Ǹjẹ́ Ọmọ Rẹ Á Lè Ṣe Ìpinnu bí Àgbàlagbà?
1. Ìpinnu wo làwọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí ti ṣe lórí ọ̀ràn gbígba ẹ̀jẹ̀ sára? Mẹ́nu kan àpẹẹrẹ kan.
1 Ìpinnu bí àgbàlagbà lórí kí ni? Lórí ọ̀ràn gbígba ẹ̀jẹ̀ sára ni. Àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ẹ Rìn Gẹ́gẹ́ Bí Jèhófà Ti Fún Yín ní Ìtọ́ni” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 1991 sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí. Àpilẹ̀kọ yìí mẹ́nu kan báwọn ọmọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe dúró gbọin ti ìpinnu tí wọ́n ṣe láti fi hàn pé tọkàntọkàn làwọn fi ṣèpinnu náà pé àwọn á ṣègbọràn sí òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ báwọn òbí àwọn náà ṣe fọwọ́ pàtàkì mú un. Ṣó pọn dandan kí ọmọ tìẹ náà tó jẹ́ aláìtójúúbọ́ ṣe irú ìpinnu yẹn?
2. Ìlànà òfin wo ni ilé ẹjọ́ kan lò nínú ọ̀ràn ọmọ aláìtójúúbọ́ kan tó kọ̀ tó lóun ò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára, ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí tí wọ́n jẹ́ Kristẹni àtàwọn ọmọ wọn aláìtójúúbọ́ sì lè rí kọ́ látinú rẹ̀?
2 Kí Ni Òfin Sọ? Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ilé ẹjọ́ tó ga jù lọ tó tíì fún ọmọ aláìtójúúbọ́, tí òye yé, lẹ́tọ̀ọ́ láti sọ pé òun ò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára ni Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ tó wà ní ìpínlẹ̀ Illinois. Nígbà tí ilé ẹjọ́ yẹn ń tún ẹjọ́ ọmọbìnrin ọlọ́dún mẹ́tàdínlógún kan yẹ̀ wò, ilé ẹjọ́ náà pàṣẹ pé: “Bí ẹ̀rí náà bá hàn kedere tó sì dájú pé aláìtójúúbọ́ náà ti gbọ́n tó láti lóye ohun tó máa tẹ̀yìn ìgbésẹ̀ rẹ̀ yọ tó sì ń ṣe bí àgbà tóye yé, a jẹ́ pé ọmọ náà lẹ́tọ̀ọ́ látàrí ìlànà òfin tó wà fáwọn ọmọ aláìtójúúbọ́ láti gbà tàbí kọ ìtọ́jú ìṣègùn tó bá fẹ́, lábẹ́ òfin.” Nítorí náà, báwọn dókítà bà fẹ́ mọ̀ bóyá òye yé ọmọ kan débi tó fi lè dá ṣe ìpinnu, àwọn dókítà tàbí òṣìṣẹ́ ìjọba èyíkéyìí lè fọ̀rọ̀ wá aláìlera náà lẹ́nu wò lórí ohun tó rí tó fi sọ pé òun ò ní gba ẹ̀jẹ̀ sára. Irú ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ gbọ́dọ̀ ti mọ bí ipò tí ìlera òun wà ṣe le tó àti ohun tó lè jẹ́ àbájáde irú ìtọ́jú ìṣègùn tóun yàn, ó gbọ́dọ̀ lè ṣàlàyé yékéyéké nípa ohun tó gbà gbọ́ nípa òfin Ọlọ́run lórí ẹ̀jẹ̀, láìfi ọ̀kan pe méjì.
3. Àwọn ìbéèrè wo làwọn òbí gbọ́dọ̀ ronú lé lórí dáadáa, kí sì nìdí?
3 Kí Ni Ọmọ Rẹ Máa Sọ? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ tìẹ ti mọ bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé ara wọn yékéyéké bí wọ́n bá bá ara wọn nírú ipò yẹn? Ǹjẹ́ wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn gbà pé àṣẹ Ọlọ́run ni pé ká ‘ta kété sí ẹ̀jẹ̀’? (Ìṣe 15:29; 21:25) Ṣé wọ́n á lè fi Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ìgbàgbọ́ wọn? Ṣé wọ́n ní ìgboyà tó láti dúró ti ìpinnu tí wọ́n ṣe lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ báwọn dókítà bá láwọn gbà pé ẹ̀mí wọn wà nínú ewu kódà táwọn òbí wọn ò bá sí nítòsí? Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ‘ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa,’ báwo lo ṣe lè mú káwọn ọmọ rẹ wà ní sẹpẹ́ de ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ èyíkéyìí tó lè dán ìṣòtítọ́ wọn wò?—Oníw. 9:11; Éfé. 6:4.
4, 5. (a) Kí ni ojúṣe àwọn òbí, ọ̀nà wo sì ni wọ́n lè gbà ṣe é? (b) Kí làwọn nǹkan tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́?
4 Ẹ̀yín Òbí Kí Lẹ Lè Ṣe? Ojúṣe yín ni láti kọ́ àwọn ọmọ yín nípa ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ẹ̀jẹ̀. (2 Tím. 3:14, 15) Wàá rí àlàyé tó ṣe kedere nípa rẹ̀ nínú ìwé Reasoning ní ojú ìwé 70 sí 74. Kẹ́ ẹ jọ fara balẹ̀ jíròrò rẹ̀ nínú ìdílé yín. Ẹ lo àkòrí náà “If Someone Says—” [Bí ẹnì kan bá sọ pé—] bó ṣe wà ní ojú ìwé 74 sí 76, láti fi ṣe ìdánrawò pẹ̀lú àwọn ọmọ yín nípa bí wọ́n á ṣe ṣàlàyé ara wọn lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ àti ohun tó mú kí wọ́n gba nǹkan yẹn gbọ́. (1 Pét. 3:15) Lára àwọn ìtẹ̀jáde tó tún lè là wá lóye lórí ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀ ni ìwé pẹlẹbẹ How Can Blood Save Your Life? àti Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 14 sí 24. Síwájú sí i, àwọn fídíò bíi Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights àti No Blood—Medicine Meets the Challenge, tá a kó sórí àwo DVD tó ní àkọlé náà Transfusion Alternatives—Documentary Series, ṣàlàyé tó tẹ́rùn nípa bí ìtọ́jú ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ ṣe bọ́gbọ́n mu, tó sì gbéṣẹ́ tó. Ǹjẹ́ ẹ ti wo àwọn fídíò yìí, tẹ́ ẹ sì ti jíròrò wọn lẹ́nu àìpẹ́ yìí nínú ìdílé yín?
5 Ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ káwọn náà ‘lè ṣàwárí fúnra wọn ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé,’ lórí ọ̀ràn ìgbẹ̀jẹ̀sára. Ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n á tó lè ṣèpinnu gidi tí inú Jèhófà á dùn sí.—Róòmù 12:2.