Ìtòlẹ́sẹẹsẹ fún Ọ̀sẹ̀ June 16
Ọ̀SẸ̀ TÓ BẸ̀RẸ̀ NÍ JUNE 16
Orin 111 àti Àdúrà
Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ:
cl orí 8 ìpínrọ̀ 17 sí 24 àti àpótí tó wà lójú ìwé 86 (30 min.)
Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run:
Bíbélì kíkà: Léfítíkù 6-9 (10 min.)
No. 1: Léfítíkù 8:18-30 (4 min. tàbí kó máà tó bẹ́ẹ̀)
No. 2: Kì Í Ṣe Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Èèyàn Ń Sìn—td 34E (5 min.)
No. 3: Ìdí Tí Kò Fi Yẹ Ká Máa Purọ́—lr orí 22 (5 min.)
Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn:
30 min: “Ẹ Máa Rántí Àwọn Tó Wà Ní Ilé Ìtọ́jú Àwọn Arúgbó.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Tẹ́ ẹ bá ń jíròrò ìpínrọ̀ 4, ṣe àṣefihàn ṣókí kan níbi tí àwọn akéde méjì tó tóótun ti ń bá máníjà ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó sọ̀rọ̀, tí wọ́n sì ń bi í bóyá àwọn lè dá àwùjọ kan sílẹ̀ níbẹ̀ táwọn á máa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, bí kò bá sí ilé ìtọ́jú àwọn arúgbó nítòsí yín, ẹ jíròrò kókó náà “Bá A Ṣe Lè Bọlá fún Àwọn Òbí Wa Tó Ti Dàgbà.” Ẹ gbé e ka ìwé Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, orí 15, ìpínrọ̀ 1 sí 14.
Orin 90 àti Àdúrà