ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • km 10/97 ojú ìwé 7
  • Àwọn Ìfilọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Ìfilọ̀
  • Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—1997
km 10/97 ojú ìwé 7

Àwọn Ìfilọ̀

◼ Àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí a óò fi lọni ní October: Àsansílẹ̀ owó fún yálà Jí! tàbí Ilé Ìṣọ́ tàbí fún ìwé ìròyìn méjèèjì. Àwọn ìwé ìròyìn ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún ọdún kan: ₦280. Ẹlẹ́ẹ̀kan lóṣù fún ọdún kan tàbí ẹlẹ́ẹ̀mejì lóṣù fún oṣù mẹ́fà: ₦140. Bẹ̀rẹ̀ láti October 12, a óò máa pín Ìròyìn Ìjọba No. 35, káàkiri. November: Pípín Ìròyìn Ìjọba No. 35 káàkiri yóò máa bá a nìṣó. Àwọn ìjọ tí ó bá ti kárí ìpínlẹ̀ wọn nípa mímú ẹ̀dà Ìròyìn Ìjọba No. 35 dé ọ̀dọ̀ àwọn onílé ní ilé tàbí ibùgbé kọ̀ọ̀kan lè fi ìwé Ìmọ̀ lọni. December: Gẹ̀ẹ́sì—New World Translation pẹ̀lú ìwé náà, The Bible—God’s Word or Man’s? Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Yorùbá—Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun. Ìfilọni àfidípò: Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. Àwọn èdè yòó kù—Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí tàbí Iwe Itan Bibeli Mi. Ìfilọni àfidípò: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí. January: Ìwé olójú ewé 192 èyíkéyìí tí a tẹ̀ sórí bébà tí ó máa ń di yẹ́lò tàbí tí ó máa ń di ràkọ̀ràkọ̀ tàbí èyíkéyìí tí a tẹ̀ ṣáájú 1985 ni a lè fi lọni ní ẹ̀dínwó. Bí ìjọ èyíkéyìí bá ní Mimu Ki Igbesi Ayé Idile Rẹ Jẹ Alayọ lọ́wọ́, wọ́n lè fi ìtẹ̀jáde yìí lọni ní ẹ̀dínwó pẹ̀lú. Àwọn ìwé olójú ewé 192 yòó kù tí a tẹ̀ jáde ṣáájú 1985 tí a tẹ̀ sórí bébà tí kì í ṣá tàbí tí kì í di ràkọ̀ràkọ̀ ni a kò gbọ́dọ̀ fi kún ìfilọni ẹlẹ́dìn-ínwó yìí. Ìfilọni àfidípò: True Peace and Security—How Can You Find It?, Isopọṣọkan ninu Ijọsin Ọlọrun Tootọ Kanṣoṣo Naa, Lilaaja Sinu Ilẹ-ayé Titun, tàbí Àìléwu Kárí-Ayé Labẹ “Ọmọ-Aládé Alaafia.” ÀKÍYÈSÍ: Kí àwọn ìjọ tí yóò bá nílò àwọn ìwé ìgbétásì tí a mẹ́nu kàn lókè yí, yàtọ̀ sí Ìròyìn Ìjọba No. 35, tí a óò kó ránṣẹ́ sí gbogbo ìjọ, béèrè fún wọn lórí Literature Order Form (S-14) olóṣooṣù wọn ti oṣù tí ń bọ̀.

◼ “Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run fún 1998” ni àkìbọnú tí ó wà nínú ìtẹ̀jáde Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa yìí, a sì gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ fún ìtọ́kasí jálẹ̀ ọdún 1998.

◼ Bí ó ti ní odindi òpin ọ̀sẹ̀ márùn-ún gbáko, oṣù November lè jẹ́ àkókò tí ó rọgbọ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.

◼ Àkókò tí ọ̀pọ̀ ìjọ ń ṣe ìpàdé yóò yí pa dà ní January 1. Nítorí náà, àìní lè wà láti kọ̀wé béèrè àwọn ìwé ìléwọ́ tuntun láti fi àwọn àkókò ìpàdé tí a ti yí pa dà hàn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́