Rí I Pé O Wo Fídíò No Blood—Medicine Meets the Challenge
Báwo ni ohun tó o mọ̀ nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tó ti wà báyìí lágbo ìmọ̀ ìṣègùn fún ṣíṣe ìtọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀ ṣe pọ̀ tó? Ǹjẹ́ o lóye ohun tí díẹ̀ lára àwọn ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ náà jẹ́ àti bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́? Wo fídíò yìí, kó o sì wá fi àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí yẹ ìmọ̀ rẹ wò.—Àkíyèsí: Nítorí pé fídíò náà ní àwọn ibì kan tá a ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ráńpẹ́, kí àwọn òbí lo òye nígbà tí wọ́n bá ń wo fídíò náà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
(1) Kí ni ìdí pàtàkì tó mú kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa kọ ìfàjẹ̀sínilára, ibo la sì ti rí ìlànà yẹn nínú Bíbélì? (2) Nígbà tí a bá nílò ìtọ́jú, kí la máa ń fẹ́ kí àwọn oníṣègùn ṣe fún wa? (3) Ẹ̀tọ́ pàtàkì wo ni aláìsàn ní? (4) Ìdí wo ló fi bọ́gbọ́n mu fún wa tó sì tún bá ẹ̀tọ́ mu láti kọ ìfàjẹ̀sínilára? (5) Tí ẹnì kan bá ti pàdánù ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀jẹ̀, àwọn ohun méjì wo ló ṣe pàtàkì jù lọ tí àwọn dókítà gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe? (6) Àwọn ewu wo ni gbígba ẹ̀jẹ̀ sára lè mú wá? (7) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun èlò tí àwọn dókítà oníṣẹ́-abẹ ní níkàáwọ́ láti dín pípàdánù ẹ̀jẹ̀ kù lásìkò iṣẹ́ abẹ? (8) Kí ló yẹ kó o fẹ́ láti mọ̀ nípa ìtọ́jú èyíkéyìí tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ? (9) Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an ṣeé ṣe láìsí pé wọ́n ń fàjẹ̀ síni lára? (10) Kí ni àwọn oníṣègùn tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i ti ń múra tán láti ṣe báyìí fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí ló sì ṣeé ṣe kó wá di ìlànà ìtọ́jú tí wọ́n á máa lò fún gbogbo aláìsàn bí àkókò ti ń lọ?
Kò sí iyèméjì pé yóò dára gan-an láti wo fídíò No Blood yìí pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa èyíkéyìí, ọkọ tàbí aya wa, tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, àwọn òṣìṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa, àwọn olùkọ́, àtàwọn ọmọ ilé ìwé ẹlẹgbẹ́ wa, tí wọ́n lè máa béèrè ìbéèrè nípa ojú tá a fi ń wo ọ̀ràn ẹ̀jẹ̀. Tí ẹnì kan bá yàn láti gba ìtọ́jú èyíkéyìí tá a fi hàn nínú fídíò yìí, ìyẹn á jẹ́ ìpinnu ara ẹni tẹ́ni náà gbé ka orí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ June 15, 2000 àti ti October 15, 2000.