Tọ́jú Rẹ̀
Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?
Bíbélì pàṣẹ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n “ta kété sí . . . ẹ̀jẹ̀.” (Ìṣe 15:20) Ìdí rèé táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀ tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà mẹ́rin tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀, bíi sẹ́ẹ̀lì pupa, sẹ́ẹ̀lì funfun, sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì àti omi inú ẹ̀jẹ̀. Wọn kì í fi ẹ̀jẹ̀ wọn tọrẹ, wọn kì í sì í fi pa mọ́ torí kí wọ́n lè gbà á sára bó bá yá.—Léf. 17:13, 14; Ìṣe 15:28, 29.
Ibo ni wọ́n ti ń rí oògùn tó ní èròjà ẹ̀jẹ̀ nínú, kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa fúnra ẹ̀ pinnu bóyá òun á lo irú oògùn bẹ́ẹ̀?
Àwọn èròjà inú ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n bá yọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ nípasẹ̀ ìlànà kan tí wọ́n ń pè ní fractionation ni wọ́n fi ń ṣe àwọn oògùn wọ̀nyí. Bí àpẹẹrẹ, a lè rí àwọn ohun mẹ́ta yìí yọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ látara omi inú ẹ̀jẹ̀: omi, èyí tó kó ohun tó lé ní ìdá mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá ohun tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀; àwọn purotéènì bí albumin, globulin àti fibrinogen tí wọ́n kó ìdá méje nínú ọgọ́rùn-ún ohun tó para pọ̀ di ẹ̀jẹ̀; àwọn ohun mìíràn bí èròjà inú oúnjẹ, omi ìsúnniṣe inú ara, gáàsì, fítámì, ẹ̀gbin ara àtàwọn ohun tó ń gbé èròjà káàkiri ara tí wọ́n kó nǹkan bí ìdá kan àbọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún.
Ṣáwọn òògùn tó ní àwọn ohun tí wọ́n bá yọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ látara èròjà ẹ̀jẹ̀ nínú tún wà lára àwọn ohun tá a gbọ́dọ̀ ta kété sí ni? A ò lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ìdí ni pé Bíbélì ò sọ ìlànà kan pàtó tá a gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé lórí irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀.a Ohun kan tó dájú ni pé, èròjà ẹ̀jẹ̀ táwọn kan fi tọrẹ ni wọ́n ń yà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ tí wọ́n wá fi ń mú irú àwọn oògùn bẹ́ẹ̀ jáde. Kristẹni kọ̀ọ̀kan ló máa pinnu ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu bóyá kóun gbà kí wọ́n fi àwọn nǹkan náà ṣètọ́jú òun tàbí kóun má gbà.
Kó o tó ṣe irú ìpinnu yìí, kọ́kọ́ ronú lórí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí: Ǹjẹ́ ó yé mi pé bí mo bá kọ gbogbo àwọn òògùn tó ní àwọn ohun tí wọ́n yọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ látara èròjà ẹ̀jẹ̀, ohun tó túmọ̀ sí ni pé mi ò ní lè lo àwọn oògùn kan bí irú èyí tó ń gbógun ti kòkòrò àrùn àti àìsàn tàbí oògùn amẹ́jẹ̀dì bí ẹ̀jẹ̀ bá ń dà lára èèyàn? Ṣé màá lè ṣàlàyé fún dókítà ìdí tí mi ò fi ní gba irú àwọn oògùn bẹ́ẹ̀? Bí mo bá sì máa gbà á, ṣe màá lè ṣàlàyé ìdí tí mo fi fẹ́ gbà á?
Kí nìdí tó fi jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo máa pinnu ohun tí màá ṣe bó bá di pé dókítà fẹ́ fi ẹ̀jẹ̀ mi tọ́jú mi lọ́nà èyíkéyìí?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Kristẹni kì í fi ẹ̀jẹ̀ tọrẹ, wọn kì í sì í tọ́jú ẹ̀ láti fà á sára bó bá yá, síbẹ̀ àwọn ọ̀nà kan wà tí wọ́n lè gbà lo ẹ̀jẹ̀ ẹni, àwọn àyẹ̀wò kan sì wà tí wọ́n lè fi ẹ̀jẹ̀ ẹni ṣe, èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ ta ko ìlànà Bíbélì. Nítorí náà, olúkúlùkù ló máa ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu bóyá kó fara mọ́ àwọn ọ̀nà kan tí wọ́n fẹ́ gbà fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ tọ́jú rẹ̀ tàbí kó má gbà.
Kó o tó ṣe irú ìpinnu yìí, bi ara ẹ láwọn ìbéèrè yìí: Bó bá ṣẹlẹ̀ pé wọ́n á darí ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ látara mi gba ibòmíràn tó fi jẹ́ pé kò ní lè máa ṣàn nínú ara mi fún àkókò kan, ṣé ẹ̀rí ọkàn mi á ṣì lè jẹ́ kí n ka ẹ̀jẹ̀ yìí sí ẹ̀jẹ̀ mi, èyí tí Bíbélì sọ pé ‘orí ilẹ̀ ni kí n dà á sí’? (Diu. 12:23, 24) Ṣé ẹ̀rí ọkàn mi tí mo ti fi Bíbélì kọ́ ò ní dà mí láàmú bó bá ṣẹlẹ̀ pé lásìkò tí wọ́n ń tọ́jú mi, wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ mi jáde, wọ́n ṣe nǹkan kan sí i, tí wọ́n sì dá a padà sára mi? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yé mi pé bí mo bá ti sọ pé mi ò fara mọ́ ọn pé kí wọ́n fi ẹ̀jẹ̀ mi tọ́jú mi lọ́nà èyíkéyìí, ohun Ató túmọ̀ sí ni pé mi ò ní gba àwọn ìtọ́jú ìṣègùn bíi fífọ ẹ̀jẹ̀ tàbí lílo ẹ̀rọ tó ń tú ẹ̀jẹ̀ jáde sínú ara níbi tí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn tí máa ráàyè wọnú ẹ̀? Ṣé mo tiẹ̀ ti fi ọ̀rọ̀ yìí sádùúrà kí n tó ṣe ìpinnu yìí?b
Àwọn ìpinnu wo ni mo gbọ́dọ̀ ṣe?
Gbé ìwé ìbéèrè méjì yìí yẹ̀ wò ná? Ìwé Ìbéèrè 1 to àwọn ohun kan tí wọn yọ sọ́tọ̀ọ̀tọ̀ látara èròjà ẹ̀jẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ, ó sì sọ báwọn onímọ̀ ìṣègùn ṣe sábà máa ń lò wọ́n. Pinnu bóyá wàá gba èyíkéyìí lára wọn kó o sì ṣe àmì sórí ìlà tó wà níbẹ̀ láti fi hàn bóyá o fẹ́, bóyá o lè fẹ́ tàbí o kò fẹ́. Ìwé Ìbéèrè 2 to àwọn ọ̀nà kan tó wọ́pọ̀ tí wọ́n lè gbà fi ẹ̀jẹ̀ rẹ tọ́jú rẹ lẹ́sẹẹsẹ. Pinnu bóyá wàá fẹ́ èyíkéyìí lára wọn kó o sì ṣe àmì sórí ìlà tó wà níbẹ̀ láti fi hàn bóyá o fẹ́, bóyá o lè fẹ́ tàbí o kò fẹ́. Àwọn ìwé ìbéèrè yìí kì í ṣe èyí tó lọ́wọ́ ọ̀rọ̀ òfin nínú, ṣùgbọ́n o lè lo ìdáhùn tó o kọ sórí àwọn ìwé náà nígbà tó o bá ń kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù DPA, ìyẹn fọ́ọ̀mù tá a fi ń fa àṣẹ ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn lé aṣojú ẹni lọ́wọ́.
Ìpinnu tíwọ fúnra ẹ ní láti ṣe ni, ẹlòmíì ò gbọ́dọ̀ bá ẹ ṣe é. Bákan náà, kẹ́nikẹ́ni má ṣe yiiri ìpinnu tí Kristẹni kan bá ṣe wò. Lórí ọ̀rọ̀ yìí, “olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”—Gál. 6:4, 5.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ìṣọfúnni síwáju sí i lórí kókó yìí wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 29 sí 31.
b Ìsọfúnni síwájú sí i lórí kókó yìí wà nínú Ilé Ìṣọ́ October 15, 2000, ojú ìwé 30 àti 31 àti nínú àwo DVD náà, Transfusion Alternatives—Documentary Series—On DVD.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 5]
ÌWÉ ÌBÉÈRÈ 1
ÈYÍ TÁWỌN ÌPINNU RẸ
KRISTẸNI KÌ Í GBÀ
Ẹ̀JẸ̀ ÀWỌN OÒGÙN TÓ NÍ Ìpinnu Tó O
ÈRÒJÀ Ẹ̀JẸ̀ NÍNÚ Gbọ́dọ̀ Ṣe
OMI INÚ Ẹ̀JẸ̀ ALBUMIN—Ó NÍ TÓ ÌDÁ MẸ́RIN
NÍNÚ ỌGỌ́RÙN-ÚN OMI INÚ Ẹ̀JẸ̀
Ó jẹ́ purotéènì kan tí wọ́n
yọ látinú omi inú ẹ̀jẹ̀. A
tún lè rí oríṣi èròjà inú ․․ Mo fẹ́ albumin
ẹ̀jẹ̀ yìí nínú ewéko, nínú tàbí
àwọn nǹkan bíi mílíìkì àti ․․ Mi ò fẹ́ albumin
ẹyin, ó sì tún wà nínú ọmú
abiyamọ tó ń tọ́mọ lọ́wọ́.
Nígbà míì, wọ́n máa ń fi díẹ̀
lára èròjà omi inú ẹ̀jẹ̀ yìí
sínú ohun tó máa ń mú kí
ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i nínú ara, èyí
tí wọ́n máa fi ń wo ẹni tó bá
dá kú tàbí ẹni tó jóná kọjá
ààlà. Bá a bá pín àwọn èròjà
tí wọ́n fi ṣe irú oògùn yìí
sọ́nà mẹ́rin, èyí tó wá látinú
omi inú ẹ̀jẹ̀ á kó tó ìdá kan.
Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìwọ̀n ṣíún báyìí
lára èròjà inú ẹ̀jẹ̀ yìí ni wọ́n
máa ń fi sínú ọ̀pọ̀ oògùn míì.
Lára irú oògùn bẹ́ẹ̀ ni irú
oògùn erythropoietin (EPO),
ìyẹn oògùn kan tó máa ń mú kí
sẹ́ẹ̀lì pupa ṣiṣẹ́ dáadáa.
IMMUNOGLOBULIN—Ó NÍ TÓ ÌDÁ
MẸ́TA NÍNÚ ỌGỌ́RÙN-ÚN OMI INÚ Ẹ̀JẸ̀
Èyí jẹ́ ohun kan tí wọ́n yọ
látinú purotéènì, tí wọ́n lè
lò láti fi gbógun ti kòkòrò
àrùn àtàwọn àrùn bíi ․․ Mo fẹ́
gbọ̀fungbọ̀fun, ipá, mẹ́dọ̀wú immunoglobulin
àti àrùn tó máa ń ṣe ẹni tí tàbí
ẹranko bá bù jẹ. Wọ́n tún lè ․․ Mi ò fẹ́
lo irú oògùn yìí láti dènà immunoglobulin
àwọn àìlera kan tó lè wu
ẹ̀mí ọmọ inú oyún léwu, wọ́n
sì lè lò ó láti pa oró ejò
tàbí ti aláǹtakùn.
ÀWỌN OÒGÙN AMẸ́JẸ̀DÌ—KÒ NÍ TÓ ÌDÁ
KAN NÍNÚ ỌGỌ́RÙN-ÚN OMI INÚ Ẹ̀JẸ̀
Onírúurú purotéènì ló wà tó
máa ń mú kí ẹ̀jẹ̀ dì bó bá ṣẹlẹ̀
pé ẹ̀jẹ̀ ń dà. Wọ́n máa ń lo
àwọn kan lára oògùn amẹ́jẹ̀dì ․․ Mo fẹ́ àwọn oògùn
yìí fáwọn èèyàn tó jẹ́ pé kí amẹ́jẹ̀dì tí wọ́n
nǹkan kékeré tóó ṣe wọ́n, ẹ̀jẹ̀ fi èròjà ẹ̀jẹ̀ ṣe
á ti máa dà lára wọn. Wọ́n tún tàbí
máa ń lò ó gẹ́gẹ́ bí oògùn láti ․․ Mi ò fẹ́ àwọn
lẹ ojú ọgbẹ́ àti láti dá ẹ̀jẹ̀ oògùn amẹ́jẹ̀dì tí
tó bá ń ya lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ. wọ́n fi èròjà ẹ̀jẹ̀
Ọ̀kan lára irú àwọn oògùn ṣe
amẹ́jẹ̀dì bẹ́ẹ̀ ni cryoprecipitate.
Àkíyèsí: Àwọn oògùn amẹ́jẹ̀dì
kan ti wà báyìí tí kò ní ẹ̀jẹ̀
nínú.
SẸ́Ẹ̀LÌ PUPA HEMOGLOBIN—BÁ A BÁ DÁ SẸ́Ẹ̀LÌ
PUPA SỌ́NÀ MẸ́TA, Ó NÍ TÓ ÌDÁ KAN
Èyí jẹ́ purotéènì tó ń gbé
afẹ́fẹ́ ọ́síjìn káàkiri inú
ara tó sì ń gbé afẹ́fẹ́ carbon ․․ Mo fẹ́ hemoglobin
dioxide lọ sínú ẹ̀dọ̀fóró. Wọ́n tàbí
máa ń fi hemoglobin tí wọ́n bá ․․ Mi ò fẹ́
mú látara èèyàn tàbí ara hemoglobin
ẹranko ṣe oògùn tó lè wo ẹni
tí ẹ̀jẹ̀ bá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán lára rẹ̀.
HEMIN—Ó NÍ TÓ ÌDÁ MÉJÌ NÍNÚ
ỌGỌ́RÙN-ÙN SẸ́Ẹ̀LÌ PUPA
Èyí jẹ́ ohun kan tí wọ́n máa
ń yọ látinú hemoglobin,
tó máa ń ṣèdíwọ́ fún
ohunkóhun tó bá fẹ́ ṣàkóbá
fún ara, wọ́n sì máa ń lò ó ․․ Mo fẹ́ hemin
láti fi wo àwọn àìlera kan tàbí
tí kò wọ́pọ̀ tó máa ń wà nínú ․․ Mi ò fẹ́ hemin
ẹ̀jẹ̀, tí kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ gbé
ìdọ̀tí ara kúrò. Àwọn àìlera
náà sábà máa ń ṣèdíwọ́ fún
bí oúnjẹ ṣe ń dà, bí ọpọlọ
ṣe ń ṣiṣẹ́ àti bí ẹ̀jẹ̀ ṣe ń
ṣàn káàkiri ara.
SẸ́Ẹ̀LÌ FUNFUN INTERFERON—SẸ́Ẹ̀LÌ FUNFUN ṢÍÚN
LÓ WÀ NÍNÚ Ẹ̀
Èyí jẹ́ purotéènì tó máa ń
gbógun ti àrùn tí kòkòrò máa ․․ Mo fẹ́ interferon
ń fà àti àrùn jẹjẹrẹ. Ọ̀pọ̀ tí wọ́n mú jáde
oògùn interferon ni ò ní látinú ẹ̀jẹ̀
èròjà tó tinú ẹ̀jẹ̀ wá. Àwọn tàbí
kan lára ẹ̀ ní èròjà tó tinú ․․ Mi ò fẹ́
sẹ́ẹ̀lì funfun inú ẹ̀jẹ̀ interferon tí
èèyàn wà. wọ́n mú jáde
látinú ẹ̀jẹ̀
SẸ́Ẹ̀LÌ AMẸ́JẸ̀DÌ Títí di báyìí, a ò tíì rí èròjà
kankan tó ṣeé tọ́jú àìlera fà yọ
látinú sẹ́ẹ̀lì amẹ́jẹ̀dì.
[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 6]
ÌWÉ ÌBÉÈRÈ 2
ÌPINNU RẸ
ONÍRÚURÚ Ọ̀NÀ TÁWỌN DÓKÍTÀ LÈ GBÀ FI Ẹ̀JẸ̀ RẸ TỌ́JÚ RẸ
*Àkíyèsí: Bí dókítà kan ṣe ń lo ẹ̀jẹ̀ nígbà tó bá ń tọ́jú aláìsàn yàtọ̀ sí ti dókítà míì. Bí dókítà bá fẹ́ lo èyíkéyìí lára onírúurú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà fi ẹ̀jẹ̀ tọ́jú aláìsàn fún ọ, ní kó ṣàlàyé gbogbo ohun tó wé mọ́ ọn kó o bàa lè mọ̀ bóyá irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀ bá ìlànà Bíbélì mu tí kò sì yàtọ̀ sí ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ mu.
ORÚKỌ ÌTỌ́JÚ OHUN TÓ WÀ FÚN Ìpinnu Tó O Gbọ́dọ̀ Ṣe
(O lè bá dókítà rẹ
sọ̀rọ̀ kó o tó fara mọ́
èyíkéyìí lára
onírúurú ọ̀nà tí
wọ́n lè gbà fi ẹ̀jẹ̀ rẹ
tọ́jú rẹ tàbí kó o tó
sọ pé o ò fara mọ́ ọn.)
GBÍGBE Ẹ̀JẸ̀ Kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tó máa
[CELL SALVAGE] dà nù pọ̀. Wọ́n máa ń gbe
ẹ̀jẹ̀ tó bá dà nù látojú
ọgbẹ́ tàbí nínú ara nígbà
tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ abẹ. ․․ Mo fẹ́
Wọ́n á fọ̀ ọ́ tàbí kí wọ́n ․․ Mo lè fẹ́*
sẹ́ ẹ, wọ́n á wá dà á padà ․․ Mi ò fẹ́
sínú ara aláìsàn náà lójú
ẹsẹ̀ tàbí lẹ́yìn náà.
DÍDA OÒGÙN PỌ̀ Kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tó máa dà
MỌ́ Ẹ̀JẸ̀ nù pọ̀. Bí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́
[HEMODILUTION] abẹ lọ́wọ́, wọ́n máa ń darí
ẹ̀jẹ̀ gba inú àwọn báàgì kan ․․ Mo fẹ́
lọ, wọ́n á wá fi oògùn kan ․․ Mo lè fẹ́*
tó ń mú kí ẹ̀jẹ̀ pọ̀ sí i, àmọ́ ․․ Mi ò fẹ́
tí kò ní ẹ̀jẹ̀ nínú, ìyẹn
nonblood volume expander,
rọ́pò rẹ̀. Bí wọ́n bá ti darí
ẹ̀jẹ̀ gba inú àwọn báàgì yẹn
lọ báyìí lásìkò iṣẹ́ abẹ,
ohun tó kù sínú ẹ̀jẹ̀ onítọ̀hún
kò ní jẹ́ ògidì ẹ̀jẹ̀ mọ́,
ìwọ̀nba ni sẹ́ẹ̀lì pupa tó máa
ṣẹ́ kù sónítọ̀hún lára. Lásìkò
tí wọ́n bá ṣì ń ṣiṣẹ́ abẹ náà
lọ́wọ́ tàbí lẹ́yìn tí wọ́n bá ti
ṣe é tán, wọ́n á dá ẹ̀jẹ̀ tó wà
nínú àwọn báàgì náà padà
sára ẹni náà.
Ẹ̀RỌ TÓ LÈ ṢIṢẸ́ Kì í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ ṣíwọ́ ṣíṣàn
ỌKÀN ÀTI Ẹ̀DỌ̀FÓRÓ káàkiri ara. Wọ́n á darí ẹ̀jẹ̀
gba inú ẹ̀rọ tó ń fa ẹ̀jẹ̀ jáde ․․ Mo fẹ́
táá sì jẹ́ kí afẹ́fẹ́ ọ́síjìn ․․ Mo lè fẹ́*
wọnú rẹ̀ táá tún wá dá a padà ․․ Mi ò fẹ́
sára ẹni náà.
Ẹ̀RỌ̀ TÓ Ń SẸ́ Ẹ̀JẸ̀ Bí ẹ̀yà ara ló ṣe máa ń ṣiṣẹ́.
[DIALYSIS] Wọ́n máa ń jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ máa ṣàn ․․ Mo fẹ́
yíká nínú ẹ̀rọ̀ kan tó máa ń ․․ Mo lè fẹ́*
sẹ́ ẹ̀jẹ̀ títí tó fi máa mọ́ kó ․․ Mi ò fẹ́
tó dà á padà sára ẹni náà.
GÍGÚN IBI TÓ Ń Òun ni wọ́n fi máa ń dí ojú
JÒ LÁBẸ́RẸ́ ibi tó ń jò nínú òpó tó gba
[EPIDURAL inú eegun ẹ̀yìn kọjá lọ sínú
BLOOD PATCH] ọpọlọ. Wọ́n á fa ẹ̀jẹ̀ ṣíún
látara ẹni náà sínú abẹ́rẹ́, ․․ Mo fẹ́
wọ́n á sì gún àyíká ibi tí ․․ Mo lè fẹ́*
èròjà olómi náà wà ní abẹ́rẹ́ ․․ Mi ò fẹ́
náà. Òun ni wọ́n máa ń fi dí
ojú ihò tí omi inú òpó
ẹ̀yìn bá ti ń jò.
LÍLO OMI INÚ Ẹ̀JẸ̀ Wọ́n máa fi ń wo àìsàn. Wọ́n á
[PLASMAPHERESIS] fa ẹ̀jẹ̀, wọ́n á sẹ́ ẹ láti rí i
pé kò sí omi inú ẹ̀jẹ̀ kankan
nínú ẹ̀. Wọ́n á fi nǹkan míì ․․ Mo fẹ́
tó lè rọ́pò omi inú ẹ̀jẹ̀ sí i ․․ Mo lè fẹ́*
kí wọ́n tó dá a padà sára ẹni ․․ Mi ò fẹ́
náà. Àwọn dókítà míì lè fẹ́
lo omi inú ẹ̀jẹ̀ ẹlòmíì láti fi
rọ́pò èyí tó wà nínú ẹ̀jẹ̀
aláìsàn náà. Bó bá rí bẹ́ẹ̀,
a jẹ́ pé kì í ṣe irú èyí tí
Kristẹni lè gbà.
TÍTÚ Ẹ̀JẸ̀ TÍ WỌ́N Wọ́n máa ń fi mọ irú àìlera
SÀMÌ SÍ DÀ SÁRA tẹ́nì kan ní, wọ́n sì tún máa
KÍ Ẹ̀RỌ TÓ Ń fi ń wo àìsàn. Wọ́n á fa ẹ̀jẹ̀
ṢÀWÁRÍ ÀRÙN LÈ díẹ̀, wọ́n á pò ó pọ̀ mọ́ oògùn ․․ Mo fẹ́
LÒ Ó LÁTI FI DÁ kí wọ́n tó dá a padà sára ẹni ․․ Mo lè fẹ́*
ÀÌSÀN MỌ̀ náà. Àkókò tí ẹ̀jẹ̀ náà máa ń ․․ Mi ò fẹ́
lò níta kí wọ́n tó dá a padà
máa ń pẹ́ jura lọ.
GÍRÍSÌ AMẸ́JẸ̀DÌ Wọ́n máa ń fi dí ojú ọgbẹ́, kì
TÍ WỌ́N MÚ JÁDE í jẹ́ kí ẹ̀jẹ̀ tó máa dà nù pọ̀.
LÁTINÚ Ẹ̀JẸ̀ TÌẸ Wọ́n á fa ẹ̀jẹ̀ díẹ̀, wọ́n á wá
FÚNRA Ẹ [PLATELET pò ó mọ́ èròjà tí sẹ́ẹ̀lì ․․ Mo fẹ́
GEL; AUTOLOGOUS] amẹ́jẹ̀dì àti sẹ́ẹ̀lì funfun pọ̀ ․․ Mo lè fẹ́*
nínú ẹ̀. Wọ́n máa ń fi àpòpọ̀ ․․ Mi ò fẹ́
yìí sójú ibi tí wọ́n fi abẹ là
lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ tàbí sójú ọgbẹ́.
Àkíyèsí: Ní ti àwọn egbòogi
míì, ẹ̀jẹ̀ màlúù ni wọ́n máa
ń fi ṣe ohun tó ń mú ẹ̀jẹ̀ dì.