Mú Kí Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Rẹ Sunwọ̀n Sí I—Múra Ọkàn Onílé Sílẹ̀ De Ìgbà Ìpadàbẹ̀wò
Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì: Tá a bá rí ẹnì kan tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa, a máa ń fẹ́ pa dà lọ nígbà tá a lè bá a nílé ká lè bomi rin irúgbìn òtítọ́ tá a gbìn. (1 Kọ́r. 3:6) Èyí sábà máa ń gba pé ká tó kúrò lọ́dọ̀ onílé, ká múra ọkàn rẹ̀ sílẹ̀ de ìgbà ìpadàbẹ̀wò nípa bíbéèrè ìgbà míì tá a lè pa dà wá. Bákan náà, ó máa dáa ká bi onílé ní ìbéèrè kan tá a máa dáhùn nígbà tá a bá pa dà wá. Èyí á jẹ́ kó máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí a máa pa dà wá, tí ìdáhùn sí ìbéèrè náà bá sì wà nínú ìwé tí a fún un, ó ṣeé ṣe kó kà á. Tí a bá múra ọkàn onílé sílẹ̀ de ìjíròrò tó máa wáyé nígbà míì tí a bá pa dà lọ, èyí á tún jẹ́ kó yá wa lára láti pa dà lọ torí a ti ní kókó kan tí a máa bá onílé jíròrò, òun náà á sì mọ ohun tí a ó jọ jíròrò tá a bá pa dà wá. Nígbà tá a bá pa dà lọ, a lè sọ fún un pé ìbéèrè tá a béèrè lọ́jọ́ tá a kọ́kọ́ jọ sọ̀rọ̀ la pa dà wá dáhùn, lẹ́yìn náà ká máa bá ọ̀rọ̀ wa lọ.
Gbìyànjú Èyí Lóṣù Yìí:
Tó o bá ń múra bó o ṣe máa wàásù láti ilé-dé-ilé sílẹ̀, tún múra ìbéèrè tí wàá dáhùn nígbà ìpadàbẹ̀wò sílẹ̀. Jẹ́ kí ẹni tẹ́ ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí mọ ìbéèrè tó o fẹ́ bi onílé náà.