Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ September 15
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ SEPTEMBER 15
Orin 105 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 13 ìpínrọ̀ 1 sí 10 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Númérì 26-29 (10 min.)
No. 1: Númérì 27:15–28:10 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Àwọn Wo Ló Ń Lọ Sí Ọ̀run?—td 33B (5 min.)
No. 3: Jésù Lè Dáàbò Bò Wá—lr orí 33 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
15 min: Báwo La Ṣe Ṣe Sí Lọ́dún Iṣẹ́ Ìsìn Tó Kọjá? Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ̀rọ̀ nípa bí ìjọ yín ṣe ṣe sí lọ́dún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá àti nígbà àkànṣe ìpolongo tó wáyé ní oṣù August. Tẹnu mọ́ àwọn àṣeyọrí tẹ́ ẹ ṣe, kó o sì gbóríyìn fún àwọn ará. Ní kí àwọn ará sọ àwọn ìrírí tó gbádùn mọ́ni tí wọ́n ní lóṣù August, kó o sì fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu akéde kan tó mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ gbòòrò sí i ní oṣù náà. Ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, mẹ́nu ba apá ibì kan tàbí méjì tó yẹ kí ìjọ yín ṣiṣẹ́ lé lórí lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tá a wà yìí, kó o sì sọ àwọn ohun tẹ́ ẹ lè ṣe láti tẹ̀ síwájú.
15 min: “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Náhúmù.” Ìbéèrè àti ìdáhùn.
Orin 46 àti Àdúrà