Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
Ọ̀nà Wo Lo Lè Gbà Sún Mọ́ Ọlọ́run?
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.
1. Ṣé gbogbo àdúrà ni Ọlọ́run ń fetí sí?
Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn orílẹ̀-èdè sún mọ́ òun nípasẹ̀ àdúrà. (Sáàmù 65:2) Àmọ́ kì í ṣe gbogbo àdúrà ló ń fetí sí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò jáwọ́ nínú ìwà ibi, Ọlọ́run kò gbọ́ àdúrà wọn. (Aísáyà 1:15) Bákan náà, bí ọkùnrin kan bá ń hùwà tí kò dáa sí ìyàwó rẹ̀, àdúrà irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè ní ìdènà. (1 Pétérù 3:7) Àmọ́, bí ẹnì kan tó dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá bá ronú pìwà dà, Ọlọ́run á fetí sí àdúrà rẹ̀.—Ka 2 Kíróníkà 33:9-13.
2. Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?
Àǹfààní ló jẹ́ láti máa gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sì jẹ́ ara ọ̀nà tí à ń gbà jọ́sìn rẹ̀, nítorí náà, Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa gbàdúrà sí. (Mátíù 4:10; 6:9) Nítorí pé gbogbo wa jẹ́ aláìpé, a ní láti máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù, nítorí pé òun ni “ọ̀nà” tí Ọlọ́run yàn. (Jòhánù 14:6) Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà kò fẹ́ ká máa gbàdúrà àkọ́sórí tàbí ká máa ka àdúrà látinú ìwé, kàkà bẹ́ẹ̀, ó fẹ́ kí á gbàdúrà látọkànwá.—Ka Mátíù 6:7; Fílípì 4:6, 7.
Ẹlẹ́dàá wa lè gbọ́ àdúrà tí a gbà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ pàápàá. (1 Sámúẹ́lì 1:12, 13) Ó ní kí á máa gbàdúrà nígbà gbogbo, ìyẹn ní ìbẹ̀rẹ̀ àti òpin ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, nígbà oúnjẹ àti nígbà tí a bá ní ìṣòro.—Ka Sáàmù 55:22; Mátíù 15:36.
3. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi ń pàdé pọ̀?
Kò rọrùn láti sún mọ́ Ọlọ́run, nítorí pé à ń gbé láàárín àwọn tí kò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì ń fi àlàáfíà tí Ọlọ́run ṣèlérí fún aráyé ṣe yẹ̀yẹ́. (2 Tímótì 3:1, 4; 2 Pétérù 3:3, 13) Nítorí náà, a ní láti máa bá àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́ láti gba ìṣírí.—Ka Hébérù 10:24, 25.
O lè sún mọ́ Ọlọ́run tí o bá yan àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́rẹ̀ẹ́. Ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣí àǹfààní sílẹ̀ fúnni láti kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìgbàgbọ́ àwọn ẹlòmíì.—Ka Róòmù 1:11, 12.
4. Ọ̀nà wo lo lè gbà sún mọ́ Ọlọ́run?
O lè sún mọ́ Jèhófà tó o bá ṣe àṣàrò lórí ohun tó o ti kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Máa ronú lórí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run, àwọn ìtọ́sọ́nà rẹ̀ àtàwọn ìlérí rẹ̀. Àṣàrò àti àdúrà máa mú kéèyàn ní ìmọrírì látọkànwá sí ìfẹ́ àti ọgbọ́n Ọlọ́run.—Ka Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:1-3.
Tó o bá ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, tó o sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan lo tó lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, ìgbàgbọ́ dà bí ohun aláàyè, tí èèyàn ní láti máa tọ́jú. O ní láti máa fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun nípa ṣíṣe àyẹ̀wò ìdí tó o fi ní ìgbàgbọ́ tó o ní.—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:21; Hébérù 11:1, 6.
5. Àwọn àǹfààní wo lo máa ní tó o bá sún mọ́ Ọlọ́run?
Jèhófà ń bójú tó àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó ń dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ ohun tó lè ba ìgbàgbọ́ àti ìrètí tí wọ́n ní nínú ìyè àìnípẹ̀kun jẹ́. (Sáàmù 91:1, 2, 7-10) Ó ní ká ṣọ́ra fún ṣíṣe ohun tó lè bá ìlera àti ayọ̀ wa jẹ́. Jèhófà ń kọ́ wa bí a ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára jù lọ.—Ka Sáàmù 73:27, 28; Jákọ́bù 4:4, 8.
Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 17 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.