Wo Fídíò Náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge, Kó O sì Jàǹfààní Rẹ̀
Báwo ni ìmọ̀ rẹ ṣe tó nípa oríṣiríṣi ọ̀nà tó ti wà lágbo ìmọ̀ ìṣègùn báyìí fún ṣíṣe ìtọ́jú aláìsàn láìlo ẹ̀jẹ̀? Ǹjẹ́ o mọ díẹ̀ lára àwọn ìtọ́jú tí àwọn oníṣègùn lè fúnni láìlo ẹ̀jẹ̀ yìí àti bí wọ́n ṣe ń lò wọ́n? Wo fídíò yìí, kó o wá fi àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e yìí yẹ ìmọ̀ rẹ wò.—Àkíyèsí: Nítorí pé àwọn ibì kan wà nínú fídíò yìí tá a ti fi iṣẹ́ abẹ hàn ní ráńpẹ́, kí àwọn òbí rò ó dáadáa bóyá ó yẹ kí àwọn ọmọ wọn kéékèèké wò ó tàbí kò yẹ kí wọ́n wò ó.
(1) Ìdí pàtàkì wo làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í fi í gbẹ̀jẹ̀, ibo ni ìlànà yẹn sì wà nínú Bíbélì? (2) Tá a bá fẹ́ gbàtọ́jú, irú ìtọ́jú wo la máa ń fẹ́? (3) Ẹ̀tọ́ wo ni ẹni tó ń gba ìtọ́jú ní? (4) Téèyàn bá lóun ò gbẹ̀jẹ̀, kí nìdí tí èyí fi tọ̀nà tó sì bọ́gbọ́n mu? (5) Tí ẹ̀jẹ̀ bá ti dà púpọ̀ jù lára èèyàn, ohun méjì wo ló ṣe pàtàkì kí dókítà kọ́kọ́ ṣe? (6) Àwọn ewu wo ló wà nínú gbígba ẹ̀jẹ̀ sára? (7) Àwọn nǹkan wo làwọn dókítà oníṣẹ́ abẹ lè lò kí ẹ̀jẹ̀ má bàa fi bẹ́ẹ̀ ṣòfò nígbà iṣẹ́ abẹ? (8) Tí wọ́n bá fẹ́ fún ẹ ní oògùn àfidípò ẹ̀jẹ̀, ìwádìí wo ló yẹ kó o ṣe nípa rẹ̀? (9) Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe láti ṣe àwọn iṣẹ́ abẹ tó le tó sì díjú gan-an láìfa ẹ̀jẹ̀ sí ẹni tó ń gbàtọ́jú lára? (10) Kí ni àwọn oníṣègùn tó ń pọ̀ sí i ń fẹ́ láti ṣe fún àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí ló sì ṣeé ṣe kó kúkú di ìlànà táwọn oníṣègùn á máa lò láti fi tọ́jú gbogbo aláìsàn?
Ẹnì kọ̀ọ̀kan ni yóò ṣe ìpinnu tó bá ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mu nípa bóyá òun á gba èyíkéyìí lára irú àwọn ìtọ́jú tá a fi hàn nínú fídíò yìí tàbí òun ò ní gbà á.—Wo Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 22 sí 24, àti 29 sí 31, àti Ilé Ìṣọ́ October 15, 2000, ojú ìwé 30 àti 31.