Fídíò Tó Sọ Nípa Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbo Àwọn Onímọ̀ Ìṣègùn
Ní báyìí, àwọn onímọ̀ nípa òfin àtàwọn onímọ̀ nípa ìṣègùn ti túbọ̀ ń fara mọ́ ohun tí àwọn aláìsàn fẹ́, wọ́n sì tún ń bọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ wọn lábẹ́ òfin. Èyí ti wá mú àwọn ìtọ́jú tuntun àtàwọn ìlànà tuntun wá sójú táyé, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì lè jàǹfààní nínú rẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Èyí gan-an ni kókó tí fídíò náà, Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights dá lé lórí. Wò ó, kí o sì ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ohun tó o kọ́ níbẹ̀.—Àkíyèsí: Nítorí pé fídíò náà ní àwọn ibì kan tá a ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ráńpẹ́, kí àwọn òbí lo òye nígbà tí wọ́n bá ń wo fídíò náà pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké.
(1) Kí nìdí tí àwọn oníṣègùn fi ń tún ìfàjẹ̀sínilára gbé yẹ̀ wò? (2) Fúnni ní àpẹẹrẹ mẹ́ta nípa àwọn iṣẹ́ abẹ tó le gan-an tí wọ́n ṣe láìlo ẹ̀jẹ̀. (3) Jákèjádò ayé, àwọn oníṣègùn àtàwọn dókítà oníṣẹ́ abẹ mélòó ló ti sọ báyìí pé àwọ́n ṣe tán láti máa tọ́jú àwọn aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀? Kí nìdí tí wọ́n fi gbà láti máa ṣe bẹ́ẹ̀? (4) Kí làwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe láwọn ọsibítù lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn nípa ìlò ẹ̀jẹ̀? (5) Àwọn ewu wo ló so mọ́ ìfàjẹ̀sínilára? (6) Ibo ni ọ̀pọ̀ àwọn ògbógi parí èrò sí báyìí nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú àwọn ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ? (7) Kí ló ń fa àìtó sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀? Báwo ni ara ẹ̀dá èèyàn ṣe lè gbé ìṣòro yìí pẹ́ tó? Kí la lè ṣe sí i? (8) Báwo la ṣe lè mú kí sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ara aláìsàn pọ̀ sí i? (9) Àwọn ìlànà wo ni wọ́n ń lò báyìí láti dín bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń ṣòfò lásìkò iṣẹ́ abẹ kù? (10) Ǹjẹ́ àwọn ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ lè ṣiṣẹ́ fún àwọn ọmọ kékeré tàbí fún àwọn èèyàn tó ní ìṣòro tó ṣeé ṣe kó mú ẹ̀mí lọ? (11) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìlànà pàtàkì tó dá lórí bíbọ̀wọ̀ fún èrò aláìsàn tí ìtọ́jú tó dára ní nínú? (12) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni yan irú ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ tí wọ́n á fẹ́ láti gbà ṣáájú kí ìṣòro tó dé? Ọ̀nà wo la lè gbà ṣe èyí?
Ìpinnu ara ẹni ni títẹ́wọ́gba àwọn ìtọ́jú kan tó fara hàn nínú fídíò náà jẹ́, ìyẹn á sì jẹ́ ìpinnu tí ẹnì kọ̀ọ̀kan gbé karí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́. Ṣé o ti pinnu irú ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ tí wàá fẹ́ láti gbà tàbí tí wàá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ gbà? Bákan náà, jẹ́ kí àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ nípa ìpinnu rẹ ní kíkún àti ìdí tó o fi ṣe ìpinnu náà.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ June 15 àti October 15, 2000.