Ǹjẹ́ O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìtọ́jú Pàjáwìrì?
Ìtọ́jú pàjáwìrì lè wáyé láìròtẹ́lẹ̀. (Ják. 4:14) Nípa bẹ́ẹ̀, ẹni tó ń fọgbọ́n hùwà ti máa múra sílẹ̀ ṣáájú bó bá ti lè ṣeé ṣe tó. (Òwe 22:3) Ǹjẹ́ o ti pinnu irú ìtọ́jú tó o fẹ́ àti ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú rẹ, ṣé o sì ti kọ ìpinnu rẹ sílẹ̀? A ti ṣe àwọn àlàyé tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ sínú fídíò tá a pè ní Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights, àti èkejì tá a ṣe sórí DVD, tá a pè ní Transfusion-Alternatives—Documentary Series. Bó o ṣe ń wo fídíò yìí, wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí. Nítorí pé àwọn iṣẹ́ abẹ mélòó kan wà nínú fídíò yìí, a gba ẹ̀yin òbí nímọ̀ràn pé kẹ́ ẹ pinnu bóyá káwọn ọmọ yín kéékèèké wò ó tàbí kí wọ́n má wò ó.
(1) Kí nìdí tí àwọn kan lágbo àwọn oníṣègùn fi ń tún ọ̀rọ̀ ìfàjẹ̀sínilára gbé yẹ̀ wò? (2) Sọ àpẹẹrẹ iṣẹ́ abẹ mẹ́ta tó ṣòro láti ṣe táwọn dókítà ti ṣe láìsí pé wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ sáwọn aláìsàn wọ̀nyẹn lára. (3) Kí nìdí tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn dókítà tí kì í ṣiṣẹ́ abẹ àti àwọn dókítà tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lágbàáyé fi gbà láti máa tọ́jú àwọn aláìsàn láìfa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára? (4) Kí ni àbájáde àwọn ìwádìí táwọn ilé ìwòsàn kan ṣe láìpẹ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (5) Àwọn ewu wo ló ń bá ìfàjẹ̀sínilára rìn? (6) Ki ní àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nídìí iṣẹ́ ìtọ́jú ìṣègùn sọ nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn yan irú ìtọ́jú ìṣègùn míì tó bá dọ̀rọ̀ fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (7) Kí ló ń fa àìtó ẹ̀jẹ̀? Kí làwọn dókítà lè ṣe láti ran ẹni tí ẹ̀jẹ̀ ò tó lára rẹ̀ lọ́wọ́? (8) Kí làwọn dókítà lè ṣe láti fi kún ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tí ara aláìsàn kan ń pèsè? (9) Ọgbọ́n wo làwọn dókítà máa ń dá táwọn aláìsàn kì í fi í pàdánù ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ jù tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn? (10) Ṣé àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a lè lò dípò ẹ̀jẹ̀ wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ fáwọn ọmọdé àtàwọn aláìsàn tó nílò ìtọ́jú pàjáwìrì? (11) Kí ni ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìlànà ìṣègùn tó pọn dandan fáwọn dókítà láti tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n bá ń tọ́jú aláìsàn?
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹnì kọ̀ọ̀kan ló máa lo ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láti pinnu èyí tó máa gbà nínú àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a fi hàn lórí fídíò yìí, á dára kó o má ṣe jẹ́ kó dìgbà tí nǹkan pàjáwìrì bá ṣẹlẹ̀ kó o tó pinnu èyí tó o máa gbà àtèyí tí o kò ní gbà. Orí 7 nínú ìwé “Ìfẹ́ Ọlọ́run” àti àwọn ìtẹ̀jáde míì tí ìwé náà tọ́ka sí pa pọ̀ pẹ̀lú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2006 máa ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó máa dá ọ lójú. Lẹ́yìn náà, tó o bá ti ṣèrìbọmi, rí i pé o kọ ohun tó o fẹ́ sínú káàdì DPA rẹ, kó o sì rí i pé ò ń mú un dání nígbà gbogbo.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 3]
Ǹjẹ́ o ti pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tó o fẹ́ àti ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú rẹ, ṣé o sì ti kọ ọ́ sílẹ̀?