ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/08 ojú ìwé 6
  • Má Fi Falẹ̀!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Má Fi Falẹ̀!
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Má Fi Falẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Fídíò Tó Ṣàlàyé Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀ràn Ìṣègùn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2006
  • Fídíò Tó Sọ Nípa Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lágbo Àwọn Onímọ̀ Ìṣègùn
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2003
  • Ǹjẹ́ O Ti Múra Sílẹ̀ De Ìtọ́jú Pàjáwìrì?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
km 1/08 ojú ìwé 6

Má Fi Falẹ̀!

Fi kí ni falẹ̀? Fífọwọ́ sí káàdì DPA (ìyẹn káàdì tá a fi ń fa àṣẹ ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́) tá a máa ń fún àwọn Ẹlẹ́rìí tó bá ti ṣèrìbọmi. Nítorí a “kò mọ ohun tí ìwàláàyè [wa] yóò jẹ́ lọ́la” ó ṣe pàtàkì pé ká tètè kọ ìpinnu wa lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn àti ọ̀nà tá a máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú wa tá a bá nílò ìtọ́jú pàjáwìrì. (Ják. 4:14; Ìṣe 15:28, 29) A ti ṣe àwọn àlàyé tó lè ràn yín lọ́wọ́ sínú fídíò Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights, èyí tó dá lórí àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a lè gbà dípò ẹ̀jẹ̀. Ẹ wo fídíò yìí, kẹ́ ẹ sì fàwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí ṣàtúnyẹ̀wò àwọn nǹkan tẹ́ ẹ ti kọ́ tàdúràtàdúrà.—Àkíyèsí: Nítorí pé a yàwòrán àwọn iṣẹ́ abẹ mélòó kan sínú fídíò yìí, a gba ẹ̀yin òbí nímọ̀ràn pé kẹ́ ẹ lo ìdánúṣe láti pinnu bóyá káwọn ọmọ yín kéékèèké wò ó.

(1) Kí nìdí táwọn dókítà àtàwọn míì tó ń pèsè ìtọ́jú ìṣègùn fi wá ń tún ọ̀ràn gbígba ẹ̀jẹ̀ sára wò báyìí? (2) Sọ àpẹẹrẹ iṣẹ́ abẹ mẹ́ta tó ṣòro ó ṣe táwọn dókítà ti ṣe láìfa ẹ̀jẹ̀ sáwọn aláìsàn wọ̀nyẹn lára. (3) Mélòó làwọn dókítà àtàwọn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ lágbàáyé tó ti gbà láti tọ́jú àwọn aláìsàn láìfa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára? Kí nìdí tí wọ́n fi gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀? (4) Kí ni àbájáde àwọn ìwádìí táwọn ilé ìwòsàn kan ṣe láìpẹ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (5) Àwọn ewu wo ló ń bá ìfàjẹ̀sínilára rìn? (6) Ibo làwọn ògbógi nídìí iṣẹ́ ìtọ́jú ìṣègùn parí èrò sí nípa àwọn àǹfààní tó wà nínú kéèyàn yan irú ìtọ́jú ìṣègùn míì tó bá dọ̀ràn fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (7) Kí ló ń fa àìtó ẹ̀jẹ̀? Báwo lèèyàn ṣe lè fara dàá tó? Kí làwọn dókítà lè ṣe láti ran ẹni tí ẹ̀jẹ̀ ò tó lára ẹ̀ lọ́wọ́? (8) Kí làwọn dókítà lè ṣe láti fi kún ìwọ̀n ẹ̀jẹ̀ tí ara aláìsàn kan ń pèsè? (9) Ọgbọ́n wo làwọn dókítà máa ń dá táwọn aláìsàn kì í fi í pàdánù ẹ̀jẹ̀ tó pọ̀ jù tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ fún wọn? (10) Ṣé àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a lè lò dípò ẹ̀jẹ̀ wọ̀nyí lè ṣiṣẹ́ fáwọn ọmọdé àtàwọn aláìsàn tó nílò ìtọ́jú pàjáwìrì? (11) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìlànà iṣẹ́ ìṣègùn tó pọn dandan fáwọn dókítà tó bá dọ̀ràn ìtọ́jú tó gbámúṣé? (12) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni tètè máa pinnu irú ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la ẹ̀jẹ̀ lọ tí wọ́n fẹ́ gbà? Báwo la ṣe lè ṣe èyí?

Ìpinnu ara ẹni tá a gbé ka ẹ̀rí ọkàn tá a ti fi Bíbélì kọ́ ni gbígba irú àwọn ìtọ́jú ìṣègùn tá a fi hàn lórí fídíò yìí jẹ́. Ṣé o ti ṣe ìpinnu tó ṣe gúnmọ́ kan lórí irú ìtọ́jú ìṣègùn tàbí ọ̀nà tó o máa fẹ́ kí wọ́n gbà tọ́jú ìwọ àtàwọn ọmọ ẹ? Tó o bá fẹ́ àlàyé tó kún lórí ọ̀ràn yìí, wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004 àti ti October 15, 2000. O tún lè wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2006, lábẹ́ àkọlé náà: “Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?” Rí i dájú pé o fi ìpinnu rẹ tó àwọn tó o yàn pé kí wọ́n ṣojú fún ẹ létí, má sì ṣe gbàgbé láti ṣàlàyé ní kíkún fún àwọn mọ̀lẹ́bí ẹ tí wọn kì í ṣe Ẹlẹ́rìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́