ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/10 ojú ìwé 3
  • Má Fi Falẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Fi Falẹ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Fi Falẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Ǹjẹ́ O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìtọ́jú Pàjáwìrì?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
km 1/10 ojú ìwé 3

Má Fi Falẹ̀!

Fi kí ni falẹ̀? Kíkọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì DPA (ìyẹn káàdì tá a fi ń fa àṣẹ ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́) tá a máa ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá ti ṣèrìbọmi. Nítorí a “kò mọ ohun tí ìwàláàyè [wa] yóò jẹ́ lọ́la,” ó ṣe pàtàkì pé ká tètè kọ ìpinnu wa lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn tá a fẹ́ àti ọ̀nà tá a máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú wa tá a bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì. (Ják. 4:14; Ìṣe 15:28, 29) A ti ṣe àwọn àlàyé tó lè ràn yín lọ́wọ́ sínú fídíò Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights, èyí tó dá lórí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a lè gbà dípò ẹ̀jẹ̀. Èdè Gẹ̀ẹ́sì la fi ṣe fídíò yìí, torí náà tó o bá gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì, wo fídíò yìí, kó o sì fàwọn ìsọfúnni tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣàtúnyẹ̀wò àwọn nǹkan tó o bá kọ́ tàdúràtàdúrà.—Àkíyèsí: Nítorí pé a yàwòrán àwọn iṣẹ́ abẹ mélòó kan sínú fídíò yìí, a gba ẹ̀yin òbí nímọ̀ràn pé kẹ́ ẹ pinnu fúnra yín bóyá káwọn ọmọ yín kéékèèké wò ó.

(1) Àwọn kan lágbo àwọn oníṣègùn ń tún ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára gbé yẹ̀ wò torí pé àwọn aláìsàn púpọ̀ sí i ni kò fara mọ́ ìfàjẹ̀sínilára. Bákan náà ọ̀pọ̀ ewu àti ìnáwó tó so mọ́ ìfàjẹ̀sínilára wà lára àwọn ohun tó mú káwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ máa tún ọ̀rọ̀ náà gbé yẹ̀ wò. (2) Àwọn dókítà ti ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an láìlo ẹ̀jẹ̀. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú fídíò náà, mẹ́ta lára àwọn iṣẹ́ abẹ náà ni: Iṣẹ́ abẹ ọkàn tí wọ́n ṣe fún ọmọ kékeré kan, iṣẹ́ abẹ ẹ̀dọ̀ àti iṣẹ́ abẹ títo egungun. (3) Jákèjádò ayé, àwọn oníṣègùn tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] láti àádọ́jọ [150] orílẹ̀-èdè ló ti ṣe tán láti máa tọ́jú àwọn aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún ìpinnu àwọn aláìsàn tí wọ́n ń tọ́jú.

(4) Àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe láwọn ọsibítù lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé, ṣe ni wọ́n túbọ̀ ń fa ẹ̀jẹ̀ síni lára láìjẹ́ pé ó pọn dandan àti pé dídín ìfàjẹ̀sínilára kù ń mú àwọn àbájáde tó dára wá. (5) Lára àwọn ewu tó so mọ́ ìfàjẹ̀sínilára ni pé ẹ̀jẹ̀ lè ní kòkòrò bakitéríà nínú, ẹ̀jẹ̀ tí a fà síni lára lè kó àrùn tí kòkòrò fáírọ́ọ̀sì ń fà ranni, ó lè sọ agbára ìdènà àrùn ara ẹni tó gbà á di ahẹrẹpẹ, àṣìṣe sì lè ti ọwọ́ èèyàn wá. (6) Gẹ́gẹ́ bí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ti sọ, lára àwọn àǹfààní tó wà nínú àwọn ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ ni pé, ó ń mú kí ìtọ́jú táwọn aláìsàn ń rí gbà dára sí i, ìnáwó tó ń bá ìtọ́jú lọ dín kù, àwọn ìtọ́jú tí kò náni lówó, tí kò léwu, tó sì gbéṣẹ́ ti wà báyìí.

(7) Èèyàn máa ń ní ìṣòro anemia nígbà tí èròjà tó ń gbé afẹ́fẹ́ oxygen nínú ẹ̀jẹ̀ (ìyẹn hemoglobin) kò bá pọ̀ tó. Ìwọ̀n sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ kò sì tó nìyẹn. Báwo ni ara ẹ̀dá èèyàn ṣe lè gbé ìṣòro yìí pẹ́ tó? Ẹ̀dá èèyàn lè fara da ìwọ̀n èròjà hemoglobin tó lọ sílẹ̀ gan-an ju ìwọ̀n tí wọ́n rò pé ó léwu tẹ́lẹ̀ lọ. Àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ oníṣègùn sì dábàá pé èèyàn lè lo oògùn tó máa ń mú ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i láti kápá ìṣòro yìí. (8) Báwo la ṣe lè mú sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ara aláìsàn pọ̀ sí i? Sẹ́ẹ̀lì pupa inú ẹ̀jẹ̀ ara aláìsàn lè pọ̀ sí i tó bá lo àfikún èròjà Iron. Nínú àwọn ọ̀ràn kan, wọ́n lè lo oògùn erythropoietin (ìyẹn EPO) láti mú ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ pa dà sí bó ṣe yẹ. Láwọn orílẹ̀-èdè kan èròjà albumin tí wọ́n mú jáde látinú ẹ̀jẹ̀ máa ń wà nínú oògùn EPO. Yálà Kristẹni kan fara mọ́ irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ tàbí kò fara mọ́ ọn jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn. (9) Àwọn ìlànà wo ni wọ́n ń lò báyìí láti dín bí ẹ̀jẹ̀ ṣe máa ń ṣòfò lásìkò iṣẹ́ abẹ kù? Àwọn ìlànà náà ni: lílo ìṣọ́ra gidigidi lásìkò iṣẹ́ abẹ, lílo àwọn ohun èlò iná mànàmáná láti dí ibi tí ẹ̀jẹ̀ ti ń ṣàn jáde, àwọn oògùn tó ń dín ẹ̀jẹ̀ dídà kù, ṣíṣàì jẹ́ kí sẹ́ẹ̀lì ẹ̀jẹ̀ ṣòfò lákòókò iṣẹ́ abẹ. Gbígba àwọn oògùn àtàwọn ìlànà yìí jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀rí ọkàn.

(10) Ǹjẹ́ àwọn ìtọ́jú tí kò la ìfàjẹ̀sínilára lọ lè ṣiṣẹ́ fún àwọn ọmọ kékeré tàbí fún àwọn tí ẹ̀mí wọn wà nínú ewu? Bẹ́ẹ̀ ni. A rí àpẹẹrẹ ọmọ ọdún mẹ́rin kan nínú fídíò náà tí ọkàn rẹ̀ kò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ, tí wọ́n sì ṣe onírúurú iṣẹ́ abẹ tó díjú gan-an fún láìlo ẹ̀jẹ̀. Ní ọ̀kan lára àwọn ilé ìwòsàn tó máa ń bójú tó àwọn aláìsàn tí ìṣòro wọn le koko ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, níbi tí wọ́n ti máa ń ṣe ọgọ́rọ̀ọ̀rún iṣẹ́ abẹ dídíjú lọ́dọọdún fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ̀ láti gba ẹ̀jẹ̀, àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ kú. (11) Ọ̀kan lára àwọn ìlànà pàtàkì nípa bíbọ̀wọ̀ fún èrò aláìsàn tí ìtọ́jú tó dára ní nínú ni bíbọ̀wọ̀ fún ẹ̀tọ́ aláìsàn láti gba irú ìtọ́jú kan tàbí láti kọ̀ ọ́. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni mọ irú ìtọ́jú tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ tí wọ́n máa yàn ṣáájú kí ìṣòro tó dé. Ṣé o ti ṣe ìpinnu tó ṣe gúnmọ́ lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn tàbí ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ? Ṣé o sì ti kọ̀rọ̀ kún káàdì DPA rẹ? Tó o bá fẹ́ àlàyé kíkún lórí ọ̀ràn yìí, fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò orí 7 nínú ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” àtàwọn ìtẹ̀jáde míì tá a tọ́ka sí níbẹ̀. Tún wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2006, lábẹ́ àkọlé náà: “Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?” Má gbà gbé láti kọ ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn tó o yàn sínú káàdì DPA rẹ lọ́nà tó yẹ. Rí i dájú pé o fi ìpinnu rẹ tó àwọn tó o yàn pé kí wọ́n ṣojú fún ẹ létí, má sì gbàgbé láti ṣàlàyé ìpinnu rẹ ní kíkún fún àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 3]

• Ṣé o ti pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tàbí ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ?

• Ǹjẹ́ káàdì DPA rẹ tó o ti kọ ọ̀rọ̀ kún máa ń wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo torí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́