ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g 7/11 ojú ìwé 20-21
  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Ṣọ́ Ẹnu Rẹ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Ṣọ́ Ẹnu Rẹ
  • Jí!—2011
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sọ̀rọ̀ Tó Dáa
  • Ẹ Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ẹnu Yín “Dára fún Gbígbéniró”
    ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run’
  • Máa Fi Ahọ́n Rẹ Sọ̀rọ̀ Tó Ń Gbéni Ró
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2015
  • Báwo La Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Tá À Ń Sọ Múnú Jèhófà Dùn?
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ṣé Ọ̀rọ̀ Ẹnu Ẹ Máa Ń Tu Àwọn Èèyàn Lára?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
Àwọn Míì
Jí!—2011
g 7/11 ojú ìwé 20-21

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Máa Ṣọ́ Ẹnu Rẹ

Lẹ́yìn tí olórí orílẹ̀-èdè kan àti obìnrin àgbàlagbà kan ti jọ sọ̀rọ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, láìmọ̀ pé ẹ̀rọ ìgbóhùn sáfẹ́fẹ́ náà ṣì wà ní títàn sílẹ̀, olórí ìjọba náà sọ pé alákatakítí ni obìnrin àgbàlagbà náà, ó sì fi ìbínú sọ fáwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé wọn ì bá má fún un láyè. Ẹnu ya ọ̀pọ̀ èèyàn jákèjádò orílẹ̀-èdè náà láti gbọ́ irú ọ̀rọ̀ tí olórí ìjọba náà sọ nípa obìnrin yìí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí bà á lórúkọ jẹ́, àwọn èèyàn kò sì dìbò fún un láti tún un yàn sípò nígbà ìdìbò tí wọ́n ṣe ní ọjọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn náà.

KÒ SÍ èèyàn tó lè kó ahọ́n rẹ̀ níjàánu láìkù síbì kan. (Jákọ́bù 3:2) Síbẹ̀, ìṣẹ̀lẹ̀ tá a sọ lókè yìí fi hàn pé ó yẹ kéèyàn máa ṣọ́ ẹnú rẹ̀. Bóyá o máa ní orúkọ rere lọ́dọ̀ àwọn èèyàn, bóyá ọwọ́ rẹ máa tẹ ohun tó wù ẹ́ láti fi ayé rẹ ṣe, bóyá o má ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn èèyàn, gbogbo rẹ̀ sinmi lórí irú ọ̀rọ̀ tó máa ń jáde lẹ́nu rẹ àti ọ̀nà tó ò ń gbà sọ ọ́.

Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ohun tí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ lè ṣe tún jù bẹ́ẹ̀ lọ? Bíbélì sọ pé ńṣe ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ń fi irú èèyàn tó o jẹ́ gan-an hàn. Jésù sọ pé: “Nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu ń sọ.” (Mátíù 12:34) Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ, ohun tó ò ń rò àti bí nǹkan ṣe ń rí lára rẹ, èyí ló sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ irú ẹni tó o jẹ́ gan-an, ó ṣe pàtàkì pé kó o túbọ̀ máa ṣàkíyèsí ọ̀nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀. Ǹjẹ́ Bíbélì tiẹ̀ lè ṣèrànwọ́? Jẹ́ ká wò ó ná.

Bó O Ṣe Lè Túbọ̀ Máa Sọ̀rọ̀ Tó Dáa

Kó tó di pé o sọ̀rọ̀ jáde lẹ́nu, wàá ti kọ́kọ́ rò ó ná. Torí náà, kó bàa lè ṣeé ṣe fún ẹ láti máa sọ̀rọ̀ tó dáa jáde lẹ́nu, ó ṣe pàtàkì pé kó o túbọ̀ máa ronú lọ́nà tó dáa. Jẹ́ ká wo bí fífi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò ṣe lè ní ipa lórí èrò rẹ, àti ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ.

Fi ohun rere kún inú ọkàn rẹ. Bíbélì sọ irú àwọn nǹkan rere téèyàn lè fi kún inú ọkàn rẹ̀, ó ní: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—Fílípì 4:8.

Tó o bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rere yẹn, èrò tí kò dáa kò ní ríbi dúró sí lọ́kàn rẹ. Má gbàgbé pé ohun tó ò ń rí àti ohun tó ò ń gbọ́ máa ń ní ipa tó lágbára lórí èrò rẹ. Torí náà, tí o kò bá fẹ́ kí èrò tí kò dáa àti èrò àìmọ́ máa wá sí ẹ lọ́kàn, máa sá fún àwọn nǹkan tó lè sọ ọkàn rẹ dìbàjẹ́. Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé, kó o máa sá fún àwọn eré ìnàjú oníwà ipá àti èyí tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ. (Sáàmù 11:5; Éfésù 5:3, 4) Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o máa ronú nípa àwọn nǹkan tó jẹ́ mímọ́ àtàwọn nǹkan rere. Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe bẹ́ẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ka Òwe 4:20-27; Éfésù 4:20-32; àti Jákọ́bù 3:2-12. Wo bí fífi àwọn ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò ṣe lè mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ sunwọ̀n sí i.a

Máa ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀. Òwe 12:18 sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà, ṣùgbọ́n ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo sábà máa ń fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ‘gún’ àwọn èèyàn tàbí tó o sábà máa ń sọ ohun tó dùn wọn, á dáa kó o sapá láti máa ronú dáadáa kó o tó sọ̀rọ̀. Fetí sí ìmọ̀ràn tó ta yọ tó wà ní Òwe 15:28, ó ní: “Ọkàn-àyà olódodo máa ń ṣe àṣàrò láti lè dáhùn, ṣùgbọ́n ẹnu àwọn ẹni burúkú máa ń tú àwọn ohun búburú jáde.”

Pinnu pé wàá ṣe ohun kan. Ní oṣù tó ń bọ̀, pinnu pé o kò ní sọ ohun tó bá kọ́kọ́ wá sí ẹ lọ́kàn, ní pàtàkì nígbà tẹ́nì kan bá múnú bí ẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni kó o ronú lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí, kó o sì sapá gidigidi láti máa sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ọgbọ́n, ìfẹ́, ati lọ́nà pẹ̀lẹ́tù. (Òwe 15:1-4, 23) Àmọ́, kò tán síbẹ̀ o.

Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì gbàdúrà pé: “Kí àwọn àsọjáde ẹnu mi àti àṣàrò ọkàn-àyà mi dùn mọ́ ọ, ìwọ Jèhófà.” (Sáàmù 19:14) Sọ fún Jèhófà Ọlọ́run pé ó wù ẹ́ gan-an láti máa sọ́rọ̀ lọ́nà tó máa múnú rẹ̀ dùn, tó sì máa jẹ́ kí ara tu àwọn èèyàn. Òwe 18:20, 21 sọ pé: “Mú kí ọ̀rọ̀ tí ó dára ti ẹnu rẹ jáde, inú rẹ yóò sì dùn. Ikú àti ìyè wà nínú ọ̀rọ̀!”—Contemporary English Version.

Jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa tọ́ ẹ sọ́nà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí dígí tó o lè fi ṣàyẹ̀wò ara rẹ. (Jákọ́bù 1:23-25) Bí àpẹẹrẹ, bó o ṣe ń ronú lórí ìlànà Bíbélì mẹ́ta tó tẹ̀ lé e yìí, bi ara rẹ pé, ‘Ǹjẹ́ ọ̀nà tí mò ń gbà sọ̀rọ̀ àti ohun táwọn èèyàn ń sọ nípa mi bá ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ mu?’

“Ìdáhùn kan, nígbà tí ó bá jẹ́ lọ́nà pẹ̀lẹ́, máa ń yí ìhónú padà, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Ǹjẹ́ o máa ń sọ̀rọ̀ jẹ́jẹ́, lọ́nà pẹ̀lẹ́tù?

“Kí àsọjáde jíjẹrà má ti ẹnu yín jáde, bí kò ṣe àsọjáde yòówù tí ó dára fún gbígbéniró bí àìní bá ṣe wà, kí ó lè fi ohun tí ó ṣeni lóore fún àwọn olùgbọ́.” (Éfésù 4:29) Ǹjẹ́ ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ máa ń gbé àwọn èèyàn ró?

“Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”(Kólósè 4:6) Ǹjẹ́ o máa ń sapá gan-an láti sọ̀rọ̀ tó ń buyì kúnni tó sì dùn-ún gbọ́ létí, kódà nígbà tí kò bá tiẹ̀ rọrùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?

Tó o bá wo ara rẹ nínú dígí, tó o sì ṣàtúnṣe àwọn ibi tó yẹ, wàá ṣeé rí mọ́ni, ara tiẹ̀ náà á sì balẹ̀. Irú àǹfààní tó o máa jẹ náà nìyí, tó o bá ń wo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bíi dígí, tó o sì ń mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà sọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a O lè ka àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì sí i lórí ìkànnì wa www.watchtower.org.

KÍ LÈRÒ Ẹ?

● Kí ni ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ ń fi hàn?—Lúùkù 6:45.

● Báwo ló ṣe yẹ kó o máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀?—Éfésù 4:29; Kólósè 4:6.

● Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó máa jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ dára sí i?—Sáàmù 19:14; Fílípì 4:8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ohun tá a sọ máa ń nípa lórí orúkọ wa àti àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn èèyàn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́