Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Ní oṣù January ọdún 2011, a ní àwọn aṣáájú-ọ̀nà tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélọ́gbọ̀n àti ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó dín mẹ́ta [31,497]. Bákan náà, a fi ìwé ìròyìn tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ síta, iye tá a fi síta jẹ́ mílíọ̀nù méjì, ẹgbẹ̀rún-ún márùn-ún àti ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́wàá [2,005,610]. Èyí máa fún yín ní ìṣírí láti máa bá iṣẹ́ rere yín nìṣó, “nítorí pé ẹ̀san wà fún ìgbòkègbodò yín.”—2 Kíró. 15:7.