Àwọn Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tá A Lè Lò
Láti Bẹ̀rẹ̀ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Sátidé Àkọ́kọ́ Lóṣù September
“Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé àwọn áńgẹ́lì wà. Ṣé ẹ̀yin náà gbà bẹ́ẹ̀? [Jẹ́ kó fèsì.] Ẹ̀dá ẹ̀mí làwọn áńgẹ́lì, wọ́n sì lágbára gan-an. Àmọ́ ǹjẹ́ ẹ rò pé wọ́n lè ràn wá lọ́wọ́? Bíbélì sọ bí wọ́n ṣe ń ran àwa èèyàn lọ́wọ́ lóde òní.” Fi ẹ̀yìn Ilé Ìṣọ́ September 1 han onílé, kẹ́ ẹ sì jọ jíròrò àlàyé tó wà lábẹ́ ìbéèrè àkọ́kọ́ àti ó kéré tán, ọ̀kan lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀. Fún un ní ìwé ìròyìn náà, kó o sì ṣètò láti pa dà lọ jíròrò ìdáhùn sí ìbéèrè tó kàn.
Ilé Ìṣọ́ September 1
“Ǹjẹ́ ẹ rò pé àwa èèyàn ti ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe? [Jẹ́ kó fèsì.] Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwa èèyàn kò lè ṣàtúnṣe ayé tó bàjẹ́ yìí, Bíbélì sọ pé Ọlọ́run lè ṣe é, yóò sì ṣàtúnṣe rẹ̀. Ohun tí Sáàmù 65:9 sọ ló jẹ́ kó dá wa lójú pé yóò tún ayé yìí ṣe. [Kà á.] Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ yìí sọ bí Ọlọ́run á ṣe tún ayé ṣe àti bí a ṣe máa gbádùn àwọn nǹkan rere lọ́jọ́ iwájú. Mo fẹ́ fún yín ní ìwé ìròyìn yìí kí ẹ kà á.”
Ji! September–October
Tó o bá fẹ́ fi Jí! lọni ní òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tó o bá rí i pé ó yẹ, o lè sọ pé: “A tún fẹ́ fún yín ní ìwé ìròyìn wa tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé. Ìwé ìròyìn yìí dáhùn ìbéèrè náà, Báwo la ṣe lè máa yanjú aáwọ̀?”