A Óò Gba Gbogbo Onírúurú Ènìyàn Là
1 Ìfẹ́ Jèhófà ni pé, “kí a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là kí wọ́n sì wá sí ìmọ̀ pípéye nípa òtítọ́.” (1 Tím. 2:4) Bí ànímọ́ àjogúnbá, ìgbésí ayé àtilẹ̀wá, àti àyíká tilẹ̀ ń nípa lórí ènìyàn dé ìwọ̀n àyè kan, wọ́n ní òmìnira yíyàn, wọ́n sì lè pinnu lẹ́nì kọ̀ọ̀kan bí wọn yóò ṣe gbé ìgbésí ayé wọn. Wọ́n lè ṣe ohun tí ó dára, kí wọ́n sì wà láàyè, tàbí wọ́n lè ṣe ohun tí ó burú, kí wọ́n sì pa run. (Mát. 7:13, 14) Báwo ni òye yìí ṣe nípa lórí ojú tí a fi ń wo àwọn ènìyàn tí a ń mú ìhìn rere Ìjọba lọ fún?
2 Kò yẹ kí a ronú pé, àwọn kókó bí orílẹ̀-èdè tàbí ẹgbẹ́ àwùjọ tí ẹnì kan ti wá tàbí ipò rẹ̀ nínú ìgbésí ayé ní ń pinnu ìfẹ́ tí ó ní fún òtítọ́. Òtítọ́ lè fa àwọn tí ẹ̀kọ́ ìwé wọn kò tó nǹkan àti àwọn tí wọ́n ti kàwé jìnnà mọ́ra, ó lè fa àwọn tí wọ́n ti ri ara wọn bọ ìṣèlú, àti àwọn amọṣẹ́dunjú, àwọn aláìgbọlọ́rungbọ́, àwọn onígbàgbọ́ Ọlọ́run-kò-ṣeémọ̀, àti àwọn ọ̀daràn paraku pàápàá mọ́ra. Àwọn ènìyàn láti apá ibi gbogbo nínú ìgbésí ayé àti gbogbo ipò àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn ti yí ipa ọ̀nà ìwà wọn àtijọ́ pa dà, wọ́n sì wà lójú ọ̀nà fún ìgbésí ayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run. (Òwe 11:19) Nítorí náà, kò yẹ kí a lọ́ tìkọ̀ láti mú ìhìn iṣẹ́ Ìjọba tọ àwọn ènìyàn inú gbogbo ipò àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn lọ.
3 Gbé Àwọn Àpẹẹrẹ Wọ̀nyí Yẹ̀ Wò: Ọkùnrin kan ti pinnu láti pa ọkọ ìyá rẹ̀, ṣùgbọ́n kò ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pinnu láti pa ara rẹ̀, ṣùgbọ́n, kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Lẹ́yìn tí a jù ú sẹ́wọ̀n fún olè jíjà àti fún títa oògùn líle, ìgbéyàwó rẹ̀ forí ṣánpọ́n. Lónìí, ọkùnrin yìí ń ṣe iṣẹ́ tí kò lábòsí, ó sì ń gbádùn ìgbéyàwó aláyọ̀ àti ìbátan àtàtà pẹ̀lú ọkọ ìyá rẹ̀. Kí ni ó fa ìyàtọ̀ yí? Ó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì fi àwọn ohun tí ó kọ́ sílò. Jèhófà kò kà á sí ẹni tí kò ṣeé yí pa dà.
4 Òkìkí tí ọ̀dọ́bìnrin kan ní gẹ́gẹ́ bí òṣèré orí tẹlifíṣọ̀n kò máyọ̀ wá fún un. Ṣùgbọ́n, nítorí tí ìwà rere Àwọn Ẹlẹ́rìí wú u lórí, ó tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sì pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ ìhìn rere Ìjọba. Gbogbo ibi tí ó lọ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé ni wọ́n ti mọ̀ ọ́n, ṣùgbọ́n, ó máa ń ṣàlàyé tayọ̀tayọ̀ pé òun fẹ́ kí a mọ òun gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe bí òṣèré kan.
5 Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan ṣètò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú ẹnì kan tí ó san àsansílẹ̀ owó fún Ilé Ìṣọ́, aládùúgbò kan gbọ́ nípa rẹ̀, ó sì wá fún ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Aládùúgbò náà mọ̀ lọ́gán pé òtítọ́ tí òun ti ń wá kiri ni èyí! Òun àti ọkọ rẹ̀ fagi lé àṣẹ ìkọ̀sílẹ̀ tí àwọn méjèèjì ti gbà, wọ́n sì parí ìjà wọn. Ó ti rìn jìnnà nínú ìwòràwọ̀, ó sì jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ awo kan, ṣùgbọ́n, kò lọ́ tìkọ̀ láti da àwọn ìwé olówó ńlá àti gbogbo ohun tí ó ní, tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí èṣù nù. Kò pẹ́ tí ó fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé, tí ó sì ń bá àwọn mọ̀lẹ́bí àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ rẹ̀ tuntun. Nísinsìnyí, ó ń fi ìtara jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn.
6 Kò yẹ kí a ro ẹnikẹ́ni pin. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ kí a fi ìtara ṣàjọpín ìhìn rere pẹ̀lú àwọn ènìyàn níbi gbogbo. A ní ìdí púpọ̀ láti ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà, tí ń “wo ọkàn,” yóò di “Olùgbàlà gbogbo onírúurú ènìyàn.”—1 Sám. 16:7; 1 Tím. 4:10.