ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 12/04 ojú ìwé 2
  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 27
  • Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 3
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2004
km 12/04 ojú ìwé 2

Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 13

Orin 47

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ àtàwọn Ìfilọ̀ tí a mú látinú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìlàjì oṣù December sílẹ̀. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n wo fídíò náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge, láti fi múra sílẹ̀ fún ìjíròrò tí yóò wáyé ní Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀. Sọ àwọn ètò àkànṣe tẹ́ ẹ ṣe fún ìjẹ́rìí ní December 25 àti January 1. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé kẹjọ (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ December 15 àti Jí! January 8 lọni. (Àbá kẹta ni ká lò láti fi Jí! January 8 lọni.) A tún lè fi ìwé ìròyìn lọni láwọn ọ̀nà mìíràn tó bá ipò ìpínlẹ̀ ìjọ mu. Nínú àṣefihàn kọ̀ọ̀kan, jẹ́ káwọn ará mọ ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a lè gbà fèsì ọ̀rọ̀ kan táwọn èèyàn fi ń dínà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀, ìyẹn ‘Mo mọ̀ nípa iṣẹ́ yín dáadáa.’—Wo ìwé kékeré náà, Bí A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Awọn Ìjíròrò Bibeli Kí A Sì Máa Báa Nìṣó, ojú ìwé 12.

15 min: “Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́—Ilẹ̀kùn Ńlá Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Ìgbòkègbodò.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Mẹ́nu kan ohun tó wà nínú ìwé ọdọọdún wa 2004 Yearbook, ojú ìwé 239 àti 240. Sọ fún àwọn ará pé ní àpéjọ àyíká, a máa ń ṣe ìpàdé kan pẹ̀lú àwọn tó bá fẹ́ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́. Rọ àwọn tó bá kúnjú òṣùwọ̀n láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ yìí pé kí wọ́n wà níbi ìpàdé yìí.

20 min: “Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Wàásù fún Àwọn Mọ̀lẹ́bí Wa?”a Lo àwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ. Sọ pé kí àwùjọ sọ ọ̀rọ̀ ṣókí nípa bí wọ́n ṣe sọ ohun tó mú kí àwọn mọ̀lẹ́bí wọn fẹ́ gbọ́ ìhìn rere, tí èyí sì fún wọn láǹfààní láti wàásù fún wọn.

Orin 17 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 20

Orin 68

5 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ.

15 min: “Ọ̀nà Tuntun Tí A Ó Máa Gbà Ṣe Àtúnyẹ̀wò Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Àyíká àti Àkànṣe.” Àsọyé àti ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ tá a gbé ka àpilẹ̀kọ tó wà lójú ìwé kẹrin. Sọ ọjọ́ tí ìjọ yín máa lọ sí àpéjọ àyíká àti àpéjọ àkànṣe tó ń bọ̀, bí ẹ bá ti mọ ọjọ́ náà. Kí àwọn tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi tètè sọ fún alábòójútó olùṣalága ṣáájú àkókò.

25 min: “Wo Fídíò Náà, No Blood—Medicine Meets the Challenge Kó O sì Jàǹfàǹní Rẹ̀.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ lórí fídíò No Blood. Lo àwọn ìbéèrè tó wà lójú ìwé kìíní. Lẹ́yìn èyí, ka ìpínrọ̀ tó gbẹ̀yìn. Rọ gbogbo àwọn ará pé kí wọ́n wá sí ìpàdé lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀, nígbà tá a máa jíròrò nípa ohun kan tí ètò àjọ Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè ta kété sí ẹ̀jẹ̀. Bí kò bá ṣeé ṣe láti jíròrò lórí fídíò yìí, kí alàgbà kan sọ̀rọ̀ lórí kókó náà, Ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run Lórí Ẹ̀jẹ̀. A gbé ọ̀rọ̀ yìí ka àpilẹ̀kọ tó wà nínú Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 19 sí 23, ìpínrọ̀ 1 sí 15.

Orin 50 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní December 27

Orin 36

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Ìròyìn ìnáwó. Rán àwọn akéde létí pé kí wọ́n fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá wọn ti ìparí oṣù December sílẹ̀. Lo àbá tó wà ní ojú ìwé kẹjọ (bó bá ṣeé lò ní ìpínlẹ̀ ìjọ yín) láti fi ṣe àṣefihàn bá a ṣe lè fi Ilé Ìṣọ́ January 1 àti Jí! January 8 lọni. (Àbá kẹrin ni ká lò láti fi Jí! January 8 lọni.)

25 min: Bí A Ṣe Lè Pa Àṣẹ Ọlọ́run Pé Ká Ta Kété sí Ẹ̀jẹ̀ Mọ́. Alàgbà ni kó sọ ọ̀rọ̀ yìí, kó lo ìwé àsọyé tí a ó fi ránṣẹ́ láti ẹ̀ka ọ́fíìsì. Láti ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni kó ti sọ fún àwọn ará pé kì í ṣe alẹ́ yìí la máa kọ àwọn ohun tó yẹ sínú káàdì DPA. Nígbà tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ń ka ohun tó wà nínú ìwé àsọyé yìí, ó lè sọ ọ̀rọ̀ ṣókí láti tẹnu mọ́ àwọn kókó pàtàkì, àmọ́ kó má ṣe lo àwọn àpẹẹrẹ tàbí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn láfikún sí ohun tó wà nínú ìwé àsọyé. Ó lè ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí a ò kọ ọ̀rọ̀ inú wọn sínú ìwé àsọyé tàbí kó fa ọ̀rọ̀ inú wọn yọ bí àkókò bá ṣe wà sí. Ní àwọn ibi tó bá ti yẹ bẹ́ẹ̀, kó tọ́ka sí àwọn ohun tó wà nínú àpótí náà, “Ohun Tuntun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Ta Kété sí Ẹ̀jẹ̀.” Kí akọ̀wé ìjọ fún gbogbo àwọn akéde tí wọ́n ti ṣèrìbọmi ní káàdì DPA àti ìwé tó ní àkọlé yìí, “Ìtọ́ni Nípa Bí A Ṣe Máa Kọ Nǹkan Sínú Káàdì DPA” kí wọ́n lè máa fojú bá a lọ tí olùbánisọ̀rọ̀ bá ń sọ̀rọ̀. Bákan náà, kí akọ̀wé rí i dájú pé àwọn káàdì Identity Card tó pọ̀ tó wà.

10 min: Ipa Tí Ẹ̀rí Ọkàn Rẹ Ń Kó. Kí alàgbà sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, èyí tá a gbé ka Ilé Ìṣọ́ June 15, 2004, ojú ìwé 23 àti 24, ìpínrọ̀ 16 sí 19. Tẹnu mọ́ ọn pé, àwọn ìpinnu tá a ní láti ṣe lórí ọ̀ràn tó bá jẹ́ ti ẹ̀rí ọkàn ṣe pàtàkì gidigidi nítorí pé wọ́n kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà.

Orin 8 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tó Bẹ̀rẹ̀ ní January 3

Orin 27

10 min: Àwọn ìfilọ̀ ìjọ. Sọ ìwé tí a óò fi lọni lóṣù January.

15 min: Àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ.

20 min: “Bí A Ṣe Lè Darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Yóò Máa Tẹ̀ Síwájú—Apá Kẹrin.” Lẹ́yìn ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí kò tó ìṣẹ́jú kan tí a gbé ka ìpínrọ̀ kìíní, jẹ́ kí a ṣe àṣefihàn oníṣẹ̀ẹ́jú márùn-ún tí a gbé ka ìpínrọ̀ kejì àti ìkẹta, kí àwọn ará lè rí bí akéde kan ṣe ń kọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ bó ṣe lè múra ìkẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀. Kí àwọn tó máa ṣe àṣefihàn náà lo ìpínrọ̀ kan nínú ìwé Ìmọ̀ tàbí ìwé pẹlẹbẹ Béèrè. Lẹ́yìn èyí, lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti bójú tó ìpínrọ̀ kejì sí ìkarùn-ún, kó o sì sọ àwọn kókó pàtàkì tó wà nínú àṣefihàn náà.

Orin 79 àti àdúrà ìparí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Má ṣe jẹ́ kí ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ìṣẹ́jú kan, kí o wá lo ìbéèrè àti ìdáhùn láti fi bójú tó ìjíròrò náà.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́