Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀
1 “Kíyè sí i, àwọn ọmọ ni ìní Olúwa.” (Orin Dá. 127:3) Bí ẹ bá ní irú ohun ìní ṣíṣeyebíye bẹ́ẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹ̀yin, gẹ́gẹ́ bí òbí, ní ẹrù iṣẹ́ aláyọ̀ kan, bí ó tilẹ̀ wúwo, láti tọ́, láti bójú tó, àti láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín. Fún àpẹẹrẹ, ẹ ha ti gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tí ó bọ́gbọ́n mu láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín kékeré lọ́wọ́ ìfàjẹ̀sínilára bí? Báwo ni àwọn ọmọ yín yóò ṣe hùwà pa dà bí wọ́n bá dojú kọ ewu ìfàjẹ̀sínilára? Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ẹ ha ti jíròrò ohun tí ẹ lè ṣe láti kojú ipò pàjáwìrì ti a ti halẹ̀ ìfàjẹ̀sínilára mọ́ni, lọ́nà gbígbéṣẹ́ bí?
2 Mímúra ìdílé yín sílẹ̀ fún irú àwọn ipò wọ̀nyí kì í ṣe ìdí láti ṣàníyàn tàbí bẹ̀rù. Ẹ kò lè retí, kí ẹ sì múra sílẹ̀ fún gbogbo ohun tí yóò dé bá yín nínú ìgbésí ayé, ṣùgbọ́n, ohun púpọ̀ wà tí ẹ̀yin, gẹ́gẹ́ bí òbí, lè ṣe ṣáájú àkókò láti dáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ ìfàjẹ̀sínilára. Kíkọ àwọn ẹrù iṣẹ́ wọ̀nyí sílẹ̀ lè yọrí sí fífa ẹ̀jẹ̀ sí ọmọ yín lára, nígbà tí ó bá ń gba ìtọ́jú ìṣègùn. Kí ni ẹ lè ṣe?
3 Ìgbàgbọ́ Dídájú Tí Ó Fẹsẹ̀ Múlẹ̀ Ṣe Pàtàkì: Ẹ gbọ́dọ̀ ronú gidigidi lórí bí ìdánilójú ìgbàgbọ́ yín nípa òfin Ọlọ́run lórí ẹ̀jẹ̀ ṣe fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó. Ẹ ha ń kọ́ àwọn ọmọ yín láti ṣègbọràn sí Jèhófà lórí ọ̀ràn yí, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ ti ń kọ́ wọn nípa òfin rẹ̀ lórí àìlábòsí, ìwà rere, àìdásí-tọ̀túntòsì, àti àwọn apá mìíràn nínú ìgbésí ayé bí? A ha nímọ̀lára gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọ́run ti pàṣẹ nínú Diutarónómì 12:23, (NW) pé: “Pinnu láìyẹsẹ̀ láti má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀”? Ẹsẹ 25 fi kún un pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́; kí ó lè máa dára fún ọ, àti fún àwọn ọmọ rẹ lẹ́yìn rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń ṣe èyí tí ó tọ́ ní ojú OLÚWA.” Dókítà kan lè sọ pé, ẹ̀jẹ̀ yóò ‘jẹ́ kí àwọn nǹkan lọ dáradára’ fún ọmọ yín tí ń ṣàìsàn, ṣùgbọ́n, ẹ ní láti pinnu láìyẹsẹ̀ láti kọ gbígba ẹ̀jẹ̀ fún ara yín àti fún àwọn ọmọ yín, ṣáájú kí ipò pàjáwìrì èyíkéyìí tó yọjú, ní wíwo ipò ìbátan yín pẹ̀lú Jèhófà gẹ́gẹ́ bí èyí tí ó ṣe pàtàkì ju fífikún gígùn ọjọ́ ayé, tí yóò ní rírú òfin àtọ̀runwá Ọlọ́run nínú. Ó wé mọ́ rírí ojú rere Ọlọ́run nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun ní ọjọ́ iwájú!
4 Bẹ́ẹ̀ ni, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ràn ìgbésí ayé. Wọn kò nífẹ̀ẹ́ àtikú. Wọ́n fẹ́ wà láàyè, kí wọ́n baà lè yin Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ inú rẹ̀. Èyí jẹ́ ìdí kan tí wọ́n fi ń lọ sí ilé ìwòsàn, tí wọ́n sì ń mú àwọn ọmọ wọn lọ síbẹ̀ láti lọ gba ìtọ́jú. Wọ́n ń béèrè ìtọ́jú lọ́dọ̀ àwọn dókítà, nígbà tí a bá sì sọ fún wọn pé a máa lo ẹ̀jẹ̀, pé òun ni ìtọ́jú ìṣègùn, wọ́n ń béèrè fún àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ àfidípò ẹ̀jẹ̀ ní ń bẹ. Àwọn dókítà tí ó mọṣẹ́ dáradára ń lò ó. Irú ìtọ́jú ìṣègùn àfidípò bẹ́ẹ̀ kì í ṣe oògùn tí kì í ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n, ó ní í ṣe pẹ̀lú ìtọ́jú ìṣègùn, àti àwọn ọ̀nà ìgbàṣe dídára, tí a kọ sínú àwọn ìwé ìròyìn ìṣègùn òléwájú. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn dókítà kárí ayé ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú wa, ní pípèsè ìtọ́jú ìṣègùn dídára láìlo ẹ̀jẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìṣòro síbẹ̀, ní àwọn ìgbà míràn, láti rí àwọn dókítà tí yóò tọ́jú àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí láìlo ẹ̀jẹ̀.
5 Rírí Dókítà Tí Ó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀: Ọ̀pọ̀ ohun ni àwọn dókítà máa ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń tọ́jú aláìsàn agbàtọ́jú kan, nígbà tí o bá sì ní kí wọ́n tọ́jú ọmọ rẹ láìlo ẹ̀jẹ̀, èyí ń dá kún ìpèníjà náà. Àwọn dókítà kan yóò gbà láti tọ́jú àwọn àgbàlagbà, ní bíbọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ ọkàn wọn nípa ìlò ẹ̀jẹ̀, bí wọ́n bá ti gbà láti fọwọ́ sí ìwé ìtúsílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ẹ̀bi. Lọ́nà kan náà, àwọn kan lè gbà láti tọ́jú àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́, tí wọ́n ti fẹ̀rí hàn pé ọmọ aláìtójúúbọ́ tí ó dàgbà dénú ni àwọn, níwọ̀n bí àwọn ilé ẹjọ́ kan ti gbà pé àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ tí ó dàgbà dénú ní ẹ̀tọ́ láti fúnra wọn pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tí wọ́n fẹ́. (Wo Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1991, ojú ìwé 16 àti 17, fún ìjíròrò ohun tí ń mú kí a ka ọmọdé kan sí ọmọ aláìtójúúbọ́ tí ó dàgbà dénú.) Bí ó ti wù kí ó rí, àwọn dókítà lè lọ́ tìkọ̀ láti tọ́jú àwọn ọmọdé, pàápàá jù lọ àwọn ìkókó, láìjẹ́ pé wọ́n gba àṣẹ láti fàjẹ̀ sí wọn lára. Ní ti gidi, ìwọ̀nba kéréje àwọn dókítà ni yóò mú un dá ọ lójú délẹ̀délẹ̀ pé àwọn kì yóò lo ẹ̀jẹ̀ lábẹ́ ipò èyíkéyìí nígbà tí wọ́n bá ń tọ́jú ọmọdé. Fún àwọn ìdí tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ìṣègùn àti òfin, ọ̀pọ̀ jù lọ dókítà ronú pé àwọn kò lè fúnni ní irú ẹ̀rí ìdánilójú bẹ́ẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, iye tí ó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ń fẹ́ láti tọ́jú àwọn ọmọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ní ṣíṣe gbogbo ohun tí wọ́n ronú pé àwọn lè ṣe ní bíbọ̀wọ̀ fún ìfẹ́ ọkàn wa lórí ìlò ẹ̀jẹ̀.
6 Lójú ìwòye èyí, kí a sọ pé, bí o ti ń wá dókítà yíyẹ kan láti tọ́jú ọmọ rẹ, ó ṣalábàápàdé ọ̀kan tí a ròyìn pé ó máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tí ó sì ti tọ́jú Àwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn láìlo ẹ̀jẹ̀, síbẹ̀ tí ó ronú pé òfin kò fi àyè gba òun láti fi dá ọ lójú délẹ̀délẹ̀ pé òun kì yóò lo ẹ̀jẹ̀? Ṣùgbọ́n, ó fi dá ọ lójú pé, òun rò pé kò ní sí ìṣòro kankan nínú ọ̀ràn èyí pẹ̀lú. O lè pinnu pé, ìwọ kò lè rí ìdanílójú tí ó tún ju èyí lọ. Lábẹ́ àwọn àyíká ipò wọ̀nyí, o lè pinnu láti fún un láṣẹ láti máa bá iṣẹ́ lọ. Bí ó ti wù kí ó rí, jẹ́ kí ó ṣe kedere pé, fífún un ní àṣẹ tí o fún un ní àṣẹ láti tọ́jú ọmọ rẹ kò túmọ̀ sí pé, o fún un ní àṣẹ láti fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. Gbígbé ìgbésẹ̀ yí yóò jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ti o ní láti gbé, láìwo ìpinnu rẹ gẹ́gẹ́ bí ìjuwọ́sílẹ̀.
7 Àmọ́ ṣáá o, bí ó bá ṣeé ṣe fún ọ láti rí ìtọ́jú ìṣègùn àfidípò, tí ó bójú mu, tí yóò dín ewu ìlo ẹ̀jẹ̀ kù tàbí tí yóò mú un kúrò pátápátá, ó dájú pé ìwọ yóò yan ìgbésẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ léwu náà. A óò retí pé kí o ṣe ìsapá aláápọn láti wá dókítà tàbí oníṣègùn iṣẹ́ abẹ tí ó fún ọ ní ìdánilójú tí ó pọ̀ jù lọ pé òun kò ní lo ẹ̀jẹ̀. Ìdáàbòbò tí ó dára jù lọ jẹ́ láti retí ìṣòro. Sa gbogbo ipá láti wá dókítà tí ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ ṣáájú. Gbìyànjú láti yẹra fún àwọn dókítà àti ilé ìwòsàn tí kì í fọwọ́ sowọ́ pọ̀, níbi tí ó bá ti ṣeé ṣe.
8 Ní àwọn orílẹ̀-èdè míràn, ohun mìíràn tí ń pinnu bóya a óò fàjẹ̀ síni lára ni, bí a óò ṣe san owó ìtọ́jú ilé ìwòsàn. Níbi tí àwọn òbí ti ní ìbánigbófò ìlera tàbí àjẹmọ́nú mìíràn, tí ó yọ̀ǹda fún wọn láti wá dókítà tí ó wù wọ́n, ó lè rọrùn dáradára láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ọmọ bọ́ sọ́wọ́ àwọn dókítà tàbí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn tí kì í fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Níní owó tí ó pọ̀ tó sábà máa ń pinnu irú ìtọ́jú àti ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tí ìdílé kan ń rí gbà lọ́dọ̀ àwọn dókítà àti ilé ìwòsàn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bóyá ilé ìwòsàn tàbí dókítà kan múra tán láti fara mọ́ gbígbé ọmọ kan kúrò ní ilé ìwòsàn náà lọ sí òmíràn sábà máa ń sinmi lórí agbára àwọn òbí rẹ̀ láti san owó ìtọ́jú ìṣègùn. Ẹ̀yin aláboyún, ó ṣe pàtàkì pé kí ẹ bójú tó ìlera yín nígbà tí ẹ wà nínú oyún! Èyí yòó ṣèdíwọ́ púpọ̀púpọ̀ fún bíbímọ láìpóṣù, àti àwọn ìṣòro tí ó so pọ̀ mọ́ ọn, níwọ̀n bí ìtọ́jú tí a ń fún àwọn ọmọ aláìpóṣù àti àwọn ìṣòro wọn lọ́pọ̀ ìgbà máa ń mú lílo ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́.
9 Nígbà míràn, àwọn dókítà máa ń ṣàròyé pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í jíròrò àtakò tí wọ́n ní sí gbígba ẹ̀jẹ̀ títí yóò fi di ìgbà tí ẹ̀pa kò bá bóró mọ́. Kò yẹ kí ọ̀ràn rí báyìí. Ọ̀kan lára ohun àkọ́kọ́ tí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ ṣe nígbà tí wọ́n bá ń lọ sí ilé ìwòsàn tàbí tí wọ́n bá ń wá ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà kan ni láti jíròrò ìdúró wọn lórí ẹ̀jẹ̀. Bí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ, béèrè láti bá oníṣègùn apàmọ̀lárakú sọ̀rọ̀ ṣáájú àkókò. Ó lè ṣeé ṣe fún oníṣègùn iṣẹ́ abẹ náà láti ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣe èyí. O gbọ́dọ̀ yẹ fọ́ọ̀mù ìgbaniwọlé wò fínnífínní. O ní ẹ̀tọ́ láti wọ́gi lé ohunkóhun tí o kò fohùn ṣọ̀kan lé lórí. Láti mú iyè méjì èyíkéyìí kúrò, kọ pé o kò fẹ́ ẹ̀jẹ̀, o kò sì yọ̀ǹda fún lílo ẹ̀jẹ̀ lábẹ́ ipò èyíkéyìí, fún àwọn ìdí tí ó jẹ mọ́ ti ìsìn àti ti ìṣègùn, sára fọ́ọ̀mù ìgbaniwọlé náà gàdàgbàgàdàgbà.
10 Ìrànlọ́wọ́ Láti Ọ̀dọ̀ Ètò Àjọ Jèhófà: Àwọn ìpèsè wo ni ètò àjọ Jèhófà ti ṣe láti ràn yín lọ́wọ́ nínú dídáàbò bo àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ ẹ̀jẹ̀? Wọ́n pọ̀ jáǹtìrẹrẹ. Society ti tẹ ọ̀pọ̀ ìwé jáde láti dá wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ àti àwọn àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́. Ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ ìwé pẹlẹbẹ náà, How Can Blood Save Your Life? àti àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn lórí kókó ẹ̀kọ́ yìí. Ẹ sì ní àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin yín nínú ìjọ àdúgbò, tí wọ́n lè pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtìlẹ́yìn púpọ̀ fún yín. Nígbà tí yánpọnyánrin bá bẹ́ sílẹ̀, àwọn alàgbà lè ronú pé ó bọ́gbọ́n mu láti ṣètò fún àdúrótì oníwákàtí 24 ní ilé ìwòsàn náà, ó dára jù bí ó bá jẹ́ alàgbà kan àti òbí aláìsàn agbàtọ́jú náà tàbí mẹ́ńbà ìdílé mìíràn tí ó sún mọ́ wọn. A máa ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára lọ́pọ̀ ìgbà nígbà tí gbogbo ìbátan àti ọ̀rẹ́ bá ti darí lọ sílé lálẹ́.
11 Ní United States, Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn tí ó ju ọgọ́rùn ún lọ ni ó wà káàkiri àwọn ìlú ńláńlá. Ní Nàìjíríà, a ní 42 nísinsìnyí. A yan gbogbo ìjọ sábẹ́ ìgbìmọ̀ kan, tí ó ní àwọn arákùnrin tí a ti dá lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣèrànwọ́ nínú. Ẹ ké sí wọn, nípasẹ̀ àwọn alàgbà ìjọ yín, nígbà tí ẹ bá nílò wọn. Ẹ kò gbọ́dọ̀ ké sí wọn fún àwọn ìṣòro tí kò tó nǹkan, ṣùgbọ́n, ẹ má ṣe jẹ́ kí ó pẹ́ jù kí ẹ tó ké sí wọn, bí ẹ bá fura pé ìṣòro ńlá kan lè máa rú yọ. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n lè fún wa ní orúkọ àwọn dókítà àti oníṣègùn iṣẹ́ abẹ tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti lo àfidípò. Níbi tí ó bá ti pọn dandan, tí ó sì ṣeé ṣe, àwọn arákùnrin wọ̀nyí máa ń ṣètò láti wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́ láti bójú tó ìṣòro náà. Jọ̀wọ́ rántí pé Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn kò lè fowó ranni lọ́wọ́.
12 Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí kò ní in lọ́kàn láti jẹ́ kí àwọn ọmọ wọ́n kú ikú “ajẹ́rìíkú.” Bí wọ́n bá ní in lọ́kàn, kí ló fà á tí wọ́n fi gbé àwọn ọmọ wọn lọ́ sí ilé ìwòsàn rárá? Ní òdì kejì pátápátá, àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí ń fínnúfíndọ̀ wá ìtọ́jú ìṣègùn fún àwọn ọmọ wọn. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì fẹ́ kí wọ́n ní ìlera jíjí pépé. Ṣùgbọ́n, wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ní ojúṣe kan tí Ọlọ́run fi fún wọn, láti yan irú ìtọ́jú ìṣègùn tí ó dára jù lọ fún àwọn ọmọ wọn. Wọ́n fẹ́ kí a bójú tó ìṣòro ìlera àwọn ọmọ wọn láìlo ẹ̀jẹ̀. Kì í ṣe kìkì pé irú àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ dára jù, tí ewu inú rẹ̀ sì dín kù nìkan ni, ṣùgbọ́n, lọ́nà tí ó ṣe pàtàkì jù lọ, ó ń mú kí àwọn ọmọ wọ́n rí ojú rere Olùfúnniníyè títóbi lọ́lá náà, Jèhófà Ọlọ́run.
13 Láìka àǹfààní àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ sí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn dókítà ka ìfàjẹ̀sínilára sí ìtọ́jú ìṣègùn tí ó bá ìlànà mu, tí ó lè pọn dandan tàbí kí ó tilẹ̀ gbẹ̀mí là pàápàá nínú àwọn ọ̀ràn kan. Nípa báyìí, nígbà tí àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí bá kọ ìfàjẹ̀sínilára tí a dábàá, ìṣòro lè dìde. Ní gbogbogbòò, kò bófin mu fún àwọn dókítà láti tọ́jú ọmọdé kan láìjẹ́ pé àwọn òbí ọmọ náà gbà. Mímọ èyí tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì rírí dókítà kan tí ó fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Ṣiṣẹ́ pẹ̀lú rẹ̀, pẹ̀lú ìrànwọ́ àwọn mẹ́ńbà Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn àgbègbè rẹ, ràn án lọ́wọ́ láti lépa àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ láti bójú tó ìṣòro àìsàn ọmọ rẹ tàbí kí o gbé ọmọ rẹ kúrò lọ sọ́dọ̀ dókítà tàbí ilé ìwòsàn tí yóò pèsè irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀.
14 Kí ni ìwọ yóò ṣe bí dókítà tàbí ilé ìwòsàn kan bá béèrè ìdí tí o fi ń kọ ìfàjẹ̀sínilára ‘agbẹ̀mílà’ fún ọmọ rẹ? Bí ìtẹ̀sí rẹ àkọ́kọ́ tilẹ̀ lè jẹ́ láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ rẹ nínú àjíǹde, àti láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ lílágbára tí o ní pé Ọlọ́run yóò jí ọmọ rẹ dìde bí ó bá kú, irú ìdáhùn bẹ́ẹ̀ yóò wulẹ̀ mú un dá wọn lójú pé agbawèrèmẹ́sìn ni ọ́.
15 Ohun tí ó yẹ kí wọ́n mọ̀ ni pé, bí ẹ tilẹ̀ ń kọ ẹ̀jẹ̀ lórí ìdí tí ó fẹsẹ̀ rinlẹ̀ nínú ìsìn, ẹ kò kọ ìtọ́jú ìṣègùn. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n rí i pé ẹ kì í ṣe òbí tí kò bìkítà tàbí oníkà, ṣùgbọ́n, kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ òbí onífẹ̀ẹ́, tí ń wá ìtọ́jú fún ọmọ yín. Ẹ kò wulẹ̀ gbà pé àǹfààní tí wọ́n sọ pé ẹ̀jẹ̀ ní ju àwọn ewu tí ó lè mẹ́mìí lọ àti ìjàǹbá tí ó ṣeé ṣe kí ó mú wá, pàápàá jù lọ, nígbà tí àwọn àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú àwọn ewu wọ̀nyí lọ́wọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó.
16 Ní sísinmi lórí ipò nǹkan, o lè jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún wọn pé, dókítà kan ni ó rò pé a nílò ẹ̀jẹ̀, ṣùgbọ́n, ọ̀nà tí àwọn dókítà máa ń gbà tọ́jú ènìyàn máa ń yàtọ̀ síra, ìwọ yóò sì fẹ́ àǹfààní láti wá dókítà tí yóò tọ́jú ọmọ rẹ ní lílo ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn tí kò mú ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́, tí ó wà káàkiri. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn, o lè ti rí irú dókítà bẹ́ẹ̀, tí yóò tọ́jú ọmọ rẹ láìlo ẹ̀jẹ̀. Bóyá ìgbìmọ̀ alárinà náà lè bá wọn ṣàjọpín àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ nípa ìṣègùn, tí ń fi bí a ṣe lè bójú tó ìṣòro ìṣègùn ọmọ rẹ lọ́nà gbígbéṣẹ́ láìlo ẹ̀jẹ̀ hàn.
17 Wọ́n mọ̀ nípa àìlóǹkà ewu tí ń bẹ nínú lílo ẹ̀jẹ̀, títí kan àrùn AIDS, àrùn mẹ́dọ̀wú, àti ọ̀pọ̀ ìjàǹbá mìíràn. O lè rán wọn létí ìwọ̀nyí, o tún lè jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ìwọ, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni òbí kan, yóò ka lílo ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́jẹ̀ nínú ìsapá láti gba ẹ̀mí là, sí títẹ òfin Ọlọ́run lójú, pé ìwọ yóò sì ka fífi ipá fa ẹ̀jẹ̀ sí ọmọ rẹ lára sí fífi ipá bá a lò pọ̀. Ìwọ àti ọmọ rẹ (bí ó bá dàgbà tó láti ní ìdánilójú ìgbàgbọ́ tirẹ̀) lè ṣàlàyé bí ẹ ṣe kórìíra irú ìfipábánilò bẹ́ẹ̀, ẹ sì lè fọ̀ràn lọ ìmọ̀lára wọn, pé kí wọ́n má ṣe fàjẹ̀ sí i lára, ṣùgbọ́n, kí wọ́n lépa àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn fún ọmọ rẹ.
18 Ní bíbá àwọn tí ń wá ọ̀nà láti fipá fàjẹ̀ síni lára lò, ó ṣe pàtàkì pé kí o má ṣe fún wọn ní ẹ̀rí èyíkéyìí pé o ń ṣiyè méjì nínú ìdánilójú ìgbàgbọ́ rẹ. Nígbà míràn, àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn máa ń béèrè bí àwọn òbí yóò bá ní ìṣòro èyíkéyìí ní “gbígbé” ẹrù iṣẹ́ pípinnu láti fàjẹ̀ síni lára “kà wọ́n lórí,” ní ríronú pé èyí yóò mú kí ó rọrùn fún àwọn òbí láti ní ẹ̀rí ọkàn tí ó mọ́. Ṣùgbọ́n, ẹ gbọ́dọ̀ mú kí ó ṣe kedere fún gbogbo àwọn tí ọ̀ràn kàn pé ẹ̀yin, gẹ́gẹ́ bí òbí, ní iṣẹ́ àìgbọdọ̀máṣe láti máa bá a nìṣó láti ṣe gbogbo ohun tí ẹ bá lè ṣe láti yẹra fún ìfàjẹ̀sínilára. Ẹ̀yin ni Ọlọ́run fún ní ẹrù iṣẹ́ yìí. Kò ṣeé gbé lé ẹlòmíràn lọ́wọ́.
19 Nítorí náà, ní bíbá àwọn dókítà sọ̀rọ̀, ẹ gbọ́dọ̀ múra láti sọ ipò tí ẹ dì mú kedere, pẹ̀lú ìdánilójú ìgbàgbọ́. Ẹ máa bá a lọ láti pàrọwà fún dókítà náà pé kí ó má ṣe fa ẹ̀jẹ̀ sí ọmọ yín lára, kí ẹ sì rọ̀ ọ́ láti lo àfidípò ìtọ́jú ìṣègùn. Ẹ máa bá a lọ láti wá ìfọwọ́sowọ́pọ̀ rẹ̀ láti gbé àwọn ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ ìṣègùn àti ìmọ̀ràn àwọn dókítà èyíkéyìí tí wọ́n ń fẹ́ kí a kàn sí wọn lórí ìṣòro ìṣègùn náà, láti lè yẹra fún lílo ẹ̀jẹ̀, yẹ̀ wò. Nínú ọ̀ràn tí ó ju ẹyọ kan lọ, dókítà tí ó ti dà bí aláìfohùnṣọ̀kan tẹ́lẹ̀ rí, ti jáde láti inú yàrá ìṣiṣẹ́ abẹ, tí ó sì fi ìdánilójú kéde pé, òun kò lo ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà, ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀, láìka ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ sí!—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, June 15, 1991, “Ibeere Lati Ọwọ Awọn Onkawe.”
20 “Ẹni tí ó fi òye ṣe ọ̀ràn yóò rí ire; ẹni tí ó sì gbẹ́kẹ̀ lé Olúwa, ìbùkún ni fún un.” (Òwe 16:20) Ẹ̀yin òbí, ẹ ṣe ìmúrasílẹ̀ tí ó pọn dandan ṣáájú, láti dáàbò bo ọmọ yín lọ́wọ́ ìfàjẹ̀sínilára, tí ń kó èérí báni nípa tẹ̀mí. (Òwe 22:3) Ẹ̀yin ọmọ, ẹ ṣiṣẹ́ lórí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àwọn òbí yín nínú ṣíṣe àwọn ìmúrasílẹ̀ wọ̀nyí, kí ẹ sì fi wọ́n sọ́kàn yín. Gẹ́gẹ́ bí ìdílé kan, ‘ẹ pinnu láìyẹsẹ̀ láti má ṣe jẹ ẹ̀jẹ̀ . . . kí ó lè máa dára fún yín’ nítorí níní ìbùkún Jèhófà àti ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀.—Diu. 12:23-25.