Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní February 6
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ FEBRUARY 6
Orin 101 àti Àdúrà
□ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 16 ìpínrọ̀ 8 sí 12, àti àpótí tó wà ní ojú ìwé 132 (25 min.)
□ Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Aísáyà 47-51 (10 min.)
No. 1: Aísáyà 51:1-11 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Kristẹni Gbọ́dọ̀ Máa Lo Orúkọ Ọlọ́run?—td 34A (5 min.)
No. 3: Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí Ọlọ́run Ìfẹ́ Pa Ẹnì Kankan Run?—2 Tẹs. 1:6-9 (5 min.)
□ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 2. Àsọyé tá a gbé ka Jí! January–March 2012, ojú ìwé 26 sí 29.
10 min: Àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.
10 min: Àwọn Àbá Tá A Lè Lò Láti Fi Ìwé Ìròyìn Lọni Lóṣù February. Ìjíròrò. Fi ìṣẹ́jú kan tàbí méjì tọ́ka sí àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣeé ṣe kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín. Lẹ́yìn náà, lo àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Ilé Ìṣọ́ February, kó o sì ní kí àwọn ará sọ àwọn ìbéèrè tó lè mú kí àwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wọn, kí wọ́n sì sọ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n lè fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun kan náà ni kó o ṣe nípa àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí àkòrí Jí! January–March 2012, tí àkókò bá ṣì wà, ẹ tún lè jíròrò àpilẹ̀kọ mìíràn nínú ìwé ìròyìn méjèèjì. Ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìwé ìròyìn náà lọni.
Orin 96 àti Àdúrà