A Ń “Wàásù Ọ̀rọ̀ Náà”
1 Gan-an gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” ọ̀pọ̀ jù lọ ènìyàn lónìí ní kìkì “àwòrán ìrísí ìfọkànsin Ọlọ́run.” (2 Tím. 3:1, 5) Èyí jẹ́ nítorí pé àwọn aṣáájú ìsìn ti kùnà láti pèsè ojúlówó ìtọ́sọ́nà tẹ̀mí fún àwọn agbo wọn. Àwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù kì í gbẹnu sọ fún Bíbélì. Wọ́n yàn láti sọ àsọtúnsọ ẹ̀kọ́ asán àwọn ọlọ́gbọ́n èrò orí àti ti àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tàbí láti ṣe ìméfò àwọn ọ̀ràn ẹgbẹ́ àwùjọ àti ti ìṣèlú dípò wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ aṣáájú ìsìn ni kò gba Bíbélì gbọ́. Wọ́n sábà máa ń fàyè gba ìbọ̀rìṣà láàárín àwọn mẹ́ńbà wọn dípò rírọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣíṣe kedere. Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àlúfàá kì í tilẹ̀ lo orúkọ Ọlọ́run, wọn kò sì gbé ìbéèrè dìde sí mímú un kúrò nínú ìtúmọ̀ Bíbélì òde òní.
2 Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ òtítọ́ nípa àwọn aṣáájú ìsìn ọjọ́ Jésù, asán ni àwọn àlùfáà òde òní ń wàásù. (Mát. 15:8, 9) Bí wòlíì Ámósì ṣe sọ tẹ́lẹ̀ gan-an ni ó rí. Ìyàn ń bẹ, “kì í ṣe ìyàn oúnjẹ, tàbí òǹgbẹ fún omi, ṣùgbọ́n ìyàn gbígbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa.” (Ámósì 8:11) Ju ohun gbogbo lọ, àwọn ènìyàn nílò òunjẹ tẹ̀mí inú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.
3 Bí A Ṣe Lè Tẹ́ Àìní Tẹ̀mí Àwọn Ènìyàn Lọ́rùn: Pọ́ọ̀lù gba Tímótì níyànjú láti rọ̀ mọ́ “ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ [ẹnì kan] di ọlọgbọ́n fún ìgbàlà,” nítorí náà, ó pàṣẹ fún un láti “wàásù ọ̀rọ̀ náà” fún àwọn ẹlòmíràn. (2 Tím. 3:14, 15; 4:2) Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a gbọ́dọ̀ rọ̀ mọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni, nígbà tí a bá ń wàásù, nípa báyìí, a ń fara wé Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa, Jésù, tí ó sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 7:16) Orí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni a gbé ẹ̀kọ́ wa kà, nítorí pé, a mọ̀ pé ọgbọ́n àtọ̀runwá ni ó ń bẹ nínú rẹ̀, a sì fẹ́ kí àwọn ènìyàn mọ orísun ìsọfúnni tí a ń ṣàjọpín pẹ̀lú wọn.—1 Kọ́r. 2:4-7.
4 Àwọn ènìyàn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ gbọ́ òtítọ́ láti inú Bíbélì, kí wọ́n baà lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé lọ́nà tí ó bọ́gbọ́n mu pé: “Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe lo ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?” (Róòm. 10:14) Nípa wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, à ń ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti jèrè ìgbàgbọ́ nípasẹ̀ ìmọ̀ pípéye. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ lè yí ìgbésí ayé pa dà sí rere, ó sì ń ṣe bẹ́ẹ̀. Òǹṣèwé ọmọ ilẹ̀ Britain náà, Charles Dickens, kọ̀wé nípa Bíbélì pé: “Òun ni ìwé tí ó dára jù lọ tí ó tí ì wà, tàbí tí yóò wà láyé, nítorí pé ó ń kọ́ni ní àwọn ẹ̀kọ́ dídára jù lọ nípasẹ̀ èyí tí ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí tí ń gbìyànjú láti jẹ́ olóòótọ́ àti olódodo fi lè rí ìtọ́sọ́nà.”
5 Àwọn tí òǹgbẹ òtítọ́ ń gbẹ nípa tẹ̀mí, wá lóyè pé àṣẹ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tì í lẹ́yìn. Nígbà náà lọ́hùn-ún ní ọdún 1913, a fún Frederick W. Franz, ọmọ kọ́lẹ́ẹ̀jì kan tí ó jẹ́ ọ̀dọ́, ní ìwé pélébé kan tí àkọlé rẹ̀ ń jẹ́, Where Are the Dead? Lẹ́yìn fífi ìfẹ́ ọkàn jíjinlẹ̀ ka ìdáhùn Bíbélì sí ìbéèrè yìí, ó polongo pé: “Èyí ni òtítọ́.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn olùwá òtítọ́ kiri ti nímọ̀lára lọ́nà kan náà. Ẹ jẹ́ kí a máa bá a lọ láti wàásù Ọ̀rọ̀ náà taápọntaápọn àti tìtaratìtara, kí a sì tipa báyìí ṣàjọpín nínú ìdùnnú gbígbọ́ kí àwọn ẹlòmíràn máa sọ pé: “Èyí ni òtítọ́.”