A Fẹ́ Kí Oṣù August Jẹ́ Mánigbàgbé!
A Máa Pín Ìwé Àṣàrò Kúkúrú Tuntun Kárí Ayé
1. Ìwàásù àkànṣe wo la máa ṣe kárí ayé bá a ṣe ń sún mọ́ ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀?
1 Ọdún yìí ló máa pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí Ọlọ́run ti gbé Ìjọba rẹ̀ kalẹ̀. Torí náà, ó bá a mu wẹ́kú pé ká wàásù lákànṣe láti fògo fún Jèhófà! Lóṣù August a máa pín ìwé àṣàrò kúkúrú tuntun kan kárí ayé, àkòrí rẹ̀ ni, Ibo La Ti Lè Rí Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Pàtàkì Nípa Ìgbésí Ayé? Ìwé àṣàrò kúkúrú yìí fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n ka Bíbélì kí wọ́n lè rí ìdáhún sáwọn ìbéèrè náà, ó sì tún ṣàlàyé bí ìkànnì jw.org ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.
2. Báwo la ṣe lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ará wa láti kígbe ìyìn sí Jèhófà lóṣù August?
2 A Máa Kígbe Ìyìn sí Jèhófà: Kí àwọn akéde lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a ti ṣe àkànṣe ètò kan fún àwọn tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù August. Lóṣù yẹn, àwọn akéde tó ti ṣèrìbọmi tó bá fẹ́ ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lè ròyìn ọgbọ̀n [30] wákàtí. Ó máa rọrùn fáwọn òṣìṣẹ́ tàbí àwọn tó ń lọ sí iléèwé láàárín ọ̀sẹ̀ láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù August torí pé ọjọ́ Friday, Sátidé àti Sunday márùn-ún loṣù yẹn ní. Tí ẹni tí ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí ọmọ rẹ kan bá ti tóótun láti di akéde, tètè sọ fún olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà. Ó dájú pé ó máa fún wa níṣìírí gan-an tí wọ́n bá di akéde, tá a sì jọ kópa nínú àkànṣe ìwàásù yìí. Láwọn ilẹ̀ kan, ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà déédéé ló máa ń fi àkókò ìsinmi wọn sí oṣù August lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ní iye wákàtí tó yẹ kí wọ́n ní lọ́dún. Àmọ́, wọ́n lè ṣe àwọn àyípadà kan kí wọ́n lè kópa kíkún nínú àkànṣe ìwàásù yìí. Ní báyìí, ńṣe ló yẹ káwọn ìdílé jíròrò bí wọ́n ṣe máa dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ará kárí ayé láti kígbe ìyìn sí Jèhófà lóṣù August.—Ẹ́sírà 3:11; Òwe 15:22.
3. Kí la fẹ́ kó ṣẹlẹ̀ nígbà àkànṣe ìwàásù tá a fẹ́ ṣe lóṣù August?
3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ rèé tá a máa pín ìwé lákànṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, a fẹ́ kí tọ̀tẹ̀ yìí jẹ́ mánigbàgbé. Ǹjẹ́ a lè sapá kí iye wákàtí, akéde àti aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ tá a máa ní lóṣù August ju ti ìgbàkígbà rí lọ? Bí ọdún iṣẹ́ ìsìn 2014 ṣe ń parí lọ, ǹjẹ́ kí Jèhófà bù kún ìsapá àwa èèyàn rẹ̀ kárí ayé kí iṣẹ́ ìwàásù tá a máa ṣe lóṣù August lè ju ti ìgbàkígbà rí lọ!—Mát. 24:14.