Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 8
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 8
Orin 133 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 12 ìpínrọ̀ 16 sí 21, àpótí tó wà lójú ìwé 127 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 22-25 (10 min.)
No. 1: Númérì 22:36–23:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Ohun Kan Tó Dájú Ni Ìyè Àìnípẹ̀kun—td 33A (5 min.)
No. 3: Bí Ọlọ́run Ṣe Dáàbò Bo Jésù—lr orí 32 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Máa Hùwà Tó Bójú Mu Tó O Bá Ń Wàásù. (2 Kọ́r. 6:3) Ìjíròrò tó dá lórí àwọn ìbéèrè yìí: (1) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa hùwà tó bójú mu nígbà tá a bá ń wàásù? (2) Báwo la ṣe lè máa hùwà tó bójú mu nígbà tí (a) àwùjọ wa bá dé ìpínlẹ̀ tá a ti máa ṣiṣẹ́? (b) a bá ń rìn láti ilé-dé-ilé ní ìpínlẹ̀ tí ilé gbígbé pọ̀ sí tàbí nígbà tá a bá ń wakọ̀ láti ilé kan sí ilé míì láwọn ìgbèríko? (d) a bá dúró lẹ́nu ọ̀nà tí à ń wàásù? (e) ẹni tá a jọ ṣiṣẹ́ bá ń wàásù lọ́wọ́? (ẹ) onílé bá ń sọ̀rọ̀? (f) ọwọ́ onílé bá dí tàbí tí ojú ọjọ́ kò bá dára? (g) onílé bá kàn wá lábùkù?
15 min: “Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Múra Ọkàn Onílé Sílẹ̀ De Ìgbà Ìpadàbẹ̀wò.” Ìjíròrò. Ṣe àṣefihàn akéde kan tó ń dá sọ̀rọ̀ bó ṣe ń múra òde ẹ̀rí sílẹ̀, ó ń ronú ìbéèrè tó máa bi onílé tó sì máa pa dà lọ dáhùn tí onílé bá gba ìwé ìròyìn lọ́wọ́ rẹ̀.
Orin 68 àti Àdúrà