Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 12
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 12
Orin 80 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
bt orí 9 ìpínrọ̀ 8 sí 18 (25 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Sáàmù 120-134 (10 min.)
No. 1: Sáàmù 124:1–126:6 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Èṣù Ni Ẹni Tí A Kò Lè Rí Tó Ń Ṣàkóso Ayé—td 10B (5 min.)
No. 3: Báwo Ni A Ṣe Lè Jẹ́ Kí ‘Ojú Wa Mú Ọ̀nà Kan’?—Mát. 6:22, 23 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
5 min: Àwọn Ìfilọ̀.
10 min: Bó O Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn—Apá 1. Àsọyé tá a gbé ka ìwé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run ojú ìwé 258 sí 260, ìpínrọ̀ 5. Ní ṣókí, ṣe àṣefihàn kan tàbí méjì látinú àpilẹ̀kọ náà.
10 min: Ìwọ Kò Mọ Ibi Tí Èyí Yóò Ti Ṣe Àṣeyọrí Sí Rere. (Oníw. 11:6) Ìjíròrò tó dá lórí Ilé Ìṣọ́ October 1, 2004, ojú ìwé 8. Lẹ́yìn tó o bá ti jíròrò ìrírí náà, ní kí àwọn ará sọ ẹ̀kọ́ tí wọ́n rí kọ́.
10 min: “Mọyì Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó O Ní.” Ìbéèrè àti Ìdáhùn.
Orin 22 àti Àdúrà