ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 8/98 ojú ìwé 1
  • August Yóò Ha Jẹ́ Oṣù Aláìlẹ́gbẹ́ Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • August Yóò Ha Jẹ́ Oṣù Aláìlẹ́gbẹ́ Bí?
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • 215,000!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
  • Ìròyìn Ìṣàkóso Ọlọrun
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1996
  • Ǹjẹ́ O Ń Ṣe Déédéé Gẹ́gẹ́ Bí Akéde Ìjọba Náà?
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2000
  • A Fẹ́ Kí Oṣù August Jẹ́ Mánigbàgbé!
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2014
Àwọn Míì
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1998
km 8/98 ojú ìwé 1

August Yóò Ha Jẹ́ Oṣù Aláìlẹ́gbẹ́ Bí?

1 Ní ọdún 1948 iye àwọn akéde jákèjádò ayé kọjá 226,000. Bí o bá wà nínú òtítọ́ ní àkókò yẹn, o lè rántí bí inú wa ṣe dùn tó láti ní iye àwọn ènìyàn púpọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ń wàásù Ìjọba náà! Nísinsìnyí, iye àwọn akéde tí ó wà ní orílẹ̀-èdè yìí nìkan tó ìyẹn. Àmọ́ ṣá o, ìpíndọ́gba 20,000 nínú wa ni kì í ròyìn kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ lóṣooṣù.

2 Tẹ́wọ́ Gba Ìpèníjà Náà: Ní oṣù August a fẹ́ sakun láti dórí góńgó tí ó ta yọ ju ti ìgbàkigbà rí lọ ti 215,000 akéde ní Nàìjíríà. Bí àwọn ìsapá wa bá yọrí sí rere, August yóò jẹ́ oṣù aláìlẹ́gbẹ́ ní tòótọ́! A lè ṣe é bí gbogbo wa bá ṣe ipa tiwa.

3 Àwọn tí ń wéwèé láti lọ lo àkókò ìsinmi lè lo àkókò díẹ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kí wọ́n tó lọ. Kó àwọn ìwé àṣàrò kúkúrú, ìwé pẹlẹbẹ, tàbí ìwé ìròyìn dání kí o lè jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn tí o bá bá pàdé nígbà tí o bá ń lọ. Bákan náà, níbi tí o ń lọ o lè gbádùn kíkópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú àwọn akéde tí ó wà ní àdúgbò náà.

4 Bí o bá ń ṣàárẹ̀, o ṣì lè kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́. Ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti jẹ́rìí fún àwọn dókítà, nọ́ọ̀sì, tàbí fún àwọn tí ó bá ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ rẹ. Bóyá o lè fi lẹ́tà tàbí tẹlifóònù jẹ́rìí.

5 Láìsí àní-àní àwọn kan yóò mọrírì ìrànlọ́wọ́ tí a bá ṣe fún wọn láti lè kópa nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní August. Kí àwọn alàgbà, ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, àti àwọn olùdarí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ ṣètò láti pèsè ìrànlọ́wọ́ yìí. Dájúdájú, má ṣe gbàgbé láti fi ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá rẹ sílẹ̀ lọ́gán ní ìparí oṣù kí a lè kà ọ́ gẹ́gẹ́ bí akéde ní August.

6 Mọrírì Àǹfààní Náà: Iṣẹ́ òjíṣẹ́ yìí jẹ́ “ohun ìtọ́júpamọ́ àtàtà.” (2 Tím. 1:14) A mọrírì àǹfààní tí a fún wa láti wàásù ìhìn rere náà. (1 Tẹs. 2:4) Bí a bá ronú nípa gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fún wa, ó yẹ kí a sún wa láti máa fìgbà gbogbo kópa nínú iṣẹ́ tí ó ṣe pàtàkì jù lọ yìí jálẹ̀ gbogbo ọdún. Kò sí ohun tí ó yẹ kí a jẹ́ kí ó dí wa lọ́wọ́ láti máa wàásù déédéé. Kí a jẹ́ kí oṣù August yìí jẹ́ oṣù tí ó ta yọ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí a sì pinnu láti máa jẹ́rìí nípa rẹ̀ lóṣooṣù lẹ́yìn náà!—Sm. 34:1.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́