Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù February
“Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run ní ètò kan lónìí tó ń lò àbí o rò pé àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ni Ọlọ́run ń lò? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí ìwé ìròyìn yìí sọ nípa àwọn tí Ọlọ́run ṣètò wọn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn.” Ṣí Ilé Ìṣọ́ February 1 sí ojú ìwé 26, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ nínú ìwé ìròyìn náà àti ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, ó kéré tán, tó wà nínú ìwé ìròyìn náà. Fún un ní àwọn ìwé ìròyìn náà kó o sì ṣàdéhùn ìgbà tí wàá pa dà wá kẹ́ ẹ lè jíròrò ìbéèrè tó kàn.
February 1
“Ǹjẹ́ o ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ‘Amágẹ́dọ́nì’ rí? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ibi tí ọ̀rọ̀ náà ‘Amágẹ́dọ́nì’ ti wá. [Ka Ìṣípayá 16:16, kó o wá béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé:] Kí lo rò pé a lè ṣe láti la ogun yìí já? [Jẹ́ kó fèsì. Wá fi ohun tó wà níwájú ìwé ìròyìn náà hàn án kó o sì sọ pé:] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ìdáhùn tí Bíbélì fúnni lórí àwọn ìbéèrè yìí.”
January–March
“Pẹ̀lú bí ọrọ̀ ajé ṣe dẹnu kọlẹ̀ lákòókò yìí, kí nìdí tó fi dára pé ká máa ṣọ́wó ná ká sì tún máa tọ́jú owó pa mọ́ torí ọjọ́ ìdágìrì? [Jẹ́ kó fèsì. Wá ka Oníwàásù 7:12.] Kó tó di pé owó lè jẹ́ ìdáàbòbò ní àkókò ìṣòro, a jẹ́ pé a mọ bá a ṣe lè tọ́jú rẹ̀ pa mọ́. Àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 4 sí 6 nínú ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn àbá tó ṣeé mú lò nípa béèyàn ṣe lè tọ́jú owó pa mọ́.”