì. Wọ́n sọ pé àwọn dókítà ṣàròyé pé, a kì í sọ fún wọn nígbà tí a bá kọ́kọ́ wá fún ìbẹ̀wò tàbí ìtọ́jú pé Ẹlẹ́rìí ni aláìsàn náà, pé wọn kò sì gbọ́dọ̀ lo ẹ̀jẹ̀ nínú ìtọ́jú tàbí iṣẹ́ abẹ. Àwọn mìíràn sọ pé, a kì í mú káàdì Advance Medical Directive/Release lọ́wọ́ láti dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí, kí wọ́n má baà fún wa lẹ́jẹ̀ láìmọ̀. Síbẹ̀, àwọn ilé ìwòsàn kan ṣàròyé pé, a kì í tètè wá sí ilé ìwòsàn. A máa ń dúró di ìgbà tí ọ̀ràn bá ti díjú. Ẹ̀yin ará, gbogbo àwọn kókó wọ̀nyí ni a kárí nínú lẹ́tà tí a kọ sí gbogbo ìjọ ní February 1, 1995, àti nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti August 1994. A ń fa ìṣòro fún ara wa àti àwọn ilé ìwòsàn nígbà tí a kò bá tẹ̀ lé àwọn ìṣètò tí a là lẹ́sẹẹsẹ. A ń mú ọ̀ràn yí wá sí àfiyèsí yín lẹ́ẹ̀kan sí i láti ‘ru yín sókè gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà ìránnilétí kan.’—2 Pét. 3:1.
4 Gbàrà tí o bá ti dojú kọ ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ ní ilé ìwòsàn, tètè kàn sí àwọn alàgbà àdúgbò rẹ, tí àwọn náà yóò sì kàn sí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn. Wọn yóò ṣèrànwọ́ fún ọ láti bá dókítà rẹ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí ó lè ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀.