Àwọn Ìfilọ̀
◼ Ìwé tá a máa lò ní January: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún ẹnì kan ní ìwé náà. Bí onílé bá ti ní ìwé yìí tí kò sì gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ẹ fún un ní ìwé ìròyìn tàbí ìwé pẹlẹbẹ èyíkéyìí tí ọjọ́ rẹ̀ ti pẹ́ tó máa nífẹ̀ẹ́ sí. February: Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé àti Sún Mọ́ Jèhófà. March: Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Ẹ sapá láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà àkọ́kọ́ tẹ́ ẹ bá fún ẹnì kan ní ìwé náà. April: Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti Jí!
◼ Bẹ̀rẹ̀ láti oṣù February, àsọyé tuntun fún gbogbo ènìyàn tí àwọn alábòójútó àyíká yóò máa sọ ni “Ṣé Jèhófà Lo Gbẹ́kẹ̀ Lé?”
◼ Inú wa dùn láti fi tó yín létí pé lọ́dún 2012, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe ní Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Badagry ní February 18 àti June 2-3. Benin City ní February 25-26 àti July 7; Ibadan ní April 14-15 àti July 14; Kwali ní March 10-11 (àpéjọ àyíká nìkan); Lekki ní May 19-20 àti August 26; Uli ní May 5-6 àti August 18. Bákan náà, a máa ṣe àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe lédè Faransé ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ yìí: Badagry ní April 1 àti June 9-10. Èdè Faransé àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Amẹ́ríkà la máa fi ṣe àwọn àpéjọ yìí látòkèdélẹ̀. A ké sí gbogbo àwọn tó gbọ́ àwọn èdè yìí pé kí wọ́n wá.
◼ Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìtẹ̀jáde ti oṣù February 1, 2012, Ilé Ìṣọ́ tá à ń fi sóde yóò máa ní abala tá a pè ní “Ẹ̀kọ́ Bíbélì.” A ṣe é fún àwọn òbí kí wọ́n lè lò ó fún àwọn ọmọ wọn ọlọ́dún mẹ́ta àti àwọn tí kò tó bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí ni yóò máa jáde ní oṣù tí àwọn àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Kọ́ Ọmọ Rẹ” àti “Abala Àwọn Ọ̀dọ́” kò bá jáde.