ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/97 ojú ìwé 2
  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
  • Ìsọ̀rí
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 6
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 13
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 20
  • Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 27
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 10/97 ojú ìwé 2

Àwọn Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn Fún October

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 6

Orin 39

10 min: Ìfilọ̀ àdúgbò. Àwọn Ìfilọ̀ tí a yàn láti inú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa.

15 min: “Gbogbo Ènìyàn Yóò Ha Nífẹ̀ẹ́ Ara Wọn Láé Bí?” Ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì láti inú Ìròyìn Ìjọba No. 35. Tọ́ka sí ìdí tí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ìpínlẹ̀ yín yóò fi jàǹfààní láti inú àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ yí. Tẹnu mọ́ ìdí tí ó fi yẹ kí a ṣe ìwéwèé nísinsìnyí láti nípìn-ín ní kíkún nínú pípín in kiri, kí a sì jẹ́ aláápọn ní pípadà ṣiṣẹ́ lórí ìfẹ́ ọkàn tí a rí.

20 min: “Pín Ìròyìn Ìjọba No. 35 Kiri Lọ́nà Gbígbòòrò.” Ọ̀rọ̀ àkọ́sọ láti ẹnu alábòójútó iṣẹ́ ìsìn. Kárí ìpínrọ̀ 5 sí 8 lọ́nà ìbéèrè àti ìdáhùn. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìṣètò tí a ṣe ní àdúgbò fún ìgbòkègbodò tí a mú gbòòrò sí i. Jíròrò àwọn ọ̀nà tí a fi lè rí i dájú pé a kárí gbogbo ìpínlẹ̀. Àwọn akéde lè lo Ìròyìn Ìjọba No. 35 nígbà tí wọ́n bá ń jẹ́rìí fún àwọn ènìyàn ní ibùdókọ̀ bọ́ọ̀sì, nínú ọjà àti ní àwọn ibi iṣẹ́ ajé kéékèèké, ní àwọn ibi ìgbọ́kọ̀sí, nínú ọkọ̀ èrò, àti níbòmíràn. Fúnni ní ìmọ̀ràn lórí bí a ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun tí wọ́n fẹ́ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù lọ́wọ́. Fi ìsọfúnni tí ó wà nínú àkìbọnú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa ti September 1995, ojú ìwé 3, ìpínrọ̀ 9 kún un. Ní àwọn ìpínlẹ̀ kan ó lè ṣàǹfààní láti dá ṣiṣẹ́, kí a má sì gbé àpò nígbà tí a bá ń pín Ìròyìn Ìjọba. Ṣàṣefihàn ìgbékalẹ̀ méjì tàbí mẹ́ta ní ṣókí.

Orin 126 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 13

Orin 41

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn kókó ìbánisọ̀rọ̀ tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ti lọ́ọ́lọ́ọ́. Rán gbogbo àwọn ará létí pé nígbà ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀, àwọn ìwé ìròyìn ni a óò gbé jáde lákànṣe pẹ̀lú Ìròyìn Ìjọba No. 35. Kí a pa dà ṣiṣẹ́ lórí gbogbo ọkàn ìfẹ́ tí a bá fi hàn.

15 min: Àìní àdúgbò.

18 min: “Báwo Ni Ìwọ Ṣe Ń Hùwà Pa Dà sí Ẹ̀mí Ìdágunlá?” Ìjíròrò láàárín alàgbà méjì. Fi àlàyé lórí àkójọpọ̀ ọ̀rọ̀ tí ó wà lábẹ́ ìsọ̀rí orí ọ̀rọ̀ náà “Bi O Ṣe Le Gbe Ija Kò Aibikita” tí ó wà nínú Ile-Iṣọ Na, October 15, 1977, ojú ìwé 638 àti 639 kún un.

Orin 130 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 20

Orin 42

15 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ìròyìn Ìnáwó.

15 min: Ṣàtúnyẹ̀wò àwọn ìrírí mélòó kan láti inú ìwé 1996 Yearbook, ojú ìwé 6 sí 8, lórí “Global Distribution of Kingdom News” (Ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba Kárí Ayé). Tẹnu mọ́ ìsapá tí àwọn akéde kọ̀ọ̀kan ṣe nínú ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba èyí tí ó kọjá. Fún gbogbo ará níṣìírí láti nípìn-ín ní kíkún nínú pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35 kiri.

15 min: “Ìwọ Ha Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Alákòókò Kíkún Bí?” Ọ̀rọ̀ àsọyé láti ẹnu alàgbà.

Orin 133 àti àdúrà ìparí.

Ọ̀sẹ̀ Tí Ó Bẹ̀rẹ̀ ní October 27

Orin 43

12 min: Àwọn ìfilọ̀ àdúgbò. Ṣàtúnyẹ̀wò ìtẹ̀síwájú tí ìpínkiri Ìròyìn Ìjọba No. 35 ti ní. Ké sí àwùjọ láti sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí. Sọ nípa bí ìpínlẹ̀ tí a ti ṣiṣẹ́ ti pọ̀ tó àti ohun tí a ní láti ṣe láti lè kárí rẹ̀ pátápátá nígbà tí yóò bá fi di November 16. Gbàrà tí a bá ti kárí ìpínlẹ̀ náà pátápátá, a óò fi ìwé Ìmọ̀ lọni ní àwọn ọjọ́ tí ó kù nínú oṣù náà. Tẹnu mọ́ góńgó ti bíbẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ nígbà ìpadàbẹ̀wò níbi tí a bá ti dáhùn pa dà lọ́nà tí ó dára sí Ìròyìn Ìjọba.

15 min: Bí A Ṣe Lè Rí Ìrètí Nínú Àìsírètí. Ọ̀rọ̀ àsọyé tí a gbé ka Ilé Ìṣọ́ ti May 15, 1997, ojú ìwé 22 sí 25 láti ẹnu alàgbà kan.

18 min: Ẹ Jẹ́ Kí Ìmọ́lẹ̀ Yín Máa Tàn. Ọ̀rọ̀ àsọyé àti ìjíròrò lórí ìwé Iṣetojọ, ojú ewé 84 sí 88. Ṣètò ṣáájú láti jẹ́ kí àwọn akéde ṣàlàyé tí ó ṣe pàtó lórí àwọn ìbéèrè tí ó tẹ lé e yìí: (1) Kí ni ìdí tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń wàásù láti ilé dé ilé? (2) Báwo ni a ṣe lo ọ̀nà ìwàásù yí tó ní ọ̀rúndún kìíní? (3) Èé ṣe tí ó fi jẹ́ kánjúkánjú láti máa bá wíwàásù lọ láti ilé dé ilé lónìí? (4) Àwọn àyíká ipò wo ni ó lè mú kí ó ṣòro fún wa láti nípìn-ín déédéé nínú rẹ̀? (5) Báwo ni a ṣe lè rí ìrànwọ́ gbà kí a baà lè máa bá a lọ? (6) Báwo ni a ṣe ń bù kún wa nípa jíjẹ́ tí a ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wa máa tàn? (7) Kí ni a lè ṣe láti túbọ̀ ṣàṣeyọrí ní kíkàn sí àwọn ènìyàn? Fúnni ní àpẹẹrẹ nípa jíjẹ́ kí àwọn akéde mẹ́ta tàbí mẹ́rin sọ àwọn ìrírí tí ń fúnni níṣìírí tí wọ́n gbádùn nígbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ láti ìsọ̀ dé ìsọ̀ tàbí tí wọ́n ń jẹ́rìí ní pópó.

Orin 136 àti àdúrà ìparí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́