Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Akéde Ìjọba Náà?
1 Inú gbogbo wa ló dùn nígbà táa gbọ́ pé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní iye akéde tó pọ̀ ju ti ìgbàkígbà rí lọ ní oṣù September 1999, tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba ó lé mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti mọ́kàndínlógójì (226,539). Ó dájú pé ìsapá àjùmọ̀ṣe ni, pẹ̀lú ìmúratán la sì fi ṣe é! Ẹ̀rí fi hàn pé láwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, ló ti ń ṣòro fáwọn akéde kan láti jẹ́ akéde Ìjọba náà tó ń ṣe déédéé, nítorí pé láti ìgbà yẹn wá, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà okòólérúgba, irínwó àti mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [220,497] akéde ló ń ròyìn lóṣooṣù ní ìpíndọ́gba. Èyí fi hàn pé ọ̀kan nínú akéde mẹ́rìndínlógójì ni kì í kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù. A gbà gbọ́ pé ọ̀rọ̀ ìṣírí tí yóò tẹ̀ lé e yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti yanjú ọ̀ràn yìí.
2 Mọrírì Àǹfààní Náà: Ó yẹ kí ìmọrírì wa jinlẹ̀ fún àǹfààní táa ní láti máa jíhìn rere náà fún àwọn ẹlòmíràn. Iṣẹ́ yìí máa ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀, ó sì ń ran àwọn aláìlábòsí ọkàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà ìyè. (Òwe 27:11; 1 Tím. 4:16) Jíjẹ́rìí déédéé ń mú ká túbọ̀ nírìírí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, ó sì máa ń mú ká láyọ̀, kí inú wa sì dùn pé a ń ṣàṣeyọrí.
3 Ròyìn Iṣẹ́ Tóo Ṣe: Báwọn kan bá ti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, wọn kì í ròyìn iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lásìkò. Ká má ṣe rò pé iṣẹ́ tí a ṣe kò tóhun téèyàn ń ròyìn. (Fi wé Máàkù 12:41-44.) Ká má ṣe máa kùnà láti ròyìn iṣẹ́ táa bá ṣe o! Níní ètò gúnmọ́ kan tí a ń tẹ̀ lé nínú ilé, irú bíi lílo kàlẹ́ńdà láti máa fi ṣàkọsílẹ̀ àkókò táa bá lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́, yóò máa rán wa létí nígbà gbogbo pé ká ròyìn lójú ẹsẹ̀ níparí oṣù kọ̀ọ̀kan.
4 Ṣèrànwọ́ Fáwọn Tó Nílò Rẹ̀: A lè mú kí àwọn ètò tí a ṣe nínú ìjọ fún ríran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti lè máa kópa déédéé nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà túbọ̀ sunwọ̀n sí i. Kí akọ̀wé ìjọ àti àwọn Olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣètò kí àwọn akéde tó nírìírí ṣèrànwọ́. Bí o bá ní àwọn ọmọ àti àwọn mìíràn tí o ń bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọn jẹ́ akéde tí kò tíì ṣe batisí, kọ́ wọn láti máa ròyìn iṣẹ́ tí wọ́n bá ṣe lóṣooṣù.
5 Rántí ìtàn ìgbésí ayé tó ní àkọlé náà, “Mo Dúpẹ́ fún Àkókò Gígùn Tí Mo Lò Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà,” tó wà nínú Ilé Ìṣọ́, October 1, 1997. Arábìnrin Ottilie Mydland láti Norway di akéde tí ń wàásù ìhìn rere náà déédéé ṣáájú kó tó ṣe batisí lọ́dún 1921. Lọ́dún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin lẹ́yìn ìgbà yẹn, nígbà tó di ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún, ó wí pé: “Inú mi dùn pé mo ṣì lè jẹ́ akéde tí ó ń ṣe déédéé.” Ìṣarasíhùwà àtàtà tó yẹ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ṣàfarawé lèyí mà jẹ́ o!