ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 1/11 ojú ìwé 2
  • Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2009
  • Irú Ìtọ́jú Ìṣègùn Wo Ló Dára Jù?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2007
  • Má Fi Falẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2010
  • Má Fi Falẹ̀!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2008
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2011
km 1/11 ojú ìwé 2

Ṣó O Mọ Èyí Tó Yẹ Kó O Yàn?

Wọ́n ti túbọ̀ ń tọ́jú àwọn èèyàn láìlò ẹ̀jẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilé ìwòsàn kárí ayé báyìí. Ṣé o mọ oríṣiríṣi ọ̀nà ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la gbígba ẹ̀jẹ̀ lọ tó wà báyìí dáadáa? Ó yẹ bẹ́ẹ̀ o, torí èyí á jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó jíire tó bá dọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn àti iṣẹ́ abẹ. Wo fídíò náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge. Bó o bá ti wò ó tán, gbàdúrà, kó o sì ṣàyẹ̀wò ohun tó o kọ́ níbẹ̀, kó o wá dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí.—Àkíyèsí: Torí pé fídíò náà ní àwọn ibi kọ̀ọ̀kan tí wọ́n ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ṣókí, kí àwọn òbí lo ìfòyemọ̀ láti pinnu bóyá kí àwọn wò ó pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn kéékèèké.

(1) Kí ni olórí ìdí táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gba ẹ̀jẹ̀? (2) Bó bá dọ̀rọ̀ ìtọ́jú ìṣègùn, kí làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́? (3) Ẹ̀tọ́ wo làwọn aláìsàn ní? (4) Kí nìdí tó fi bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn gba ìtọ́jú tí kò la gbígba ẹ̀jẹ̀ lọ, báwo nìyẹn sì ṣe fi hàn pé èèyàn kò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ọ̀ràn ìlera rẹ̀? (5) Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ̀jẹ̀ ń dà lára aláìsàn láìdáwọ́ dúró, nǹkan méjì wo làwọn dókítà gbọ́dọ̀ ṣe ní kíákíá? (6) Ìlànà mẹ́rin wo làwọn dókítà ní láti tẹ̀ lé bí wọ́n bá fẹ́ tọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀? (7) Báwo làwọn dókítà ṣe lè ṣe é (a) tí ẹ̀jẹ̀ tó máa dà lára aláìsàn ò fi ní pọ̀ jù, (b) tí wọ́n á fi lè rí i pé sẹ́ẹ̀lì pupa ò ṣòfò, (d) tí ẹ̀jẹ̀ tára ń mú jáde á fi pọ̀ sí i, (e) tí ẹ̀jẹ̀ ara aláìsàn á fi tó pa dà? (8) Ṣàlàyé ọ̀nà táwọn dókítà lè gbà fi ẹ̀jẹ̀ rẹ tọ́jú rẹ, bíi (a) dída oògùn pọ̀ mọ́ ẹ̀jẹ̀ àti (b) fífi ẹ̀rọ gbe ẹ̀jẹ̀. (9) Kí ló yẹ kó o mọ̀ nípa ìtọ́jú ìṣègùn tí kò la gbígba ẹ̀jẹ̀ lo? (10) Ṣé iṣẹ́ abẹ tó gbẹgẹ́ tó sì díjú ṣeé ṣe láìjẹ́ pé wọ́n fa ẹ̀jẹ̀ síni lára? (11) Àyípadà rere wo ló ń ṣẹlẹ̀ lágbo àwọn oníṣègùn báyìí?

Bí ẹnì kan bá máa yan èyíkéyìí lára àwọn ọ̀nà ìtọ́jú tá a fi hàn nínú fídíò yìí, ìyẹn á jẹ́ ìpinnu ara rẹ̀ níbàámu pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tó ti fi Bíbélì kọ́. Ṣó o ti pinnu irú ìtọ́jú tí ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ máa gbà àti bó o ṣe fẹ́ kí wọ́n ṣe é? Ṣó o sì ti kọ ọ̀rọ̀ tó yẹ sínú káàdì DPA rẹ? Fún àlàyé kíkún lórí ọ̀rọ̀ yìí, fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004 àti October 15, 2000. Kó o wá lo ìwé ìbéèrè tó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti December 2006 tó ní àkòrí náà, “Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?,” láti ṣe àwọn ìpinnu lórí irú ìtọ́jú tó o fẹ́ tàbí èyí tí o kò fẹ́. Paríparí rẹ̀, rí i dájú pé o kọ ọ̀rọ̀ tó péye nípa ìtọ́jú tó o fẹ́ sínú káàdì DPA rẹ. Jẹ́ kí ẹni tó o bá yàn láti jẹ́ aṣojú rẹ lórí ọ̀ràn ìtọ́jú ìṣègùn àti àwọn ẹbí rẹ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí ní òye kíkún nípa àwọn ìpinnu rẹ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́