Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún January
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 6
Orin 6
15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Sọ̀rọ̀ lórí ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá ti orílẹ̀-èdè àti ti ìjọ àdúgbò, fún oṣù September. Ṣàyẹ̀wò Àpótí Ìbéèrè.
15 min: Àkókò Láti Gba Káàdì Advance Medical Directive/Release Tuntun. Alàgbà títóótun jíròrò ìjẹ́pàtàkì kíkọ ọ̀rọ̀ kún káàdì náà dáadáa, àti mímú un lọ́wọ́ ní gbogbo ìgbà. Káàdì yí ń gbẹnu sọ fún ọ nígbà tí o kò bá lè sọ̀rọ̀ fúnra rẹ ní àkókò pàjáwìrì. (Fi wé Òwe 22:3.) Ó ṣe pàtàkì láti kọ̀rọ̀ kún káàdì tuntun lọ́dọọdún láti pèsè ìkéde wa lọ́ọ́lọ́ọ́ lórí àìgbẹ̀jẹ̀, níwọ̀n bí àwọn dókítà kan àti àwọn mìíràn ti sọ pé káàdì tí ó ti lé ní ọdún kan lè má fi ìdánilójú ìgbàgbọ́ ẹnì kan ti lọ́ọ́lọ́ọ́ hàn. Lẹ́yìn ìpàdé, a óò fún gbogbo akéde tí ó ti ṣe batisí ní káàdì Advance Medical Directive/Release, àwọn tí ó sì ní àwọn ọmọ aláìtójúúbọ́, tí kò tí ì ṣe batisí, yóò gba Identity Card fún ọmọ kọ̀ọ̀kan. Ṣàlàyé pé, a kò ní kọ̀rọ̀ kún àwọn káàdì wọ̀nyí láṣàálẹ́ yìí. Kí a fara balẹ̀ kọ̀rọ̀ kún wọn nílé, ṣùgbọ́n KÍ A MÁ fọwọ́ sí wọn. A óò fọwọ́ sí wọn, a óò jẹ́rìí sí wọn, a óò sì kọ déètì sí wọn níbi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí ó tẹ̀ lé e, lábẹ́ àbójútó olùdarí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ. Òun yóò rí i dájú pé gbogbo àwọn tí a yàn sí àwùjọ rẹ̀ rí káàdì àti ìrànlọ́wọ́ tí wọ́n nílò gbà. Àwọn tí ń fọwọ́ sí i gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí gbọ́dọ̀ rí ẹni tí ó ni káàdì náà nígbà tí ó ń fọwọ́ sí i. Àwọn olùdarí tàbí alàgbà yóò ran ẹni tí kò wá ní ọjọ́ náà lọ́wọ́ nígbà Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí ó tẹ̀ lé e, títí tí gbogbo akéde tí ó ti ṣe batisí bá kọ̀rọ̀ kún káàdì wọn dáradára, tí wọ́n sì fọwọ́ sí i. (Ṣàtúnyẹ̀wò lẹ́tà October 15, 1991.) Àwọn akéde tí kò tí ì ṣe batisí lè kọ ìtọ́sọ́nà tiwọn jáde fún ara wọn àti fún àwọn ọmọ wọn, nípa mímú àwọn èdè ìsọ̀rọ̀ inú káàdì yí bá ipò àti ìgbàgbọ́ wọn mu.
15 min: “A Tóótun, A sì Gbára Dì Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn.” (Ìpínrọ̀ 1 sí 6) Sọ̀rọ̀ ṣókí lórí ìpínrọ̀ 1 àti 2, ní títẹnumọ́ àìní fún wa láti ní ìgbọ́kànlé pé, pẹ̀lú ìrànwọ́ Jèhófà, a lè kọ́ àwọn ẹlòmíràn lọ́nà gbígbéṣẹ́. Jẹ́ kí akéde méjì, onílé méjì ṣàṣefihàn àwọn ìgbékalẹ̀ inú ìpínrọ̀ 3 sí 6, tí wọ́n ń fi bí a ṣe ń ṣe ìkésíni àkọ́kọ́ àti ìpadàbẹ̀wò hàn.
Orin 14 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 13
Orin 16
7 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Tẹnu mọ́ àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ nínú àwọn ìwé ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́. Pèsè ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè sọ ẹni tí a jẹ́, nígbà tí a bá ń tọ àwọn ènìyàn lọ láti lè jẹ́rìí àìjẹ́-bí-àṣà. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nígbà tí wọ́n ń bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀ nínú ìsọ̀, lójú pópó, ní ibùdókọ̀, nínú ọkọ̀ èrò, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Sọ ètò tí a ṣe fún iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀.
10 min: “A Tóótun, A sì Gbára Dì Láti Kọ́ Àwọn Ẹlòmíràn.” (Ìpínrọ̀ 7 sí 9) Sọ ìrírí nípa ṣíṣe ìpadàbẹ̀wò, tí ó wà nínú 1995 Yearbook, ojú ìwé 45, tí ń tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ṣíṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ ọkàn èyíkéyìí tí a bá fi hàn. Jẹ́ kí akéde onírìírí kan ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ inú ìpínrọ̀ 7 àti 8. Bí a tilẹ̀ fi àwọn ìtẹ̀jáde mìíràn lọni ní ìbẹ̀rẹ̀, a gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wa láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ nínú ìwé Ìmọ̀, nígbẹ̀yìngbẹ́yín. Rọ gbogbo àwùjọ láti ṣètò àkókò ní ọ̀sẹ̀ tí ń bọ̀ láti ṣe ìpadàbẹ̀wò.
13 min: “Àfidípò Ìtọ́jú Ìṣègùn Tí Kò Mú Ẹ̀jẹ̀ Lọ́wọ́.” Kí alàgbà kan tí ó tóótun bójú tó èyí. Ka gbogbo ìpínrọ̀. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì ìpínrọ̀ 3 àti 4, àti ìjẹ́pàtàkì kíkàn sí àwọn alàgbà nígbà tí ẹ̀jẹ̀ bá dí awuyewuye nínú ìtọ́jú.
15 min: “Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀.” Alàgbà sọ̀rọ̀ lórí ìpínrọ̀ 1 sí 10. Mú ìdí tí ó wà lẹ́yìn dídé orí ìpinnu pé gbígbà tí àwọn òbí gbà pé kí oníṣègùn kan tọ́jú ọmọ wọn lábẹ́ àwọn àyíká ipò tí a mẹ́nu kàn nínú ìpínrọ̀ 5 sí 7 kì í ṣe ohun tí a gbọ́dọ̀ wò gẹ́gẹ́ bí ìjuwọ́sílẹ̀, ṣe kedere.
Orin 15 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 20
Orin 21
10 min: Àwọn Ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.
15 min: “A Óò Gba Gbogbo Onírúurú Ènìyàn Là.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ké sí àwùjọ láti sọ ìrírí ṣókí, tí ń fi bí wọ́n ti rí ìdáhùnpadà dídára gbà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn láti inú iṣẹ́ ìgbésí ayé ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ hàn.
20 min: “Dídáàbò Bo Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Ìlòkulò Ẹ̀jẹ̀.” Ìjíròrò ìpínrọ̀ 11 sí 20 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹnu mọ́ ọn pé, ìmúrasílẹ̀ ṣáájú tí àwọn òbí ti ṣe ní wíwá ìtọ́jú ìṣègùn fún ọmọ wọn ni ó sábà máa ń jẹ́ kọ́kọ́rọ́ sí àṣeyọrí nínú yíyẹra fún ìfàjẹ̀sínilára.
Orin 23 àti àdúrà ìparí.
Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní January 27
Orin 20
10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò.
18 min: “A Ń ‘Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà.’” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àlàyé tí ń fi ìdí tí a fi ní ìmọrírì jíjinlẹ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún un.—Wo Jí!, September 8, 1985, ojú ìwé 9 sí 11.
17 min: Ṣàyẹ̀wò Àwọn Ìwé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Tí A Óò Fi Lọni ní February. Tọ́ka sí àwọn apá fífanimọ́ra inú àwọn ìwé náà, irú bí: (1) Àwọn àkòrí gbígbàfiyèsí, (2) àwọn àwòrán mèremère, àti (3) àwọn ìbéèrè tí a tẹ̀ jáde tí ń ru ìfẹ́ sókè. Ní ìbámu pẹ̀lú apá ìpàdé tí a parí tán, fún àwùjọ níṣìírí láti lo àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ti fara balẹ̀ yàn, nínú ìgbékalẹ̀ náà. Jẹ́ kí a ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ kan tàbí méjì. Rán gbogbo àwùjọ létí láti gba àwọn ìwé tí wọn yóò lò ní ọ̀sẹ̀ yí.
Orin 26 àti àdúrà ìparí.