ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 5/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 5
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 5/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún May

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 5

Orin 130

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

12 min: “Máa Tọ Jésù Lẹ́yìn Nígbà Gbogbo.” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn ìrírí láti inú Ilé-Ìṣọ́nà, June 1, 1993, ojú ìwé 12, kún un.

23 min: “Fi Ojúlówó Àníyàn Hàn fún Gbogbo Ọkàn Ìfẹ́ Tí O Bá Rí.” Ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Tẹnu mọ́ àìní náà láti pa dà ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́. Dábàá àwọn ọ̀nà ọgbọ́n tí a lè gbà béèrè àdírẹ́sì ilé àwọn tí a bá bá pàdé ní ìgboro kí a baà lè jẹ́rìí fún wọn síwájú sí i. Jẹ́ kí àwọn akéde dídáńgájíá ṣàṣefihàn méjì nínú àwọn ìgbékalẹ̀ tí a dábàá ní ìpínrọ̀ 6 sí 9. Ṣàtúnyẹ̀wò àpótí náà, “Bí A Ṣe Lè Kẹ́sẹ Járí Nínú Ṣíṣe Ìpadàbẹ̀wò,” ní ojú ìwé 3 nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti March 1997. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti ṣètò àkókò díẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ṣe àwọn ìpadàbẹ̀wò.

Orin 151 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 12

Orin 133

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò, àti àwọn ìṣètò iṣẹ́ ìsìn pápá fún òpin ọ̀sẹ̀.

15 min: Àpótí Ìbéèrè. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan.

20 min: ‘Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997.’ (Ìpínrọ̀ 1 sí 8) Ìgbéyẹ̀wò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn láti ẹnu akọ̀wé. Ka ìpínrọ̀ 3, 5, àti 8. Tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, ti ìtìlẹ́yìn onígbọràn fún ìṣètò ilé gbígbé.

Orin 162 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 19

Orin 139

10 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn ìnáwó.

20 min: “Dídarí Àwọn Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Tí Ń Tẹ̀ Síwájú.” Arákùnrin tí ó dáńgájíá bá akéde kan tàbí méjì, tí wọ́n ń ṣe dáradára nínú dídarí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́, jíròrò àpilẹ̀kọ náà. Ní lílo àwọn apá kan nínú ìwé Ìmọ̀ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, wọ́n ṣàlàyé àwọn ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mú kí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà máa bá a nìṣó lọ́nà tí ó ṣe déédéé, tí ó sì mú kí wọ́n lè fòye mọ ohun tí akẹ́kọ̀ọ́ náà ń kọ́ ní ti gidi.—Wo àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti June 1996, ìpínrọ̀ 5, 8, 12, àti 21.

15 min: ‘Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ìgbàgbọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run” ti 1997.’ (Ìpínrọ̀ 9 sí 14) Ìgbéyẹ̀wò lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn láti ẹnu alàgbà kan tí ó dáńgájíá. Ka ìpínrọ̀ 10.

Orin 165 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní May 26

Orin 148

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ àfilọni fún oṣù June. Ní lílo ìwé Ìmọ̀, ṣàlàyé bí a ṣe lè lo èrò tí ó wà ní ìpínrọ̀ 17 sí 19 ní ojú ìwé 10 àti 11 láti fi múra ìgbékalẹ̀ ṣókí kan sílẹ̀. Fún gbogbo àwùjọ níṣìírí láti pọkàn pọ̀ sórí sísakun láti bẹ̀rẹ̀ àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́. Tẹnu mọ́ àìní náà láti ran àwọn olùfìfẹ́hàn lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú kíákíá.—Wo Ilé-Ìṣọ́nà, January 15, 1996, ojú ìwé 13 àti 14.

12 min: “Èé Ṣe Tí A Fi Ń Pa Dà Lọ Ṣáá?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Fi àwọn kókó tí ó wà nínú àpótí tí ó wà ní ojú ìwé 570 nínú ìwé Proclaimers kún un.

18 min: Àwọn àìní àdúgbò. Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà kan tàbí ìjíròrò láti ẹnu alàgbà méjì tí ó dá lórí àìní ìjọ nípa tẹ̀mí. Fúnni ní ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu, àti àwọn àbá tí ó gbéṣẹ́ fún sísunwọ̀n sí i.

Orin 174 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́