215,000!
Iye àwọn akéde tí a fẹ́ kí ó ròyìn ní Nàìjíríà ní oṣù August 1998 nìyẹn. Ó ha lè ṣeé ṣe fún wa láti dórí iye yẹn bí? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè ṣe bẹ́ẹ̀! Àkọsílẹ̀ tí a ṣe ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí nípa àwọn ìjọ ní Nàìjíríà fi àròpọ̀ iye àwọn akéde tí ó jẹ́ 226,185 hàn. Àmọ́ ṣá o, góńgó tí ó ta yọ ju ti ìgbàkigbà rí lọ tí ó ròyìn ní oṣù kan ṣoṣo èyíkéyìí jẹ́ 207,193, ní April 1998. Báwo ni a ṣe lè kọjá iye tí ó jẹ́ aláìlẹ́gbẹ́ yẹn? A lè ṣe é bí akéde kọ̀ọ̀kan nínú ìjọ bá ṣe àwọn ètò tí ó ṣe gúnmọ́ láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní oṣù August, tí a sì ròyìn ìgbòkègbodò yẹn lọ́gán. Oṣù August ní òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún. Gbìyànjú láti tètè bẹ̀rẹ̀ nínú oṣù, nípa bẹ́ẹ̀ kí o má ṣe kùnà láti lo àkókò díẹ̀ nínú iṣẹ́ ìjẹ́rìí nínú oṣù August. Pẹ̀lú ìsapá wa lápapọ̀, ó yẹ kí a dórí góńgó tí ó ta yọ ju ti ìgbàkigbà rí lọ nínú iye àwọn akéde tí ó kọjá 215,000 fún ìgbà àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà. Ẹ wo irú igbe ìyìn tí ìyẹn yóò jẹ́ sí Jèhófà!—Sm. 47:1.