Àwọn Kókó Inú Ìròyìn Iṣẹ́ Ìsìn
Inú wa dùn láti sọ fún yín pé àwọn akéde tó ròyìn ní oṣù tó gbẹ̀yìn ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ, iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́rìndínlógún àtààbọ̀ ó lé ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́rìndínlógún [330,316]. Èyí jẹ́ ọ̀nà tó dára gan-an láti parí ọdún iṣẹ́ ìsìn 2011! Ní ìpíndọ́gba ní oṣù August, àwọn akéde kọ̀ọ̀kan lo ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó wákàtí mọ́kànlá àbọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan àtààbọ̀. Bákan náà, láàárín ọdún iṣẹ́ ìsìn yẹn, iye àwọn tó ṣèrìbọmi jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlá àti ẹgbẹ̀ta lé mẹ́tàdínláàádọ́rùn-ún [12,687]. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún bó ṣe bù kún ìsapá wa tó sì mú ká ṣe àṣeyọrí ńlá yìí ni pé ká túbọ̀ máa sapá láti jẹ́ káwọn èèyàn gbọ́ nípa ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa pa dà lọ ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ gbogbo àwọn tó bá fetí sí ọ̀rọ̀ wa.—Sm. 116:12-14.