Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù September
“Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí ìgbàgbọ́ wọn sì yàtọ̀ síra máa ń gbàdúrà. Ǹjẹ́ o ronú pé Ọlọ́run ń tẹ́tí sí gbogbo àdúrà, ṣé ó sì máa ń dáhùn wọn?” Jẹ́ kó fèsì. Mú Ilé Ìṣọ́ September 1 fún un, kẹ́ ẹ sì jọ ka àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16, kẹ́ ẹ jíròrò rẹ̀, kẹ́ ẹ sì ka ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Béèrè bóyá onílé á fẹ́ láti gba ìwé náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ September 1
Fi iwájú ìwé ìròyìn náà hàn án, kó o sì sọ pé: “Kí ni ìdáhùn rẹ sí ìbéèrè yìí? [Jẹ́ kó fèsì.] Gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ. [Ka 1 Jòhánù 5:19.] Gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe sọ, “ẹni burúkú náà,” tàbí Èṣù, ló ń darí ayé yìí. Àmọ́, ìyẹn tún gbé àwọn ìbéèrè kan wá síni lọ́kàn. Ibo ni Èṣù ti wá? Ṣé ẹni gidi kan ni? Kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà á láyè láti máa darí ayé? Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa rẹ̀.”
Ji! July–September
Àwa èèyàn sábà ń sọ ọ̀rọ̀ àwọn ẹlòmíì lẹ́yìn, tó sì jẹ́ pé a ò lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ lójú wọn. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Bíbélì sọ ìdí kan tí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fi máa ń ṣẹlẹ̀ nínú Jákọ́bù 3:2. Ìwé ìròyìn yìí sọ ọ̀nà mẹ́rin tá a lè gbà máa sọ̀rọ̀ tó dáa.” Lo àpilẹ̀kọ tó bẹ̀rẹ̀ lójú ìwé 20.