Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ní Saturday Àkọ́kọ́ Lóṣù September
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé ọjọ́ kan ń bọ̀ tí Ọlọ́run máa fi iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan dá a lẹ́jọ́. Ṣé o rò pé ó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọjọ́ Ìdájọ́ àbí ká máa retí ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí ohun tí ibí yìí sọ.” Fún onílé ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ September 1, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àwọn ìsọfúnni tó wà lábẹ́ ìsọ̀rí àkọ́kọ́ lójú ìwé 16 àti ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a tọ́ka sí. Fún onílé ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Láwọn ibi tó pọ̀ karí ayé ni àwọn èèyàn ti máa ń ṣe kèéta tàbí fi ìyà jẹ àwọn obìnrin. Ó ṣeni láàánú pé, ẹ̀sìn táwọn kan ǹ ṣe ti dá kún ìṣòro yìí. Ǹjẹ́ o rò pé Ọlọ́run bìkítà nípa àwọn obìnrin lóòótọ́? [Jẹ́ kó fèsì.] Kíyè sí bí Bíbélì ṣe sọ pé kí àwọn ọkọ máa hùwà sí àwọn ìyàwó wọn. [Ka Éfésù 5:28, 29.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa irú ojú tí Ọlọ́run fi ń wo àwọn obìnrin.”
Ji! July–September
“Lóde òní, kò fi bẹ́ẹ̀ mọ́ àwọn èèyàn lára láti máa gbóríyìn fún àwọn ẹlòmíì. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì. Lẹ́yìn náà ka 2 Tímótì 3:1, 2.] Ìwé ìròyìn yìí jẹ́ ká mọ̀ pé tá a bá ń yin àwọn èèyàn tọkàntọkàn, ó máa ń fún wọn lókun ó sì máa ń jẹ́ kí ara wọn yá gágá.” Fi àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé 28 han onílé.