Fídíò Tó Ṣàlàyé Ohun Pàtàkì Kan Tó Ń Ṣẹlẹ̀ Lọ́wọ́ Nínú Ọ̀ràn Ìṣègùn
Àwọn amòfin àtàwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti túbọ̀ ń fetí sí ohun tí aláìsàn bá lóun fẹ́ àti ohun tó jẹ́ ẹ̀tọ́ rẹ̀ lábẹ́ òfin. Èyí ti mú kí wọ́n jágbọ́n àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tuntun àti bí wọ́n á ṣe máa gbọ́ ara wọn yé, èyí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè jàǹfààní nínú rẹ̀. (Ìṣe 15:28, 29) Ohun tí fídíò náà Transfusion-Alternative Health Care—Meeting Patient Needs and Rights dá lé lórí nìyẹn. O ò ṣe wò ó, kó o sì gbé àwọn ohun tó o bá rí kọ́ nínú rẹ̀ yẹ̀ wò.—Àkíyèsí: Nítorí pé fídíò náà láwọn ibì kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ṣókí, káwọn òbí lo ìfòyemọ̀ láti pinnu bóyá káwọn ọmọ wọn kéékèèké wò ó.
(1) Kí nìdí táwọn kan lágbo ìṣègùn fi wá ń tún ọ̀ràn fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára yẹ̀ wò? (2) Sọ irú iṣẹ́ abẹ mẹ́ta tó ṣòro ṣe tí wọ́n lè ṣe láìfa ẹ̀jẹ̀ séèyàn lára. (3) Mélòó làwọn dókítà àti oníṣẹ́ abẹ tó ti gbà láti tọ́jú àwọn aláìsàn láìfa ẹ̀jẹ̀ sí wọn lára? Kí ló mú kí wọ́n gbà láti ṣe bẹ́ẹ̀? (4) Kí ni àbájáde ìwádìí táwọn ilé ìwòsàn kan ṣe láìpẹ́ yìí jẹ́ ká mọ̀ nípa lílo ẹ̀jẹ̀? (5) Àwọn ewu wo ló wà nínú fífa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (6) Ìpinnu wo lọ̀pọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ṣe nípa àǹfààní tí wọ́n rí pé ó wà nínú àwọn nǹkan míì tó lè dípò fífàjẹ̀ síni lára? (7) Kí ló ń fa àìtó ẹ̀jẹ̀? Ibo lagbára èèyàn lè gbé e dé kó tó pa èèyàn lára? Kí la lè ṣe láti dènà rẹ̀? (8) Ọ̀nà wo lèèyàn lè gbà mú ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i nínú ara aláìsàn? (9) Àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n ti lò láti dín ẹ̀jẹ̀ tó máa ń dànù nígbà iṣẹ́ abẹ kù? (10) Ǹjẹ́ àwọn nǹkan míì tí wọ́n lè fi rọ́pò ẹ̀jẹ̀ lè ṣiṣẹ́ fáwọn ọmọdé tàbí fáwọn tí wọ́n wà ní bèbè ikú? (11) Kí ni ọ̀kan lára àwọn ìlànà iṣẹ́ ìṣègùn tó ń jẹ́ kí wọ́n lè tọ́jú aláìsàn lọ́nà tó yẹ? (12) Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni ti pinnu irú àwọn nǹkan àfirọ́pò ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n fẹ́ ṣáájú àkókò? Báwo la ṣe lè ṣe èyí?
Bí ẹnì kan bá máa yan èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tá a fi hàn nínú fídíò yìí, ìyẹn á jẹ́ ìpinnu ara rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó fi Bíbélì kọ́. Ṣó o ti pinnu èyí tí ìwọ àti ìdílé rẹ máa yàn lára àwọn nǹkan téèyàn lè ṣe yàtọ̀ sí gbígba ẹ̀jẹ̀ sára? Rí i pé o jẹ́ káwọn ẹbí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí mọ̀ sí ìpinnu tó o bá ṣe kó o sì sọ ohun tó sún ọ ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ fún wọn.—Wo “Ìbéèrè Látọwọ́ Àwọn Òǹkàwé Wa” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, àti October 15, 2000.